Nigeria Election 2023: Tàni Peter Obi tí Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party?
Oríṣun àwòrán, AFP
Article Information
Author, Olivia Ndubuisi & Nduka Orjinmo
Role, BBC News, Lagos
Olowo onisowo nla to lamilaka, Peter Obi jẹ ọkan lara alagbara to jade dupo aarẹ Orilẹede Naijiria, to si n fi da awọn oludibo, paapa awọn ọmọ ogun to wa lori ayelujara pe ìjọba yoo mu ayipada deba Naijiria.
Naijiria jẹ Orilẹede kan to n wa olugbala ti yoo sẹgun awọn ìṣoro to n koju, awọn ọdọ lori ayelujara rí Peter Obi gẹgẹ bii olugbala, ti wọn si n ṣe atilẹyin fun ati ẹgbẹ oṣelu Labour Party níbi ifigagbaga pẹlu ẹgbẹ oselu meji to tun lorukọ.
Àkọlé fídíò, Peter Obi lori nnkan akọkọ to jẹ orilẹede Naijria logun
Ọna ti Obi n lo lati fi fa awọn eeyan mọra ni o fun lokiki, to si n fi da ọpọlọpọ loju pe
"Asiko ti to lati gba Orilẹede wa padà."
"Eto ìdibo ìdibo yii lo wa laarin ẹẹya ati ìjọ ati ẹẹya tuntun." O bẹ fún BBC.
Ọpọ igba ni orukọ Peter Obi ma le tete lori ayelujara lori ọrọ kan ti awọn alatilẹyin rẹ ba sọ, ti ẹ si dá wọn mọ pẹlu aworan Peter Obi tabi ti ẹgbẹ oselu rẹ.
Ọpọ awọn alátilẹyin rẹ ni wọn jẹ ọdọ ti wọn wa ni labẹ ọgbọn ọdun, tí wọn si pe ara wọn ni "Coconut Head generation" èyí to tun mọ "Awọn ọdọ to san lori" nitori wọn ṣe ara wọn lọkan, ti wọn ni ominira ọkan, tí wọn si bu ẹnu atẹlu awọn agbalagba oselu tí wọn ní wọn ṣe nkankan fun ilọsiwaju awọn ọdọ.
Diẹ lara wọn ni, Dayo Ekundayo lati ila oorun Owerri ni wọn kopa ninu iwọde Endsars to bu ẹnu atẹlu bi ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, Sars lọdun meji sẹyin, ti iwọde naa si tun pe fun ayipada ijọba.
Ni bayi, awọn ọdọ wọnyi n lo ọna ti wọn gba fi ṣe iwọde Endsars lati ko arawọn jọ, ti wọn si n kowo jọ lati ṣe atilẹyin fun Peter Obi, ẹni ti wọn gba gbọ pe o koju osuwọn ju awọn oludije meji lati ninu ẹgbẹ oṣelu to ti n ṣe ijọba lati ọdun 1999.
"Oloṣelu wo lo ti dipo mu, to si ni iwa ọmọluabi rẹ? N ko ri idi miiran fun awọn ọdọ orilẹede Naijiria," Ekundayo lo sọ eleyi.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọlé àwòrán, Pupọ awọn alatilẹyin Obi ni wọn kopa ninu ifẹhonuhan EndSars lọdun 2020
O ti kopa ninu iwọde fun Peter Obi, to si n pese ohun irinsẹ fun awọn akẹkọọ lati kopa ninu iponlogo fun Peter Obi bi o ṣe ṣe lasiko fẹhonuhan EndSars.
Sugbọn awọn alatako ni Obi jẹ oloṣelu oni magagebe, ọkan lara awọn to ma ṣa dide lasiko idibo pẹlu igbagbọ lati pin ninu agbara ẹgbẹ ti yoo gba agbara lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ti wa tẹlẹ.
Ọpọ awọn alatilẹyin lati ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ati awọn miiran to n fi oju sunukun wọ eto idibo ni wọn gba pe olori ni Peter Obi, to si koju osuwọn ju awọn oludije yooku lọ sugbọn ko ni okiki kakari orilẹede Naijiria lati bori eto idibo, ti wọn si kesi awọn alatiléyin rẹ pe ki wọn ma fi ibowọn sofo.
