Wo bí àwọn hòmóònù tó wà nínú àgọ́ ara rẹ ṣe le dárí ìhùwàsí rẹ

Obìnrin tó sùn lórí ibùsùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Jasmin Fox-Skelly
    • Role, BBC Future
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Àwọn hòmóònù inú ara máa ń kó ipa láti mú kí àwọn ẹ̀yà ara ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n lágbára, tí wọ́n le ṣiṣẹ́ òdì èyí tó le ní ipa lórí ọkàn àti ìlera ọpọlọ ẹni.

A máa ń fẹ́ràn láti rò pé èrò ọkàn wa jẹ́ ohun tí a ní ìkápá lé lórí ṣùgbọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí?

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, láti ọjọ́ pípẹ́ ti mọ̀ pé àwọn kẹ́míkà kan tí wọ́n ń pè ní neurotransmiiters ní ipa tó lágbára lórí ọpọlọ èèyàn. Síbẹ̀, bí ìwádìí ṣe ń tẹ̀síwájú, wọ́n ń ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn hòmóònù le ní ipa lórí wa lọ́nà tí a kò rokàn.

Wọ́n ń lo ìmọ̀ yìí láti wá ìtọ́jú sí àwọn àìsàn bíi ìrònú àpọ̀jù.

Àwọn hòmóònù jẹ́ ìrànṣẹ́ kẹ́míkà tí àwọn ẹ̀yà ara kan máa ń gbé jáde. Wọ́n máa ń wọnú ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì máa ń gba ibẹ̀ rin káàkiri ara kí wọ́n tó dúró sára ẹ̀yà kan.

Èyí ló máa ń sọ fún ara pé kí ó ṣe nǹkankan pàtó. Bí àpẹẹrẹ, hòmóònù insulin ló máa sọ fún ẹ̀dọ̀ àti ẹran ara láti mú àpọ̀jù 'glucose' tó bá wà nínú ẹ̀jẹ̀, kó sì fi pamọ́ bíi 'glycogen'.

Àwọn àkóso tí hòmóònù máa ń fà

Àwọn hòmóònù tó lé ní àádọ́ta ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí lára èèyàn.

Àpapọ̀ wọn ló ń ṣe àkóso ara tó fi mọ́ ìdàgbàsókè èèyàn, bí èèyàn ṣe ń ní ìbálòpọ̀ sí, bí èèyàn ṣe ń bím, bí a ṣe ń sùn, tí à ń jí àti pàápàá jùlọ ìlera ọpọlọ.

"Àwọn hòmóònù máa ń ní ipa gidi lórí ọkàn wa," Nafissa Ismail, Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìrònúọkàn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Ottawa, Canada.

"Wọ́n máa ń ṣe èyí nípa níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn neurotransmitters tí wọ́n pèsè ní àwọn agbègbè ọpọlọ kan àti níní ipa lórí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ti kú tàbí neurogenesis nígbà tí wan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀dá àwọn neuron míì."

Obìnrin tó di ojú, tí àwọn àwọ̀ funfun àti dúdú wà lára rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn àìsàn tó nííṣe pẹ̀lú ọpọlọ bíi ìrònú àpọ̀jù, àwọn nǹkan tó máa ń ṣeni lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá lágbára jẹ́ èyí tó máa ń pọ̀ si lásìkò tí àyípadà bá bá hòmóònù. Èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin.

Bí ìrònú àpọ̀jù ṣe máa ń ṣe ọkùnrin àti obìnrin máa ń rí bákan náà nígbà tí wọ́n bá wà ní ọmọdé ṣùgbọ́n tí ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé obìnrin máa ń pọ̀ sib í wọ́n bá ṣe ń dàgbà.

Ṣé a le di ẹ̀bi èyí ru àwọn hòmóònù bí? Ó le má jẹ̀ ẹ́ ohun tuntun láti mọ̀ pé fún obìnrin, àwọn hòmóònù tó níṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ máa ń ní ipe lórí bí ọkàn èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́.

