‘A ti bẹ̀rẹ̀ ayẹwo òkú Whitney Adeniran láti mọ ohun tó pà á sí iléẹ̀kọ́ Chrisland’

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ apapọ awọn obi to ni akẹkọọ nile ẹkọ Chrisland School, nibi ti akẹkọbinrin kan, Whitney Adeniran ti gbẹmi mi, ti ṣe ipade pajawiri.
Nibi ipade naa ni wọn ti yannana awọn igbesẹ ti wọn ti gbe, lẹyin ti iṣẹlẹ iku ọmọbinrin naa ṣẹlẹ ati awọn igbesẹ mii ti wọn tun fẹ gbe.
“Pẹlu ọkan wuwo la fi n sọrọ ipapoda ọmọ wa daadaa, Whitney Adeniran ni ọjọ Kẹsan Oṣu Keji ọdun 2023 lakoko ayẹyẹ idije ojule-si-ojule ti wọn maa n ṣe lọdọọdun ni gbọngan iṣere Agege.
Awọn igbesẹ wa ta n gbe lori iku Whitney Adeniran - Ẹgbẹ Obi
Ẹgbẹ awọn obi naa ni, kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni awọn bẹrẹ oniruuru igbesẹ pẹlu awọn alaṣẹ to ga julọ ni ile ẹkọ naa, ti awọn si n tẹsiwaju ninu rẹ.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ awọn obi naa, Alufa ThankGod Oganwo fọwọ si lorukọ awọn alaga ẹgbẹ obi ati olukọ, wọn ṣe alaye pe awọn igbesẹ wa ti awọn ti n gbe lori ipapoda Whitney Adeniran.
Awọn koko ọrọ ti wọn fẹnuko le lori ti wọn si n gbe igbesẹ le lori ree
Awọn ẹgbẹ obi naa ni awọn ti n ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ to ga julọ ni ile ẹkọ Chrisland pẹlu erongba lati ni oye awọn nnkan to rọ mọ iṣẹlẹ ọjọ naa.
Bakan naa ni wọn ni awọn tun fẹ mọ awọ́n igbesẹ tawọn alasẹ ileẹkọ naa gbe kiakia lẹyin isẹlẹ naa.
Tun wẹ, wọn tun ti n finmu finlẹ lati mọ awọn igbesẹ tawọn alasẹ ile ẹkọ naa tun n gbe lọwọlọwọ.
Alufa Oganwo ni “A fẹ mọ pe ṣe wọn ba awọn obi oloogbe naa, Ọgbẹni ati Arabinrin Adeniran sọrọ lasiko ọhun.
Ati pe se wọn si fi iṣẹlẹ naa to awọn ileeṣẹ ijọba to tọ leti.
Ẹgbẹ awọn obi ati olukọ ti ṣaaju kan si awọn obi Whitney lori foonu, ti a si tun pada ṣe abẹwo si ile wọn lojukoju lati ba wọn kẹdun.
A wa fi da wọn loju nipa atilẹyin ẹgbẹ awọn obi han fun wọn, ni akoko ti wọn wa yii.














