'Ẹ yé gbé ìròyìn irọ́ kiri! Adeleke kò gbèrò láti ṣe ìfigagbága ijó Valentine kankan o'

Oríṣun àwòrán, Olawale Rasheed
Latari iroyin kan tawọn eeyan ti n pin kiri pe Gomina ipinlẹ Osun Ademola Adeleke fiwe pe awọn oṣiṣẹ ijọba lati wa ṣe akanṣe eto ifigagbaga ni ayajọ ọjọ awọn ololufẹ eyi ti yoo waye ni ọla ọjọ Kẹrinla oṣu Keji ọdun yii, ijọba ipinlẹ Osun ti fi iwe sita lati sọ pe irọ gbaa ni wọn n pa.
Iroyin naa ti ṣaaju tan kalẹ pe “Gomina Ademola Adeleke fiwe pe awọn akọwe agba, awọn adari ẹka ileeṣẹ ijọba, awọn ọga agba, adari ijọba ibilẹ kaakiri ati gbogbo oṣiṣẹ to wa ni ipinlẹ naa wa si ibi ajọyọ ayajọ ọjọ ololufẹ lara eyi ti wọn yoo ti ṣe ifigagbaga ijo.
Lootọ ni atẹjade kan jade latọdọ adari awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa, K.N Akintola to sọ pe ayẹyẹ ijo Valentine naa yoo waye.

Oríṣun àwòrán, Olawale Rasheed
Amọṣa, kete ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun Ademola Adeleke ni wọn fi atẹjade ti gomina naa fi sita ranṣẹ eyi ti Mallam Olawale Rasheed fọwọ si.
Atẹjade naa sọ wipe “lodi si ohun ti awọn iroyin ẹlẹjẹ tawọn oniroyin ori ayelujara kan n gbe kiri, Sẹnetọ Ademola Adeleke ko ni oun fẹ ṣe ayẹyẹ ayajọ ololufẹ.
Dipo rẹ, ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ lo n ṣe agbekalẹ eto ayajọ awọn ololufẹ ọlọdọọdun eyi ti wọn si ti n ṣe lati ọdun mẹrin sẹyin”.
Eyi tumọ si pe akanṣe eto naa jẹ eyi ti awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Osun ti maa n ṣe lati asiko ijọba gomina ana, Adegboyega Oyetola.
“ẹgbẹ naa kan fiwe pe Gomina Adeleke gẹgẹ bii alejo pataki ni gẹgẹ bi imoore si ipa pataki to ti ko fun atilẹyin ati itaji si itọju awọn oṣiṣẹ ijọba.”
Atẹjade naa fihan pe iwe ipe ti wọn fi pe Adeleke jẹ ohun to yẹ ẹ tori igbesẹ akin to gbe eyi to mu ojutu wa si iṣoro abọ owo oṣu ti o ti n waye nipinlẹ naa ati ọgbọn amulo rẹ lati koju ipenija ati adinku to n ba ọrọ owo awọn oṣiṣẹfẹyinti.
“Torinaa, ko tọna lati tori iwa ibatẹnijẹ ati tẹmbẹlẹkun gbe iru iroyin bayẹn sita pe Gomina n pe apejẹ ayajọ ololufẹ”.














