World Radio Day: Iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò máa ń mú ẹ̀wà àti àpọ́nlé ba ni àmọ́ kò lówó lórí

Àkọlé fídíò, World Radio Day: Àwọn òṣìṣẹ́ rédíò ní àwọn ń pa ìsòro àwọn mọ́ra ni láti mú inú aráàlú dùn

Loni tii se ọjọ Kẹtala osu keji tun ni ayajọ miran fun eto igbohunsafẹfẹ lori redio tun ko.

Idi si niyi ti BBC Yoruba fi jade sita lati ba awọn ilumọọka agbohunsafẹfẹ sọrọ nipa iriri wọn lẹnu isẹ ati awọn ipenija to n koju wọn.

Olanrewaju Adewusi, Titilayo Akinsola ati Abiodun Adewole salaye pe lootọ ni isẹ igbohunsafẹfẹ lori redio maa n mu iyi, apọnle ati ẹwa ba awọn, amọ isẹ la ri, ọwọ n kako lasan ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn fi kun pe awọn saba maa n pà ipenija tawọn ba n koju mọra lasiko ti awọn ba wa lori afẹfẹ ni, lọna ati mu ayọ ati idunnu ba awọn eeyan to n gbọ awọn.

Wọn wa n gbadura pe ki Ọlọrun fi owo ti isẹ igbohunsafẹfẹ nidi, ko ma jẹ pe awọn yoo kan gbe orukọ lori ni.