Ìkanra ipò olùdíje ààrẹ tí Emefiele kò rí gbà ló fi gbé ètò ‘Naira design’ jáde láti ba iṣẹ́ jẹ́ fún APC - Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu/ facebook
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ke si aarẹ Buhari pe ko ba gomina banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele pe ko yi eto pada lori eto ayipada owo naira to n gun le.
Gomina Akeredolu sọ ọrọ yii lasiko to fi n gbalejo ẹka ọdọ igbimọ ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC to kan sii ni ọfiisi rẹ nilu Akurẹ.
O ni kii ṣe iru asiko yii ti idibo n sunmọ lo yẹ ki ijọba apapọ maa gbe iru ilana bẹẹ bii ọwọngogo owo naira jade eyi to n mu inira ba omilẹgbẹ ọmọ Naijiria.
Iyi ẹgbẹ oṣelu APC ti n wa silẹ nitori inira ilana Owo tuntun ati ọwọngogo epo to n waye lasiko yii -Akeredolu
Gomina Akeredolu ni ko si aniani pe eto naa ti mu ọpọlọpọ inira ba araalu, ti o si ti tipasẹ bẹẹ bi adinku nla ba iyi ẹgbẹ oṣelu naa laarin awọn oludibo.
O ni iyanu nla lo jẹ pe pẹlu pe ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria gbe idajọ kalẹ pe ki wọn so eto naa rọ naa, ‘gbogbo wọn lo n hu iwa bii pe ko si idajọ kankan nilẹ’.
“A ti sọ tẹlẹ pe ki wọn yọ ọgbẹni yii kuro nipo nigba to ti dije du ipo aarẹ. Arakunrin yii ko tọ fun ipo yii mọ. Eeyan to gbiyanju lati di aarẹ fẹ yi wa lagbo da si ina bayii.”
Gomina ipinlẹ Ondo ni ohun to yẹ ki ijọba ati Banki apapọ Naijiria ṣe ni pe ko jẹ ki owo tuntun ati eyi to wa nilẹ tẹlẹ ṣi maa lọ ni ifẹgbẹkẹgbẹ titi ti wọn yoo fi le e pin owo tuntun naa kari.
O niyiyan ti ẹgbẹ yan Aṣiwaju Ahmed Tinubu gẹgẹbi oludije si ipo aarẹ rẹ kii ṣe aṣiṣe rara bẹẹni kiiṣe nitori pe awọn jumọ wa lati ẹya kan naa, bikoṣe nitori atimaaṣebọ rẹ.