Iléeṣẹ́ ètò ìlera National Health Service ní UK sọ pé tó bá tik ú ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí nǹkan oṣù obìnrin bá máa wá, ẹ̀yà ara oestrogen àti progesterone máa já wálẹ̀ èyí tó le papọ̀ mọ́ ìkórira fún àwọn kan àmọ́ kìí ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń rí bẹ́ẹ̀ fún.

Àwọn onímọ̀ sọ pé àwọn obìnrin kan máa ń ní premenstrual dysphoric disorder (PMDD), àìlera kan tó níṣe pẹ̀lú èrò ọkàn tó sì máa ń mú kí obìnrin míì ní èrò pípa ara rẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ méjì kí nǹkan oṣù tó bẹ̀rẹ̀.

Fún ọ̀pọ̀ obìnrin tó ní PMDD, nǹkan tó lágbára tí wọ́n máa ń kojú ní oṣooṣù ni èyí tó sì máa ń ní ipa láyé wọn gẹ́gẹ́ bí Liisa Hantsoo tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka psychiatry and behavioural sciences ní ilé ẹ̀kọ́ gíga The Johns Hopkins University School of Medicine, Amẹ́ríkà.

Ní kété tí obìnrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tán, ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa ń rí ìjáwálẹ̀ hòmóònù progesterone àti oestrogen.

Bẹ́ẹ̀ náà ni tí oestrogen bá lọ sókè ni ìwádìí ti sọ pé ó máa ń fa kí ara yá gágá, tó sì máa ń fa ìdùnnú.

"Tí a bá fún èèyàn ní abẹ́rẹ́ allopregnanolone, ó máa ń jẹ́ kí ara wọn balẹ̀," Ọ̀jọ̀gbọ́n Hantsoo sọ.

Àwọn hòmóònù tó máa ń ṣe ṣégeṣège nínú oyún, lásìkò perimenopause àti ìgbà tí obìnrin kò bá rí nǹkan oṣù mọ́ máa ń ní ipa lórí ìlera ọpọlọ.

Àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization sọ pé ìdá mẹ́tàlá (13%) obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ló máa ń ní depression.

Kílódé tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ní kété tí obìnrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tán, wọ́n máa ń rí ìjáwálẹ̀ nínú hòmóònù progesterone àti oestrogen. Lásìkò tí nǹkan oṣù obìnrin bá ti ń múra àti dúró, àwọn onímọ̀ sọ pé ó ṣeéṣe kí hòmóònù tó ń rí sí ilé ẹyin obìnrin máa ṣe ṣégeṣège.

Kìí ṣe iye hòmóònù tí èèyàn ní gan ni pàtàkì bíkòṣe bó ṣe ń lọ sókè àti bó ṣe ń wálẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Liisa Galea ní ẹ̀ka psychiatry ní ilé ẹ̀kọ́ University of Toronto, Canada.

"Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń gba àyípadà yàtọ̀ síra. Nígbà tí àwọn kan kò ní mọ ìnira kankan nígbà tí wọ́n kò bá rí nǹkan oṣù mọ́, kìí rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn míì.

Àwọn ọmọdé márùn-ún tó wà nínú ọgbà tí wọ́n ń ṣeré

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kìí ṣe ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin nìkan. Àwọn ọkùnrin náà máa ń rí àdínkù nínú testosterone wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyípadà wọn kìí fojú hàn tó bẹ́ẹ̀ bíi ti àwọn obìnrin.

Ẹ̀rí ti fi hàn pé àyípadà kékeré le ní ipa lórí ọkàn wọn ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ni èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ fún.

"A máa ń rí àyípadà lára èrò ọkàn àwọn ọkùnrin bí àyípadà bá ṣe ń bá testosterone wọn ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀," Ọ̀jọ̀gbọ́ Ismail sọ.

Ọ̀nà kan tí hòmóònù ìbálòpọ̀ ṣe máa ń nípa lórí èrò ọkàn èèyàn ni bí àwọn neurotransmitter serotonin àti dopamine bá ṣe ń lékún nínú ọpọlọ. Tí serotonin bá lọ sílẹ̀, ó le ṣokùnfà kí èèyàn ní depression.

Àwọn ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn oestrogen le mú serotonin ṣiṣẹ́ si àti láti mú ẹya dopamine pọ̀ si nínú ọpọlọ.

Àwọn ẹ̀rí míì sọ pé oestrogen le dá ààbò bo àwọn neuron láti má bàjẹ́, tó sì lè mú ìdàgbàsókè bá neuron tuntun nínú ọpọlọ tí wọ́n ń pè ní hippocampus – èyí tó máa ń kó ipa tó lágbára lórí bí èèyàn ṣe ń rántí nǹkan.

Àwọn èèyàn tó bá ní àìsàn depression àti Alzheimer ni ìgbàgbọ́ wà pé wọn kò ní neuron nínú hippocampus wọn.

Èyí ló fà á tó jẹ́ pé àwọn obìnrin tí kò bá rí nǹkan oṣù mọ̀ ṣe sábà máa ń gbàgbé nǹkan.

Tí wàhálà ara bá gbòdì

Bákan náà ni àìní neuron nínú hippocampus máa ń ní ipa lórí àwọn hòmóònù míì bíi hypothalamus-pituitary-adrenal (HPA) èyí tó máa ń rí sí bí ẹ̀yà ara ṣe máa ń gba wàhálà.

Nígbà tí àyà èèyàn bá ń jà, hypothalamus – abala ọpọlọ tó máa ń ṣe àkóso bí ara ṣe ń gbé hòmóònù jáde – máa rán iṣẹ́ sí pituitary gland láti gbé hòmóònù tí wọ́n ń pè ní adrenocorticotropic hormone (ACTH) jáde.

ACTH yóò wá sọ fún adrenal glands láti pèsè cortisol.

Cortisol yóò sọ fún ara láti pèsè ṣúgà sínú ẹ̀jẹ̀, èyí tí yóò sọ fún ọpọlọ àti ara láti pèsè agbára tó nílò lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.

Ọwọ́ èèyàn méjì tó di ara wọn mú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

HPA máa ń ṣiṣẹ́ nígbà tí èèyàn bá ṣe wàhálà.

Lọ́pọ̀ ìgbà, cortisol tó wà lára yẹ kó sọ fún ọpọlọ pé kó fi ara balẹ̀. Hippocampus yóò sọ fún hypothalamus láti yé ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú pituitary tó máa ń ṣe ìdádúró wàhálà ara.

Ẹ̀wẹ̀, bí èèyàn bá ṣe wàhálà púpọ̀, èyí kìí ṣẹlẹ̀, tí ọpọlọ yóò sí kún fún cortisol.

Èyí kò dára rárá nítorí cortisol máa ń kí ọpọlọ wú, èyí tó máa ń pa àwọn neuron inú hippocampus, tí kò sì ní jẹ́ kó máa fún èèyàn ní àmì.

Cortisol le pa àwọn neuron tó wà ní agbègbè ọpọlọ bákan náà bíi amygdala àti prefrontal cortex.

Fínfín oxytocin le jẹ́ kí èèyàn lawọ́, kí èèyàn sì ní ojú àánú.

"Amygdala jẹ́ abala kan ní ọpọlọ tó máa ń ṣe àkóso bí èèyàn ṣe máa ń gba nǹkan mọ́ra àti pé tí èèyàn bá ti pàdánù rẹ̀ ló máa ń jẹ́ kí ìmọ̀lára dínkù," Ọ̀jọ̀gbọ́n Ismail sọ.

Atrophy nínú prefrontal cortex ló máa ń jẹ́ kó ṣòro láti gbájúmọ́ nǹkankan tàbí pinnu lórí nǹkankan lásìkò. Tí atrophy tó wà ní hippocampus máa ń jẹ́ kó ṣòrò láti máa rántí ìṣẹ̀lẹ̀.

Bí cortisol ṣe máa ń jẹ́ kó rẹ èèyàn, oxytocin, tí wọ́n máa ń pè ní hòmóònù ìfẹ́ máa ń ṣe ìdàkejì rẹ̀.

