Adigunjalè gun àkàbà jí adé ayaba àti ẹ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ lórí ọ̀kadà
Wọ́n ti gbé Mùsíọ̀mù, Louvre Museum kan tì pa ní Paris lẹ́yìn tí àwọn olè kan yawọ ibẹ̀.
Mínísítà fọ́rọ̀ àṣà France, Rachida Dati kọ sójú òpó X rẹ̀ pé bí wọ́n ṣe ń ṣí mùsíọ̀mù náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni àwọn olè náà wọ ibẹ̀ àti pé àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.
Ó ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ tí àwọn olè náà jígbé ni wọ́n ti ṣàwárí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Dati ṣàlàyé pé wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ àmọ́ kò sọ ohun tó jẹ́ gangan.
Mínísítà náà sọ pé àwọn olè náà ṣe iṣẹ́ náà láì sí ìbẹ̀rù tàbí lo ìwà ipá kankan.
Kò sí ẹnikẹ́ni tó jáde láyá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Mùsíọ̀mù náà ní àwọn ń ti iléeṣẹ́ fún ìgbà kan ná àmọ́ wọn kò sọ ohunkóhun le lórí.
Louvre Museum ni mùsíọ̀mù tí àwọn èèyàn máa ń ṣe àbẹ̀wò sí jùlọ lágbàáyé, tí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ọnà àwọn oníṣẹ́ ọnà sì pọ̀ sí jùlọ.
Ohun tí a mọ̀

Oríṣun àwòrán, Mohammed Badra/EPA/Shutterstock
Akọ̀ròyìn BBC News ní Paris, Hugb Scofield sọ pé piléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé kan ní àwọn olè mẹ́ta, tí wọ́n da aṣọ bojú ni wọ́n yawọ Louvre lẹ́yìn tí wọ́n ṣílẹ̀kùn rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú.
Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé ní France, Laurent Nunez sọ pé nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yawọ Apollo Gallery láti ojú fèrèsé.
Nunez ní àwọn olè mẹ́ta sí mẹ́rin tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà lo ọkọ̀ ńlá tó wà ní ẹ̀gbẹ́ mùsíọ̀mù náà láti fi wọ ibẹ̀, ṣe iṣẹ́ láabi wón.
Ó ní nígbà tí wọ́n wọlé tán, wọ́n kó àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n fi pàtẹ, tí wọ́n sì lo ọ̀kadà láti fi sá kúrò níbẹ̀. Ó ní ìṣẹ́jú méje ni àwọn olè náà lò láti fi ṣiṣẹ́.
Ìwádìí ṣì ń lọ láti fi mọ iye nǹkan tí wọ́n jí kó ní pàtó.
Yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ohun olówó iyebíye, iléeṣẹ́ náà àwọn nǹkan tí wọ́n jí kó náà ní ìwúlò fún àṣà àti ìtàn.
Andrew Harding, tó jẹ́ akọ̀ròyìn BBC, tó wà ní ẹ̀gbẹ́ Louvre sọ pé àwọn ọlọ́pàá k]o jẹ́ káwọn èèyàn wọ inú mùsíọ̀mù náà mọ́, tó fi mọ́ òpópónà tó wà níwájú rẹ̀.
Wọ́n ń ṣe ìwádìí fojú sun ìlà oòrùn gúúsù mùsíọ̀mù náà níbi ti wọ́n ti rí àgà, irú èyí tó máa ń wà lórí àwọn ọkọ̀ panápaná.
Àgàbà náà kan gbangba òkè mùsíọ̀mù náà èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé ibẹ̀ ni àwọn olè náà gbà gun orí òkè ilé náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó fẹ́ wọ Louvre ni wọn ríbi wọlé lọ́jọ́ náà.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Gallery Apollo, tí ìgbàgbọ́ wà pé òhun gan ni àfojúsùn àwọn olè náà ló jẹ́ pé ibẹ̀ ni àwọn adé olókùta iyebíye àwọn France kù sí.
Ọ̀pọ̀ wọn ló ti sọnù nígbà tí wọ́n ti ta àwọn òmíràn dànù ṣùgbọ́n tí wọ́n kó àwọn èyí tó kù pamọ́.
