Kí ló fà á tí àwọn ọkùnrin fi máa ń lá àlá ìbálòpọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ iroyin ẹlẹjẹ to n ja kiri pe nipa awọn ọkunrin, pe wọn tọ atọ ọkunrin lasiko ti wọn ba ṣun lọwọ, ti ọpọ ọkunrin si gbagbọ pe eyi tumọ si pe atọ ọkunrin naa ko le di ọmọ.
Titọ atọ fun ọkunrin lasiko to n ba sun lọwọ ki n ṣe nnkan to buru, gẹgẹ bii awọn onimọ ilera ṣe ṣalaye.
Ajọ eleto ilera agbaye ni ti ọkunrin ba ti n dagba ni awọn atọ rẹ yoo ma pọ si, ti o si ma fa ki orun ma kun wọn nigba miiran.
Ala ibalopọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oniwadii ni fasiti Hong Kong Shu Yin se iwadii lori 'Ala ibalopọ' ati ohun to fa to fi jẹ pe eyi ma n waye lasiko ti ọkunrin ba n sun.
Ida Ọgọta awọn to kopa ninu iwadii yii sọ fun awọn oniwadii pe awọn ala ibalopọ yii ma jẹ ki atọ wọn jade. Igbagbọ wa pe awọn ọmọde ma ni ala yii pẹlu.
Wọn ni awọn ma n la awọn ala yii ni igba mẹsan an lọdun.
Bakan naa ni igbagbọ kan wa pe awọn ala yii da lori nnkan ti eeyan ba n ro lọkan; bi o ti lẹ jẹ pe iwadii yii ṣe tako o.
Awọn oniwadii fihan pe, bi o ti lẹ jẹ pe ibalopọ ṣe pataki ni igbesi aye ẹda, ko yẹ ko jẹ nnkan ti eeyan yoo ma fi la ala, eyi to tunmọ si pe iye awọn to n kopa ninu rẹ kere gan.
Onimọ kan nipa ibalopọ, Dokita Kamaraj ni, "Ara ọkunrin ma n pese atọ loorekoore, ti atọ ko ba jade lasiko ibalopọ, yoo jade lasiko ti wọn ba n sun lọwọ. Eyi ki i ṣe nnkan to buru.
Dokita Bhupati Jan ni, "Gẹgẹ bii obinrin ṣe n ṣe nnkan oṣu, lawọn ọkunrin naa n tọ atọ.
Ṣe eyi le fa airiọmọbi fun ọkunrin?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oniwadii lati ilẹ ẹkọ giga Tongji Medical College lorilẹede China gbe iwadii kan jade sori opo ayelujara American Academy of Medicine, nibi ti wọn se iwadii atọ ọkunrin ti ko le bimọ ati ti ọkunrin ti ara rẹ pe.
Iwadii naa fihan pe ida mejileladọrun ọkunrin ti ko le bimọ lo jẹ pe wọn koju inira lasiko ibalopọ.
Ẹwẹ, ọpọ le la ala ibalopọ lasiko orun.
Iwadii, atọ ọkunrin 91 lo ni ipenija ti a n pe erectile dysfunction tabi erectile dysfunction ni wọn ṣawari.
Iwadii ọhun fihan pe atọ to ma n jade lasiko orun jẹ ida 30.6, to pọju ju ti eyi to n jade lasiko ibalopọ tabi ọna miiran.
O ni iwadii ni pe awọn ọkunrin ti ko le bimọ ni atọ gidi ṣugbọn o ma n jade lasiko orun.
Dr. Kamraj ni, "Ọkunrin bẹrẹ lati ọdun mejila tabi ju bẹ lọ le ni ipenija erectile dysfunction. Ko si ẹri ijinlẹ sayẹnsi ti a le sọ pe o fa eyi ni ara ọkunrin.
"Ara ma n pese atọ tuntun lẹsẹkẹsẹ to pa jade tan, titọ atọ lasiko orun ko le fa airi ọmọ bi fun ọkunrin."
Ki lo fa ti ọkunrin fi n ni ala ibalapọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dr. Bhupati Jan said, "Ara ma n tọju atọ to bap ese pamọ. Iye atọ ti ara ba pese, to ba tik un, o gbọdọ jade, ko si tun pese omiran. "
Dr. Kamaraj ṣalaye pe nini ala ibalopọ ko tun mọ si pe ọkunrin naa ni aisan kankan.
O fikun pe iwadii ti waye lori eyi ṣugbọn awọn ko le ṣawari ohun pato to n fa ala ibalopọ.
"Eyi le waye nitori eeyan n gbero lati ni ibalopọ tabi ara rẹ dide."
"Ko si iwadii pe awọn ala yii le se akoba fun atọ ọkunrin tabi sise dide ọkunrin," o sọ.
Kamaraj ni, "igbadun laisi ibalopọ tumọ si llera gidi."












