‘Àlááfíà àti ìsọ̀kan ni a fẹ́ ní Naijiria’, Ẹ wo àwọn ohun táwọn Ọbalayé sọ fún Tinubu n'Ibadan

Aworan

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ṣepade pẹlu awọn ọbalaye ni ilu Ibadan.

Ipade naa n waye ṣaaju eto idibo gbogboogbo ti yoo waye lorilẹede Naijiria.

Awọn ọbalaye to sẹ ipade idankọkọ pẹlu Tinubu wa lati ilu Ekiti, Eko, Kogi, Kwara, Ogun, Ondo, Osun ati Oyo

Ojaja II, Ooni ti ile Ife ati Arole Oodua, Oba Adeyeye Eniitan Ogunwusi lo ṣaaju awọn ọbalaye naa.

Lẹyin ipade idakọnkọ ọhun ni Ọba Adeyeye Ogunwusi sọ fun awọn oniroyin ohun ti wọn fẹ lọwọ ijọba

Ọba Ogunwusi ni ohun to jẹ awọn ọbalaye logun lasiko yii ki bi alaafia ati irẹpọ pẹlu iṣọkan yoo ṣe jọba ni Naijiria.

Aworan

Bakan naa ni wọn beere fun eto aabo to peye lọwọ ijọba fun awọn araalu, paapaa ni ilẹ Yoruba.

Lori ọwọngogo epo bẹntirol, Ọba Adeyeye Eniitan Ogunwusi fi aidunnu rẹ han lori bi ọwọngogo epo bẹntirol ṣe fa rogbodiyan ni awọn ilu kaakiri ilẹ Yoruba to fi mọ ọwọngogo aini owo naira tuntun.

Awọn ọbalaye naa wa rrọ ijọba lati mu ayedẹrun fun awọn eniyan.

Aworan

‘’A o ri pe eto idibo to n bọ lọ ni irọwọrọṣẹ ‘’

Aworan

Ninu ọrọ rẹ, Ọba Adeyeye Eniitan Ogunwusi ni gbogbo awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba ni yoo ṣe atilẹyin fun eto idibo to n bọ naa.

Ooni ti Ile-ifẹ ni awọn yoo sa ipa awọn lati ba awọn araalu sọrọ ki wọn le jade lọgọọrọ lati dibo yan ẹni ti ọkan wọn fẹ.

Bakan naa ni awọn lọbalọba naa kesi Ajọ INEC to n risi eto idibo lati sa ipa wọn nipa ṣiṣe oun to tọ ati eyi ti o yẹ lasiko idibo naa.

Aworan

Akọroyin BBC wa nibi ipade naa jabọ pe awọn lọbalọba naa buwọlu oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe ijọba tiwantiwa larugẹ.

Awọn lọbalọba naa wa rọ ijọba to wa lode yii lati mu inira kuro lọrọ awọn araalu, ki wọn ṣe deede si awọn mẹkunu to dibo fun wọn, ki alaafia, idajọ ọdọdọ ati iṣọkan le jọba ni Naijiria.