Amẹ́ríkà já ohùn tó jọ bàálù atọpinpin bọsílẹ̀ ní Alaska

Oríṣun àwòrán, Aworan Alaska
Aarẹ orilẹede Amerika Joe Biden ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ ologun ofurufu ja afurasi baalu digboluja to n fo kiri loju ofurufu ni agbegbe Alaska bọsilẹ.
Agbẹnusọ aarẹ Biden, John Kirby ni nnkan ohun lo tobi to ọkọ ayọkẹlẹ kekere ti o si le ṣe ijamba fun awọn araalu, botilẹ jẹ wi pe wọn ti le sọ pato ibiti nkan ohun ti wa tabi idi to fi n fo loju ofurufu Amẹrika.
Iṣẹlẹ yi waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn ologun Amẹrika jaa baalu aṣofofo china bọsilẹ.
Nigba ti Kirby n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba White House, o salaye pe nnkan ti Amerika jaa kere si baalu asofofo ti wọn ja silẹ lọsẹ to kọja ni ori omi South Carolina.
Kirby ni ijọba Amẹrika ti ran baalu ologun lati lọ ko awọn nkan to jasilẹ nibiti o ja si,
Agbenusọ aarẹ ni awọn ko ti mo nnkan ohun jẹ tabi ẹni ti o ni.
Kirby teṣiwaju ninu ọrọ rẹ, o ni ṣaaju ki wọn to ja baalu naa wọn ri daaju wi pe ko si ẹni kankan ninu rẹ, ti Aare Biden si paṣẹ pe ki wọn jaa nnkan na bọsilẹ.
O ni ijọba orilẹede Amerika yoo lo gbogbo agbara rẹ lati dabobo awọn olugbẹ Amerika ati oju ofurufu orilẹede naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Awọn ologun n wa awọn afọku baluu afẹfẹ naa lati se ayẹwo"
Agbenusọ ile iṣẹ ologun Amẹrika Ọgagun pat Ryder ni nnkan ohun kere si baalu China ti wọn ja silẹ laipẹ yii.
O fidi rẹ mulẹ pe Baalu ologun F-22 lo ja nnkan ohun ni dede ago mẹfa kọja(18:45 GMT) irọlẹ ana.
Ọgagun Ryder ni awọn Ijona ku nnkan ohun ni awọn ṣajọ lati gbe lo si ile ayẹwo ki wọn le sọ pato ibiti nnkan ohun ti wa.
Nkan ohun lo ti sun mo bebe ala laarin Amẹrika ati Canada ki wọn to ja silẹ,Aarẹ Canada ni wọn ti ṣalaye fun oun nipa nnkan to n fo lo furufu Amẹrica ti oun si fọwọdi ki wọn ja lulẹ.
Kirby ni pẹlu iwadi nnkan to n fo ko ni agbara lati yi kiri bi ti akọkọ ti wọn ja lulẹ,lọwọlọwọ ko si nnkan miran to ṣẹsẹ ko mu ipaya wa loju ofurufu orilẹede Amẹrika lakoko yii.