Èèyàn máa ń pèsè oxytocin lásìkò ìbímọ, fún ọmọ lọ́yàn àti bí èèyàn bá dà lẹ́yìn ìbálòpọ̀.

"Nígbà tó bá dàbí pé èèyàn ní ààbò, tí a sì ní ìmọ̀lára pé àtìlẹyìn wà fún èèyàn, ó máa ń mú àdínkù bá cortisol tí wàhálà máa ń fà.

Ọwọ́ tí ó mú oògùn dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìwádìí ní ìwòsà hormone replacement therapy (HRT) le ṣe ìrànwọ́ fún àwọn obìnrin tó ń kojú àìrí nǹkan oṣù mọ́

Lára àwọn ìwádìí tí wọ́n gbà wọlé sọ pé àwọn hòmóònù méjì pàtàkì tí thyroid máa ń pèsè le fa inú fu àyà fu àti depression.

Àwọn hòmóònù náà ni triiodothyronine (T3) àti thyroxine (T4), tí àwọn méjéèjì sì máa ń ṣe ìrànwọ́ lórí bí ọkàn ṣe n ṣiṣẹ́ àti bí ara ṣe máa ń gbóná sí.

Ẹ̀wẹ̀, tí àwọn hòmóònù yìí bá ga – tí thyroid bá ń ṣiṣẹ́ tó ga – àyà èèyàn le máa já. Tó sì jẹ́ pé tó bá lọ sílẹ̀ púpọ̀, depression le wáyé. Ohun ayọ̀ ibẹ̀ ni pé àtúnṣe wà fún wọn.

"Tí èèyàn bá sọ fún àwọn dókítà pé àyípadà bá bí òun ṣe ń ṣe, àyẹ̀wò tí wọ́n máa ní kó kọ́kọ́ ṣe ni àyẹ̀wò àwọn hòmóònù nítorí ó máa ṣeéṣe láti ṣe àtúnṣe àwọn hòmóònù," Ismail sọ.

Ìdí tí thyroid fi máa ń ní ipa lórí ọkàn èèyàn ṣùgbọ́n ìwádìí kan ní T3 máa ń mú àlékún bá serotonin àti dopamine nínú ọpọlọ.

Ìwòsàn tuntun

Ìrètí wà pé ìmọ̀ tuntun nípa hòmóònù àti bí wọ́n ṣe máa ń ní ipa lórí ìṣesí èèyàn yóò mú ìwòsàn jáde.

Àwọn àpẹẹrẹ ti ń wà pé èyí ti fẹ́ máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú oògùn kan tí wọ́n ń pè ní Brexanolone èyí tó máa ń ṣe bíi hòmóònù allopregnanolone.

Bákan náà ni àwọn ẹ̀rí wà pé tí èèyàn bá ní testosterone tó ń já wálẹ̀, lílo oògùn tó máa pọnkún testosterone yóò ṣiṣẹ́.

Ìwádìí tún fi hàn pé àwọn ìwòsàn fún oestrogen tó fi mọ́ hormone replacement therapy (HRT), le mú àlékún bá ìṣesí èèyàn àmọ́ kìí ṣe gbogbo obìnrin ló máa ń la àwọn nǹkan yìí kọjá.

Àwọn hòmóònù tó wà fún ìfètò sí ọmọ bíbí máa ń ṣiṣẹ́ àrà lórí àwọn kan tó ní PMDD, tó sì lè mú ìṣòro àwọn míì pọ̀ si.

Èyí ṣàfihàn bí ìwádìí lórí wíwá ìwòsàn ṣe fi hàn pé a kò tíì mọ ìdí tí àyípadà hòmóòmù ṣe máa ń ní ipa lórí àwọn èèyàn kan.

"A mọ̀ pé hòmóònú máa ń nípa lórí ìṣesí àti ìlera ọ[pọlọ ṣùgbọ́n a nílò láti ṣe àwárí bí wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ àti ìwòsàn tó péye," Ọ̀jọ̀gbọ́n Ismail sọ.

BBC Future ló ni iṣẹ́ ìwádìí