Ìdìbò yóò wáyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí owó níta tí àwọn èèyàn sì ń fẹ̀hónúhàn – INEC

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters
Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti sọ pe onyẹ kan ko ni yẹ eto idibo gbogbo ti yoo waye ninu loṣu yii bo tilẹ jẹ pe ko si owo lode, ti ọpọ araalu si n fẹhonuhan.
Lẹyin ti CBN tẹ owo ₦200, ₦500 ati ₦1000 tuntun ni ọpọ ọmọ Naijiria ti ko sinu hilahilo latari aisi si owo naa nigboro.
Iṣẹlẹ naa si ti mu ki ọpọ eeyan maa ro pe o ṣeeṣe ki ijọba sun eto idibo to yẹ ko waye siwaju nitori wahala naa.
Amọ alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ti ni ki awọn eeyan lọ fi ọkan wọn balẹ nitori ko si ohun ti yoo yẹ eto idibo naa.
O ni “CBN ti fi da wa loju pe akoba kankan ko ni waye nitori ọrọ owo ọhun, nitori naa, ko si wahala.”

“Nipa ohun to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria nipa ifẹhonuhan, ọrọ eto abo niyẹn, awọn eleto abo si ti fi da wa loju pe awọn yoo daabo bo gbogbo awọn agbegbe ti idibo yoo ti waye kaakiri Naijiria.”
Alaga INEC ọhun tun rọ awọn agunbanirọ ti yoo ṣiṣẹ lọjọ naa lati ṣe olootọ si awọn ọmọ Naijiria lọjọ idibo dipo awọn oloṣelu.
O pari ọrọ rẹ pe awọn yoo tọpinpin awọn agunbanirọ to ba lo ẹrọ BVAS lọjọ naa lati le ṣiro iṣẹ ti wọn ṣe.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọlọ́pàá 400,000 ni a ó dà sáàrín ìgboro lásìkò ètò ìdìbò ọdún yìí – Iléeṣẹ́ ọlapàá

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ni bayii ti eto idibo gbogbogbo Naijiria ku nnkan bii ọsẹ kan, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun ti gbaradi lati pese abo to peye fun idibo naa.
Agbẹnuṣọ ileeṣẹ naa ni olu ilu Naijiria, Abuja, DSP Josephine Adeh lo sọ beẹ fun BBC.
O ni awọn ti fọwọsowọpọ pẹlu ajọ eleto idibo, INEC, atawọn ajọ eleto idibo miran lati ri daju pe ko si wahala kankan lasiko eto idibo ọhun.
Josephine ni “Awọn oṣiṣẹ wa atawọn ẹṣọ alabo miran ti gba idanilẹkọ daadaa nipa bi wọn ṣe le pese eto abo to dantọ.”
Agbẹnusọ ọlọpaa naa sọ pe ki eto idibo to bẹrẹ lawọn yoo ti ran awọn ọlọpaa si ibudo idibo lati daabo awọn oṣiṣẹ INEC, to fi mọ awọn oludibo.
Yatọ si ipese abo, o ni awọn yoo tun ṣewadii awọn ibi ti wahala ti le bẹ silẹ lati tete pana irufẹ wahala bẹẹ ko to bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @cleenfoundation
Ọlọpaa 400,000 ni a o da si igboro
DSP Adeh sọ siwaju si pe “A o ko ọpọ awọn ọlọpaa saarin igboro ilu Abuja lasiko eto dibo naa.”
“Gẹgẹ bi ohun ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa sọ ṣaaju, yoo le ni ọlọpaa 400,000 ti a o da si igboro kaakiri Naijiria lasiko eto idibo ọhun.”
O fi kun pe ileeṣẹ ọlọpaa n ṣagbeyẹwo bi awọn eto idibo to kọja ṣe lọ lati kọgbọn nipa bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ ninu eto idibo ọdun yii.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa ti ko ba si lẹnu iṣẹ lọjọ idibo naa yoo lanfani lati lọ dibo fun oludije ti ọkan wọn n fẹ.
Josephine ni eyii ko tii ṣẹlẹ rara lawọn eto idibo to ti waye sẹyin ni Naijiria.