Wọn gbagbọ pe Obi jẹ ẹni to n ṣe idiwọ fun ọna lati le ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress kuro ni ijọba, to si ti pin ibo awọn alatako si ọna to pọ.
Olujọsin ijọ Aguda lati Ila oorun orilẹede Naijiria ni wọn ko ni okiki to peye ni ilu awọn Musulumi ni apa ariwa, nibi ibo wọn ti ṣe koko fun oludije to ba fẹ bori eto idibo.
Amọ Obi ati Igbakeji rẹ, Yusuf Datti Baba- Ahmed ti kopa ninu iponlogo ibo ni apa ariwa, eyi to so eso rere, ti ọpọ awọn araalu si jade lati kopa ninu ipolongo ibo naa nibi ti ọpọ ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ko ni ẹsẹ nilẹ rara, amọ awọn ero naa ni awọn oloselu le fi owo ra lati kopa ninu ipolongo ibo.
Awọn alatako rẹ tun wa bere pe n jẹ Obi setan lati soju bi iwajẹgurujẹra, eyi to bu ẹnu atẹlu yoo se wa sopin lẹyin ti orukọ rẹ jade ninu Pandora, eyi to tun asiri fifi ọrọp pamọ awọn olowo ati alagbara lọdun 2021.
Nigba ti wọn ko fi ẹnu pe o ji owo kan an, Obi kuna lati darukọ awọn dukia rẹ, to wa lakoso awọn mọlẹbi rẹ.
Wọn fi ẹsun kan Obi pe o lo owo ilu lati dokowo fun ileeṣ ẹnigba to jẹ gomina ipinlẹ Anambra. Obi ni irọ nla ni ọrọ naa, to si safihan bi idagbasoke ṣe ba owo rẹ.
Obi ti sọ ni ọpọ gba pe ko ṣe dandan fun oun lati di aarẹ, eyi jẹ ọrọ iyalẹnu lati ti ẹnu oloṣelu to ti parọ ẹgbẹ oṣelu nigba mẹrin ọtọtọ lati ọdun 2002.
O fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ni oku ọjọ ti eto idibo abẹle yoo waye ninu oṣu karun un ọdun to kọja, ti ẹgbẹ oṣelu naa si kede Atiku Abubakar, igbakeji aarẹ tẹlẹ gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oṣelu naa.
Oríṣun àwòrán, AFP
Àkọlé àwòrán, Igbakeji Obi, Yusuf Datti Baba-Ahmed, ni o jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ lati ipinlẹ Kadanu.
Awọn alatako rẹ ni o kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nitori o mọ pe oun ko le bori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP amọ pinnu lati kuro ninu ẹgbẹ o ti igbakeji oludije aarẹ lọdun 2019, to si morile ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Awọn alatako rẹ gbagbọ pe wọn le kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nitori o kọ lati lati fun awọn ọmọ ẹgbẹ ni owo abẹtẹlẹ ni bi eto idibo abẹle, ti wọn si gbe ọrọ yii jade: "A ko ki n fun eeyan lowo" fun bi o ṣe kuna lati san abẹtẹlẹ ati iwuwasi si rẹ sise owo ilu mọkunmọkun.
Wọn sapejuwe rẹ gẹgẹ oloselu ti ko gba igberege, to si setan lati koju ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ti ọpọ ti wọn tọwọ bọ owo ilu
Bakan naa ni ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya naa ni ipa ti wọn ninu yiyan Obi gẹgẹ oludije Aarẹ.
Ni orilẹede ti idaji awọn eeyan lo jẹ Kristẹni, awọn alatilẹyin ni reti pe eyi yoo ṣe anfani fun lati bori ibo aarẹ lẹyin ọdun mẹjọ ti Aarẹ MuhammadU Buhari, wọn ko fẹ Musulumi mọ gẹgẹ aarẹ- oludije APC Bola Tinubu tabi Atiku Abubakar ti PDP bo sori ipo aarẹ.
Ọpọ igba ni Obi ti kopa ninu ijọsin awọn ile jọsin kaakiri orilẹede Naijiria, ti awọn Kristẹni si ni oun ni oludije ti wọn yoo dibo fun ninu eto idibo to n bọ ninu o'su yii.