Lára àwọn tó kù níbẹ̀ ni àwọn èyí tí wọ́n rí gbà lẹ́yìn tí wọ́n gba ìjọba fún Emperor Napoleon, ìbátan rẹ̀, Napoleon III àtàwọn ìyàwó wọn, Marie-Loiuse àti Eugenie.
Lójú òpó ìkànnì ayélujára Louvre, wọ́n ní àwọn nǹkan olówó iyebíye tó wà níbẹ̀ ni òkúta dáyámọ́ǹdì mẹ́ta tí wọ́n ń pè ní Regent, Sancy àti Hortensia.
Mùsíọ̀mù tó tóbi jùlọ ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Mohammed Badra/EPA/Shutterstock
Louvre ni mùsíọ̀mù tó tóbi jùlọ ní àgbáyé bí ó ṣe fẹ̀ ní ìwọ̀n 73,000 èyí tó tóbi ju pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lọ ní ìlọpo mẹ́wàá.
Ààfin àwọn ọbà ilẹ̀ Faransé ni wọ́n kọ́kọ́ kọ fún ní 1546. Ọba Francis I, tó kọ́kọ́ lo ibẹ̀, jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà tó sì gbèrò láti lo Louvre láti fi máa ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́ ọnà tó kójọ.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọba tó ń jẹ ń mú ìgbèrú bá ibẹ̀, tí ọba Louis XIV sì gba iṣẹ́ ọnà Ọba Charles I wọ ibẹ̀ lẹ́yìn tí ogun abẹ́lé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì parí.
Ohun aládàni ló jẹ́ títí di ìbẹ̀rẹ̀ 1789 nígbà tí wọ́n fi ogun gba ìjọba, tí wọ́n sì ṣi fún gbogbo èèyàn láti máa wọ ibẹ̀ lọ́dún 1793.
Lónìí, iṣẹ́ ọnà tó wà ní Louvre lé ní 35,000 tó fi mọ́ iṣẹ́ ọnà "Monna Lisa" ti Leonard da Vinci.
Èèyàn 30,000 ló máa ń ṣe àbẹ̀wò sí Louvre ní ojoojúmọ́.
Ṣé jíjí nǹkan ní Louvre wọ́pọ̀?
Olè jíjà kò wọ́pọ̀ ní mùsíọ̀mù náà nítorí ààbò ibẹ̀ gbópọn ṣùgbọ́n ó ti wáyé níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí – èyí tó gbajúmọ̀ jùlọ ni ti ọdún 1911 nígbà tí wọ́n jí iṣẹ́ ọnà "Monna Lisa" ti Leonard da Vinci.
Àwọn ọlọ́pàá fi ọ̀rọ̀ wá akéwì Guillaume Apollinaire àti Pablo Picasso lẹ́nu wò nígbà náà ṣùgbọ́n ọmọ orílẹ̀ èdè Italy kan ni ìwádìí fi hàn pé ó ji nítorí ó fẹ́ kí iṣẹ́ ọnà náà padà sí Italy.
Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n tó ri ní Florence, tí wọ́n sì da padà sí Paris. Iṣẹ́ ọnà kò ì tíì gbajúmọ̀ tó báyìí nígbà náà.
Lọ́dún 1983 ni àwọn ohun ìjà tí wọ́n lò ní sẹ́ńtúrì kẹrìndínlógún di àwátì níbẹ̀ tó sì jẹ́ pé ọdún 2011 ni wọ́n tó rí wón padà.
Ní ọdún 1998 ni wọ́n jí iṣẹ́ ọnà Camille Corot tó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà ní sẹ́ńtúrì Kọkàndínlógún. Wọ́n yọ iṣẹ́ ọnà náà, Chemin de Sevres ni wọ́n yọ lára ògiri láì sí ẹnikẹ́ni tó mọ̀ tí wọn k]o si rí mọ́ títí di òní. Èyí ló ṣokùnfà bí wọ́n ṣe mú àtúnṣe bá ètò ààbò mùsíọ̀mù náà.















