Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín Ned Nwoko àti Regina Daniels? Ohun tá a mọ̀ rèé

Aworan Regina Daniels
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ned Nwoko ti sọrọ lori ẹsun ti iyawo rẹ to jẹ oṣere tiata, Regina Dainels fi kan an.

Aṣofin ọhun to n soju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Delta ni oun ko figba kankan lu iyawo oun ṣugbọn iyawo oun kundun lilo ogun oloro ati mimu ọti lile, ẹsun ti Regina Daniels ko ti fesi si.

Nwoko, ninu ọrọ to gbe sori ayelujara fẹsun kan iyawo rẹ pe o n lo ogun oloro, ti oun si fẹ ri daju pe o tẹsiwaju ninu itọju rẹ nitori ẹru abo rẹ n ba oun.

O tẹsiwaju ninu ọrọ pe oun ko kọlu tabi lu eyikeyi iyawo oun ṣugbọn Regina kuro ni ile nitori ko ni anfani si awọn aaye kan.

Aworan

Oríṣun àwòrán, sir.sammywest/Instagram

"Regina ko ki n ṣe bayii. Ipenija ogun oloro ati ọti mimu lo ṣokunfa eyi," o sọ.

"O gbọdọ tẹsiwaju ninu itọju rẹ bibẹkọ ẹru rẹ n ba mi.

"Ni bayii ti o ti kuro ni ile lọ sibi ti yoo ti ni anfani si ogun. Mo ni awọn iyawo mii, eyikeyi wọn ko fẹsun kan mi pe mol u wọn ri."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu fidio kan to bọ sori ayelujara lọjọ Ṣatide, Regina fẹsun kan ọkọ rẹ pe, ọkọ rẹ sọ fun awọn tọgi pe ki wọn kọlu oun.

Omije n bọ loju Regina Daniels ninu fidio naa, ti ọpọ eeyan si yi ka ti wọn pẹtu si lọkan.

O n pariwo pe oun ko le gba nnkan ti ọkọ rẹ se n fun mọ.

"Ninu ile Ned Nwoko, n ko ja mọ nkankan ṣugbọn ninu ile mi, olori ni mi. Laye mọ, n ko le ṣe eyi mọ, o ti pọju," o sọ.

Ninu fidio ti ẹgbọn Regina, Sammy West, gbe soju opo Instagram, o fẹsun kan Nwoko pe o kọlu aburo oun, to si sa kuro nibẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Nwoko pese awọn ẹri to ṣafihan, gilassi to fọ ati awọn ọkọ to bajẹ.

O ni iyawo oun, Regina lo se eyi, to si tun gbe ifọti fun awọn oṣiṣẹ rẹ mẹta lai si idi.

"Regina ni onijangbọn ni bi bayii, lo n gba awọn eeyan leti, oṣiṣẹ mẹta lo ti gba leti laarin wakati mejidinlaadọta, to si n ba dukia jẹ, to mọ ọkọ, lai si idi.

"O titọ ni pe, mo ti ni ko bẹrẹ itọju nibi ti ko ti ni anfani si awọn ogun oloro yii ni Asokoro tabi ni oke okun paapa ni Jordan.

Ta ni Regina Daniels?

Aworan Regina Daniels

Ẹni ọdun marundinlọgbọn ni oṣere tiata niu, Regina Daniels

Regina bẹrẹ iṣẹ tiata ni ẹni ọdun meje, to si kopa ninu sinima akọkọ ni ọdun 2007 "Marriage in Sorrow".

Lati igba naa, o ti kopa ni o le ni ọgọrun sinima bii Miracle Child, Python Girl, Spider-Girl, Hanging Coffin, Jaja the Great, Queen Rebecca ati bẹ bẹ lọ.

Regina Daniels fẹ Baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, to jẹ oloṣelu ni ẹni ọdun mejidinlogun, ti igbayawo naa si pe ọdun mẹfa pẹlu ọmọ meji.

Regina ni iyawo kekere fun Ned Nwoko.

Ta ni Ned Nwoko?

Aworan Ned Nwoko

Oríṣun àwòrán, PrinceNedNwoko/Instagram

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni Ned Nwoko, oloṣelu ati agbẹjọro ni orilẹede Naijiria.

Ned Nwoko lọ si fasiti Keele ni Staffordshire, nibi to kawe gba imo oye ofin.

Lẹyin to kawe ni ilẹ UK, o darapọ mọ ileeṣẹ ofin ti ilẹ Gẹẹsi ni Lincoln Inn.

Ned Nwoko bẹrẹ iṣẹ amofin ni ilẹ United Kingdom, nibi to ti ni ọpọ iriri ko to de pe o pada wa si orilẹede Naijiria.

Ni ọdun1995, o gba ami ẹyẹ agbẹjọro ẹya dudu to mọ iṣẹ.

ọdun 1998 ni Nwoko pada si orilẹede Naijiria, to si bọ sidi oṣelu ni ọdun 1999.

O wọle sipo aṣoju ẹkun idibo Aniocha/Oshimili ni ile igbimọ kekere lati ọdun 1999 si 2003.