Eyi ti fa ọpọlọpọ awuye lati ọdọ awọn alatako rẹ pe o gbero lati mu iyapa waye pẹlu ọna to gbe iponlogo rẹ lọ si ile jọsin, Obi ni ọrọ naa koribẹ rara.
Awọn miiran ṣe atilẹyin fun Obi nitori ẹẹya to ti wa. Ẹẹya Igbo jẹ okan lara ẹẹya mẹta to tobi lorilẹede Naijira, amọ Naijria ni aarẹ lati ẹẹya ni ẹẹkan soso, to jẹ aarẹ ode lẹyin ti orilẹede Naijria gba ominra lọwọ orilẹede British lọdun 1960
Awọn ọmọ igbo ti fi ẹsun kan ijọba Naijria pe awọn yọ wọn ṣẹyin, ti wọn si lero pe Obi too dide si agbara lati fun apa guusu ila oorun, nibi ti pupọ wọn gbe , ti wọn si fẹ ri ohun idagbasoke eyi ti yoo koju ipe awọn ẹgbẹ adigbara Indigenous People of Biafra.
Awọn alatako ni Obi jẹ alatilẹyin IPOB, ẹgbẹ ti wọn dasilẹ to ṣe akoba fun Naijria, amọ o sọ fun BBC pe o gbagbọ ninu isọkan orilẹede Naijira ati pe iha toun kọsi ipe awọn to n pe fun ipinya Naijria ni pe awọn lati ba ijọba ni gbolohun, ki wọn si oju sunukun wọ ọrọ naa.
O ni oun kan to yẹ ko jẹ Naijiria logun ni ọrọ eto abo to mẹyẹ tori o di oun lemọlemọ , to si yẹ ki a gbogun ti.
"Ti a ba gbogun ti eto abo loni, a ti gbogun to oun ti ṣe idena fun awọn agbẹ wa lati ma lọ soko, to si mu fikun ba bi a ṣe pese ounjẹ," Obi salaye
Akẹkọọ jade Philosophy, o sise ni ileeṣẹ mọlẹbi ko to lọ ma ri owo fun ara rẹ, to n ko gbogbo nkan wọle lati oke okun ti a si ni awọn ileeṣẹ to n pese awọn nnkan wọnyi.
O le da olowo Naijiria mọ lati ọna jinjin sugbọn Obi da yatọ, to si wọ asọ rẹ pẹlu iyi.
O ni oun ni bata meji lati ile itaja Bristiah, to si nifẹ lati wọ asọ igba dọla si ti ẹgbẹrun mẹrin dọla ti Tom Ford, to si ma jẹ ẹru rẹ fun ara rẹ yatọ si pe ko fun eeyan lọwọ lati ba gbe.
Koda ko yọ awọn ọmọ silẹ. Ọmọ rẹ ọgbọn ọdun ni ko fun ni ọkọ ayọkẹlẹ, ti ọmọ to ku si jẹ olukọ ni ile ẹkọ akọbẹrẹ, eyi jẹ ohun iyalẹnu lorilẹede ti orukọ awọn oṣelu ti si ilẹku isẹ nla .
Awọn OBIdients
Pẹlu ẹsun lorisiri lori bi o ṣe owo ilu, saa Peter Obi gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Anambra jẹ ọkan gboogi ohun ti awọn na ika si ninu ipolongo ibo aarẹ to n ṣe.
Awọn alatilẹyin rẹ salaye pe o na owo nla si eto ẹkọ ipinlẹ naa ati pe o san owo awọn osisẹ lasiko- eyi to jẹ ohun ti awọn gomina lorilẹede Naijiria ko ki n kọbi ara si.
O fi ọpọlọpọ owo silẹ ninu apo ijọba ipinlẹ naa lẹyin saa ọdun mẹjọ rẹ gẹgẹ bi gomina.
Oríṣun àwòrán, AFP
Àkọlé àwòrán, Awọn alatilẹyin Obi jẹ ọdọ lati apa to laju lorilẹede Naijiria.
Sugbọn Frances Ogbonnaya, akẹkọọ ni ipinlẹ Anambra ni saa Peter Obi gẹgẹ bi Gomina jẹ ohun Iyalẹnu bi awọn araalu ṣe n kan sara si orukọ rẹ fun isẹ ribiribi to ṣe gẹgẹ bi gomina.
