Irọ́ ni o! A kò gbé ìgbésẹ̀ láti dìtẹ̀ gbàjọba ṣáájú ìdìbò Naijiria – Iléeṣẹ́ ológun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ologun ni Naijiria ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn n gbimọ lati ditẹ gbajọba ki idibo ma baa waye ninu ọdun 2023.

Eyi n waye lẹyin ti ọkan gboogi lẹgbẹ oṣelu APC sọ wi pe awọn ọgagun ni Naijiria ṣe ipade idakọnkọ pẹlu oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar.

Ileeṣẹ ologun ni iroyin ẹlẹjẹ to kọni lominu ni ẹsun ti wọn fi kan wọn.

A o rii daju pe ofin orilẹede Naijiria leke ninu eto idibo to n bọ - Ileeṣẹ ologun

Idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria yoo waye ni oṣu yii ti awọn oludije si ti gbaradi.

Awọn mẹta ti o wọpọ laarin awọn to n dije du ipo ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lati ẹgbẹ oṣelu APC, Atiku Abubakar lati ẹgbẹ oṣelu PDP ati Peter Obi lati ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, General Tukur Gusau fi lede ni ileeṣẹ ọmọogun ni Naijiria ti ni awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati rii pe ofin orilẹede Naijiria di bibọwọ fun lasiko eto idibo to n bọ naa.

‘’A mọ iṣẹ wa ni iṣẹ, a o si ri pe ofin Naijiria duro deede lasiko eto idibo naa.’’

‘’ Ẹka ileeṣẹ ọmọogun ni Naijiria ko ni lọwọ si mọdaru kankan, irọ ati iroyin ẹlẹjẹ ni awọn iroyin to gbode kan.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty

Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ko i tii fesi si atẹjade ti ileeṣẹ ikọ ọmọogun ni Naijiria naa fi lede.

Bakan naa ni awọn araalu ko kọ ibi ara si iroyin naa, nitori ọpọlọpọ nkan lo n ṣẹlẹ lorilẹede naa, to fi mọ eto aabo to mẹhẹ, aisi epo bẹntirol, ọwọngogo owo lode.