Bàálù tó fẹ́ ba ṣekú pàwọn ẹ̀ṣọ́ pápákọ̀ òfurufú nínú ọkọ̀ wọn, àwọn awakọ̀ bàálù mọ́ríbọ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eeyan meji padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ ofurufu akẹru kan to balẹ si papakọ ofurufu Hong International Airport ṣadeedee kuro loju ọna rẹ to si ja sinu omi okun laaarọ ọjọ Aje.
Ṣadeedee ni ọkọ ofurufu Emirates EK9788 naa to n bọ lati Dubai kuro loju ọna rẹ to si kọlu ọkọ awọn ẹṣọ eleto abo ni papakọ ofurufu ọhun.
Eeyan meji to wa ninu ọkọ awọn ẹṣọ eleto abo naa lo ku ninu iṣẹlẹ ọhun, nigba tawọn mẹrin to wa ninu baalu naa mori bọ.
Ijamba ọkọ ofurufu yii wa lara ijamba baalu to tii buru julọ ninu itan papakọ ofurufu Hong Int'l Airport.
Ko si akọsilẹ iru ijamba ọkọ ofurufu bayii fun ọpọlọpọ ọdun ni papakọ ofurufu Hong Kong.
Awọn alaṣẹ ti bẹrẹ iwadii lori ọna ti baalu naa fẹ ba si i.
Awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa ni awọn dari awakọ baalu naa lori ibi to yẹ ko ba si.
Awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa tun sọ pe awọn ami wa loju ọna baalu to maa n dari awọn baalu to fẹ gbera tabi to ba fẹ ba.
Ọga agba papakọ ofufuru Hong Kong, Steven Yiu, sọ pe ọkọ awọn ẹṣọ eleto abo n rin loju ọna mii to jina si ọna ti baalu naa wa nigba ti ijamba ọhun ṣẹlẹ.
Ọgbẹni Yiu ni ṣadeedee ni baalu ọhun kuro loju ọna rẹ ti o kọlu odi to wa lẹgbẹ oju ọna rẹ, lẹyin naa lo kọlu ọkọ awọn ẹṣọ papakọ ofurufu to si gbe e ju sinu okun.
Ọga agba papapọ ofurufu naa fidi rẹ mulẹ pe ọkọ awọn ẹṣọ eleto abo naa ko gba oju ọna baalu rara.
Yiu fikun ọrọ rẹ pe ''ko yẹ ki baalu morile ọna ti omi okun wa, ati pe awakọ baalu naa ko sọ bo ya nnkan ti ṣẹlẹ si baalu naa lori afẹfẹ nigba to fẹ balẹ.
Awọn omuwẹ gbiyanju lati yọ oku awọn eeyan to wa ninu ọkọ eleto abo papakọ ofurufu naa lati inu okun.
Ọmọ ọdun mọkanlelogoji ni ọkan ninu awọn eeyan to ku naa, nigba ti ẹni keji jẹ ọmọ ọgbọn ọdun.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣee ṣe kawọn ṣe iwadii ẹsun ọdaran lori iṣẹlẹ ọhun
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Emirates sọ ninu atẹjade kan ti o fi sita wi pe nnkan kan lo bajẹ lara baalu to ja naa nigba to fẹ balẹ.
Ileeṣẹ naa sọ ninu atẹjade ọhun pe awọn awakọ baalu naa moribọ, ati pe ko si ẹru ninu baalu akẹru naa.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Emirates tun ṣalaye pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu Turkish carrier Act Airlines lo ya baalu akẹru Boeing 747-481 naa lo.
Kete ti ijamba naa ṣẹlẹ lawọn mẹrin to wa ninu ọkọ ofurufu naa ṣi ilẹkun pajawiri lati sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn panapana to tete debi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ lo ri awọn eeyan naa, ti wọn si doola wọn.
Aworan baalu naa ṣafihan bi o ti ge si meji ti apa idi rẹ si wa ninu omi okun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣee ṣe kawọn ṣe iwadii ẹsun ọdaran lori iṣẹlẹ ọhun.
Ajọ AAIA to maa n ṣewadi lẹka irinajo ọkọ ofurufu ni Hong Kong sọ pe awọn si n wa ẹrọ apoti ''cockpit'' to maa n sọ nnkan to ṣokunfa ijamba ọkọ ofurufu ninu okun.
Eyi ni ijamba ọkọ ofurufu to buru sikeji julọ lati igba ti papakọ ofurufu Hong Kong ti kuro lati Kai Tak lọ si Chek Lap Kok loṣu Keje ọdun 1998.
Ni oṣu Kẹjọ ọdun 1999 ni ọkọ ofurufu akero China Airlines kan ja lulẹ lasiko ti iji lile typhoon kan fẹ, eeyan mẹta lo ku ninu iṣẹlẹ naa.