"Tani o fowo pamọ niwaju ebi? Tani o fowo pamọ niwaju kosikosi?
Sugbọn iwa ati iṣejọba Peter Obi lo fa ọpọlọpọ awọn alatilẹyin rẹ mọra ti wọn pe arawọn ni OBIdients.
Ọpọ wọn ni wọn ti fi ẹsun kan pe wọn sọrọ si awọn eeyan lori ayelujara, ti awọn si n pe ẹnikẹni ti ko ba ti dibo fun Peter Obi gẹgẹ bi ọta ilu.
Obi fesi pẹlu ọrọ kan to gbe sori ayelujara lati kesi awọn alatilẹyin rẹ lati ni ẹmi ibaraẹniṣepọ sugbọn ipa kekere ni ọrọ naa ko lọdọ awọn ololufẹ rẹ.
Ti ẹnikẹni ba sọ fun awọn alatilẹyin Obi pe eto idibo ko ki n ṣe nkan ori ayelujara, ni kiakia ni wọn yoo fesi pada pe pupọ awọn oludibo ni awọn jẹ ọdọ.
Amọ o le ma ri bẹ ti pupọ wọn ko ba jade lati dibo.
Pẹlu bi o ṣe ku ọsẹ diẹ ti eto idbo yoo waye, ko si aniani pe awọn eeyan waye lẹyin Obi sugbọn awọn onimọ ni bi ẹgbẹ oṣelu rẹ ko ni agbara kakiri lati orilẹede Naijiria lati ṣe atilẹyin fun sugbọn Obi ko ṣe fọwọrọsẹyin ninu eto idibo yii.
"Ilana yii ti pa wa mọ de ibi ti a wa yii, ilana yii ti ṣo wa di orilẹede ti iya ati isẹ n baja julọ, ilana yii ti sọ ọpọlọpọ ọmọ kuro ni ile ẹkọ, ilani yii ni a fẹ parẹ."
O tẹsiwaju pe ilana yii," Ọgọrun milọnu ọmọ Naijiria ni o gbe ninu isẹ ti eeyan milọnu marundinlogoji ọmọ orilẹede Naijiria ko mọ ibi ti ọunjẹ yoo ti wa".
Ti idaji awọn eeyan yi ba jaade lati dibo fun Peter Obi lọjọ ibo, o le jẹ ohun to nilo julọ.
Ó gba oyè nípa ìmọ̀ ìṣirò ní fásitì ìpínlẹ̀ Chicago (Chicago State University)
Ó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko fún sáà méjì láti 1999 sí 2007
Ó ṣojú [wọ̀ Oòrùn ìpínlẹ̀ Eko ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láti 1992 sí 1993.
Ó jẹ́ èèyàn kan tó ti pẹ́ nhí ìdí òṣèlú Nàìjíríà, ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò du ipò ààré nìyí.
ìgbógun ti ìṣèjọba sójà
Mú ìdàgbàsókè bá owó tó wọlé fún ìpínlẹ̀ Eko ní ọ̀nà tó ju ìlọ́po mẹ́rin lọ láti N22.2 blilion ní 1999 sí N220.9 bíllion ní 2007.
Ó ṣiṣẹ́ bíi ọ̀gá tó ń ṣe àyẹ̀wò ìwé owó, lẹ́yìn náà ló ṣe iṣẹ́ akápò ní iléeṣẹ́ Mobile Producing Nigeria, ọ̀kan lára iléeṣẹ́ epo tó tóbi jù ní Nàìjíríà.
Láti ṣé àlékún ọjà tí Nàìjíríà ń tà síta àti láti dín ìgbẹ́kẹ̀lé Nàìjíríà kù lóríiohun òkèrè.
Láti sọ àìníṣẹ́ ṣe láàrin àwọn ọ̀dọ́ di ìlàjì láàrin ọdún mẹ́rin àti láti pèsè iṣẹ́ mílíọ́nù kan nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀pútà láàrin ọdún méjì.
Mú àyípadà bá ètò ìdájọ́ kó lè mójútó ìdènà ìrúfin àti ṣe àlékún ìfọkàntán lórío àwọn agbófinró.
Atiku Abubakar
Peoples Democratic Party (PDP)
Ọjọ́ orí: 76
Igbákejì ààrẹ Naìjíríà láti ọdún 1999 sí 2007.
Ó kàwé gboyè eléèkejì (masters) lórí àjọṣepò àwọn orílẹ̀èdè (International Relations) láti fásitì Anglia Ruskin University , UK.
Ó jẹ́ ẹni tó ṣe iṣẹ́ aṣọ́bodé rí kó tó di olóṣèlú láti nǹkan bíi ọdún 1980.
Ó du ipò ààrẹ náà ní ẹmaàrú ùn ní ọdún 1993, 2007,2011, 2015 àti 2019, ṣùgbọ́n kò wọlé.
Òun ló dá fásitì Amẹ́ríkà ti Nàìjíríà (American University of Nigeria) silẹ̀, fasitì náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́.
Oníṣòwò tó ṣe àṣeyọrí tó ní okòwò níbi ọ̀rọ̀ epo, ọ̀gbìn, bánkì àti ògùn.
Ètò títa iléeṣẹ́ ìjọba tó ní àríyànjiyàn nínú.
Fún àwọn aládáni ní ipa tó pọ̀ nínú ètòi ọrọ̀ ajé.
Fún ìṣọ̀kan orílẹ̀èdè ní agbára síi nípa ìṣe déédéé àti ìdájọ́ òdodo láàrin àwọn ẹ̀yà tó ń gbé ní Nàìjíríà.
Ṣe àtúntò ètò ìṣèjọba Nàìjíríà.
Peter Obi
Labour Party
Ọjọ́ orí: 60
Gómìnà tó ṣe sáà méjì ní ìpínlẹ̀ Anambara láti ọdún 2007 sí ọdún 2014.
Ó du ipò igbákejì ààrẹ ní ọdún 2019.
Oníṣòwò tó kàwé gboyè nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọgbọ́n (Philosophy) ni University of Nigeria Nsukka.
"o bá ìpínẹ̀ rẹ̀ dá okòwo ''sub soveriegn wealth fund '' tó tó $156 million ní ìgbà tó fẹ́ fi orí oyè sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà.
Ó gbé ìpínlẹ̀ Anambara lọ sí ipò kínní láti ipò kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà lórí ìdánwò NECO àti WAEC.
Ó ní àwọn ṣọ́ọ̀bù alágbàtà kan tó fún ẹgbẹgbẹ̀rún èèyàn ní iṣẹ́.
Ó ṣèlérí láti kó àkóyawọ́ la'ti ríi pé ìjọba gbógun ti ìwà àjẹbánu.
Ó ṣèlérí láti gbé Nàìjíríà dé ibi ṣíṣe nǹkan láti ibi lílo nǹkan.
Ó ṣèlérí láti gbé ọlá fún ìdàgbàsókè àwọn èèyàn nípasẹ̀ fífi owó sí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́sì, ètò ìlera àti àwọn nǹkan amáyédẹrùn.
Rabiu Kwankwaso
New Nigeria Peoploes Party (NNPP)
Ọjọ́ orí:66
Mínísítà fún ètò ààbò láti ọdún 2003 sí ọdún 2007
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano láti ọdún 1999 sí ọdún 2003, àti láti ọdún 2011 sí ọdún 2015.
Ó ṣojú agbègbè Madobi ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin n;i ọdún 1992 àti ààrin Kano ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2019.
Ó kàwé gboyè PhD ní orí ìmọ̀ ẹ̀rọ ilé kíkọ́ láti fásitì Sharda ní India.
Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ìtọrẹ.
Ó ṣe àfikúnb iye àwọn tó wọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ láti mílíọ́nù kan lọ́dún 2011 sí mílíọ́nù mẹ́ta ní ọdún 2015 nígbà tó kúrò lórí oyè.
Ó pèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ àti aṣọ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀.
Ó dá fásitì Sáyẹ́nsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìpínlẹ̀ Kano sílẹ̀ ní Wudil sílẹ̀. Ó tún dá Northwestern University sílẹ̀. Àwọn fásitì ìpínlẹ̀ Kano méjéjì.
Ó ṣe ìlérí láti pèsè iṣẹ́ nípasẹ̀ ìdókòwò lórí ètò ọ̀gbìn.