Chrisland School: Ìjọba, ilé ẹ̀kọ́, òbí gbọdọ̀ mú ètò ìlera, ààbò àwọn ọmọ lọ́kúnkúndùn- Onímọ̀ ètò ẹ̀kọ́

Aworan gomina Sanwo-Olu, ile ẹkọ Chrisland ati iya Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu/chrisland/twitter/bam.babycity/instagram

Akọṣẹmọṣẹ kan nipa eto Ẹkọ ti woye pe aisi amojuto to peye lati ọdọ ijọba, awọn alaṣẹ ileewe ati awọn obi lo n fa awọn kudiẹkudiẹ to n mu iku aitọjọ waye fun awọn akẹkọọ ati awọn iṣẹlẹ kotọ miran lorilẹede Naijiria.

Onimọ ẹkọ naa woye ọrọ yii ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lori awọn ọna to wa lati pese aabo to peye nile ẹkọ atawọn ayika fawọn ọmọde.

Ọgbẹni Dairo ṣalaye pe ọpọ igba ni ijọba, awọn alaṣẹ ile ẹkọ atawọn obi kii ronu nipa aabo to peye fun awọn akẹkọọ ni gbogbo igbesẹ ti wọn ba n gbe fun eto ẹkọ awọn ọmọde.

Iroyin iku Whitney Adeniran ti da ọpọ awuyewuye silẹ lẹyin ti ọmọdebinrin naa jade laye nibi idije ere idaraya onilejile interhouse sport ile ẹkọ Chrisland School to wa ni Opebi nilu Eko.

"Ṣe ọkọ itọju alaisan pajawiri ‘ambulance’ wa ni sakani ibudo ti akẹkọọ Chrisland ku si?"

Dairo ni ailakasi awọn eeyan yii ni oun le e sọ pe o kun ara ohun to ṣeeṣe ko fa iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

Eekan akọṣẹmọṣẹ eto ẹkọ naa ni ibeere oun fun awọn to ṣe eto idije ere idaraya onilejile ’interhouse sports’ naa ni pe:

“ṣe ọkọ itọju alaisan ‘ambulance’ wa ni sakani ibudo naa?

Ṣe awọn akọṣẹmọṣẹ ilera wa nibẹ?”

O ni ọpọ awọn ile ẹkọ wọnyii ni kii mu ọrọ aabo lọkunkundun ayafi ti wahala bi eyi ba ṣẹlẹ tan.

Awọn igbesẹ fun idaabo bo akẹkọọ lasiko pajawiri

Awọn koko ohun ti o la kalẹ fun amulo niwọnyii lati pese abo fun awọn akẹkọọ lasiko pajawiri:

  • Awọn oludasilẹ ile ẹkọ gbọdọ bẹrẹ si ni kọ awọn akẹkọọ nipa iṣẹlẹ pajawiri ati kikoju rẹ
  • Awọn ile ẹkọ gbọdọ bẹrẹ si nii pese awọn ohun elo ati oṣiṣẹ lati koju iṣẹlẹ pajawiri
  • Awọn ijọba, paapaajulọ ileeṣẹ eto ẹkọ gbọdọ rii daju pe wọn n ṣe amojuto to yẹ fun awọn ile ẹkọ gbogbo ni ibamu pẹlu ilakalẹ ode oni.
  • Ijọba gbọdọ maa kan an nipa fun awọn obi lati maa fi iwe alaye ipo ilera akẹkọọ lati ile iwosan ijọba han ni ile ẹkọ ni saa gbogbo.
  • Gbogbo awọn ile ẹkọ ti ko ba ni ohun elo gbogbo ati oṣiṣẹ to ba yẹ ni ki ijọba ti pa.
  • Awọn obi gbọdọ maa ṣe alaye lẹkunrẹrẹ nipa ipo ilera awọn ọmọ wọn fun ile ẹkọ