Afurasí méje wà ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá Eko fẹ́sùn ìṣekú pa Toyin Adeniji

Aworan Ben Hundeyin

Oríṣun àwòrán, Benjamin Hundeyin/facebook

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn afurasi meje ti wa ni atimọle fun ẹsun iṣeku pa Toyin Adeniji, oluranlọwọ fun agba ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Eko, Dapo Sarumi. Awọn ọlọpa sọ pe Adeniji ni wọn yinbọn pa ni agbegbe Agege ni ilu Eko ni ọjọ Aje. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, fidi isẹlẹ naa mulẹ ti o si fi kun pe iwadii ti bẹrẹ lori iwa ọdaran naa.

Ninu ọrọ rẹ, Hundeyin so wi pe “mo fe fi idi re mule pe Toyin Adeniji ni wọn yinbọn pa ni agbegbe Agege. “A mu awọn afurasi meje ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ iṣeku pani naa iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun".