Nnamdi Kanu : Ọlọ́pàá gbé ìkìlọ̀ kalẹ̀ lóríi ṣíse ìwọ́de nítòsí Aso Rock, Sowore fárígá

Aworan awọn ọmọ ileeṣẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti ṣe ikilọ fun gbogbo awọn ẹgbẹ to n gbero lati se iwọde lọjọ Aje niluu Abuja pẹlu aṣẹ lati ọwọ ile ẹjọ pe ki wọn sumọ awọn agbegbe kan ni olu ilu Abuja.

Adajọ M.G. Umar lo gbe idajọ yii kalẹ ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2025 ninu ẹjọ nọmba No. FHC/ABJ/CS/2202/2025, to wa laarin ijọba apapọ orilẹede Naijiria, Omoyele Sowore ati awọn mẹrin mii, eyi ko ni gba wọn ni aaye lati se iwọde ni agbegbe ile ijọba Aso Rock Villa, Ile igbimọ aṣofin, ileeṣẹ ọlọpaa, ile ẹjọ, agbegbe Eagle Square ati ọna Shehu Shagari.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin, ninu atẹjade to fi sita, ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri pe mojuto ofin Naijiria to faye gba alaafia lasiko iwọde yii.

"Pẹlu aṣẹ ile ẹjọ ati ojuṣe ileeṣẹ ọlọpaa lati mojuto ofin, ileeṣẹ ọlọpaa n kesi awọn ẹgbẹ yii ti wọn n pe fun itusilẹ Mazi Nnamdi Kanu layi tẹle ofin ati ilana ti ile ẹjọ gbe kalẹ fun wọn.

Iwọde yii, ti yoo waye lonii ọjọ Aje, Ogunjọ oṣu kẹwaa, lo n pe fun itusilẹ olori ikọ IPOB, Nnamdi Kanu, ẹni to ti w ani atimọle ati ọdun 2021, lẹyin ti ọwọ tẹ lorilẹede Kenya, to si n koju ẹsun

Hundeyin fikun pe bo ti lẹ jẹ pe ofin faye gba araalu lati ṣe ifẹhonuhan, o gbọdọ jẹ sise ni ilana ofin.

"Aṣẹ ile ẹjọ wa fun aabo awọn olufẹhonuhan, ki ṣe lati tẹ oju ẹtọ wọn mọlẹ.

"Idi ree ti a n fi gba awọn eeyan ni amọran pe ki wọn tẹle aṣẹ ile ẹjọ, ki wọn si yago fun awọn agbegbe yii.

"Ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri daju pe eyi ko fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ, ti a o si da abo bobo ẹmi ati dukia araalu."

Sowore tako idajọ ile ẹjọ

Ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, ẹni to n pe fun iwọde itusilẹ Nnamdi Kanu, ti bọ sori ayelujara lati tako aṣẹ ile ẹjọ ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe sita lori fifi ofin de awọn agbegbe kan fun awọn olufẹhonuhan.

"Ko si idajọ ile ẹjọ kankan to da iwọde lọ si Aso Rock duro," Sowore sọ.

O jiyan pe aṣẹ ile ẹjọ ko ni ẹsẹ nilẹ rara nitori wọn ko gbe jade ni orukọ olujẹjọ tabi ẹgbẹ to n wọde.

Sowore fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe, to si ni eke wọn han sita.

O kede pe ikọ agbẹjọro 115 ti wa ni ilẹ lati tako aṣẹ ile ẹjọ naa ni kete to ba jade.

Bakan naa ni Sowore ikilọ pe awọn ko ni faye gba ki ileeṣẹ ọlọpaa fi tipatipa mu ẹnikẹni lasiko iwọde yii.