Àwọn ajìjàgbara Oodua Nation ń gbèrò àti da ìbò rú nílẹ̀ Yorùbá - Ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà

Aworan Yoruba nation ati aworan ọga ọlọpaa NAijiria, Baba Usman Alkali

Oríṣun àwòrán, other/nigeria police

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Baba ti fi ẹsun kan awọn ajijagbara ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba pe wọn n ko nnkan ijagun jọ lati da eto idibo apapọ to n bọ lọna lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ati ọjọ kọkanla oṣu kẹta.

Lasiko to n ba awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa sọrọ lolu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abuja, ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Baba Alkali sọ pe awọn igbesẹ ti awọn ẹgbẹ naa n gbe n ti igi bọ oju abo orilẹede Naijiria, eleyi to ni o lee pagidina eto idibo ti ko lẹjanbakan ninu lọdun yii.

Bakan naa lo ni awọn agbebọn ati agbesunmọmi n da awọn ileto ati ilu laamu lẹkun iwọ oorun ariwa ati aringbungbun arira Naijiria eyi to si n ṣe akoba fun ọrọ aje ati igbayegbadun awọn eeyan to n gbe nibẹ.

“Bakan naa, awọn iwa ijijagbara to n mu iwa ipa ati rogbodiyan dani latọdọ ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB/ESN lati kọlu awọn ohun idanimọ iṣejọba tiwantiwa bii dukia ajọ INEC, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ awọn ajọ alaabo ati dukia ijọba apapọ lọna ati da ibo apapọ ru lẹkun ila oorun gusu Naijiria.”

Ipe fun ipinya ẹya Yoruba kuiro lorilẹede Naijiria bẹrẹ si ni i goke lohun gooro lọdun 2021. Eekan ọmọ Yoruba ni, Sunday Igboho lo lewaju ipe naa.

Amọṣa, ariwo naa walẹ diẹ lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS kọlu ile rẹ lọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.

Aworan Ọga ọlọpaa NAijiria nibi ipade pẹlu awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, nigeria police

Erongba Sunday Igboho lati sa lọ soke okun ba ijakulẹ pade nigba ti awọn agbofinro gbe e ni papakọ ofurufu ni orilẹede Benin Republic fun oṣu diẹ ki wọn to gba oniduro rẹ.

Ọga ọlọpaa Naijiria rọ awọn ọlọpaa lati ṣiṣẹ wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ “labẹ ilakalẹ ofin eto idibo atawọn ofin miran.” Ti o si n fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo duro ṣinṣin lati rii pe eto idibo alaafia ti ko lẹjambakan ninu lo waye lọdun yii.