Kére ooo! Oyo, Eko, Ogun atàwọn ìpínlẹ̀ míràn yóò dojúkọ ìṣẹ̀lẹ̀ òmíyale, àyàfi...

Flooding in Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita fun ọrọ omi, Suleiman Adamu ti kilọ pe awọn agbegbe ijọba ibilẹ 178 ni awọn ipinlẹ mejilelọgbọn pẹlu olu ilu Naijiria, Abuja (FCT) wa lara awọn agbegbe ti o ṣẹṣẹ ki isẹlẹ omiyale ti waye lọdun yii.

Suleiman lo fi ikilọ na lede nibi ipade apero awọn akọroyin ni Abuja

O ni awọn asọtẹlẹ ajọ to woye oju ọjọ, Nigeria Hydrological Service (NIHSA) ṣe afihan bi oju ọjọ yo ṣe ri lọdun yii.

Suleiman ni, awọn asọtẹlẹ oju ọjọ fun ọdun 2023 fihan pe ijọba ibilẹ 178 ni awọn ipinlẹ mejilelọgbọn pẹlu ilu Abuja wa lara awọn ipinlẹ to ṣẹṣẹ ki isẹlẹ omiyale waye.

O ni ijọba ibilẹ 224 ninu ipinlẹ marundinlọgoji wa lara awọn agbegbe ti o ṣẹṣẹ ki iṣẹlẹ omiyale ma waye.

Ipinlẹ mejilelọgbọn lorilẹede yii yoo ni iriri omiyale

“Awọn ipinlẹ ti oseṣee ki iṣẹlẹ Omi yale ti ṣẹlẹ ni Adamawa, Abia, Akwa Ibom, Anambra, Bauchi, Bayelsa, Benue, Cross River, Delta, Ebonyi, Ekiti, Edo, Gombe, Imo, Jigawa, Kaduna, Kano, Kebbi, Kogi, Kwara , Lagos, Nasarawa, Niger, Ogun, Ondo, Osun, Oyo, Rivers, Sokoto, Taraba, Yobe, Zamfara and the FCT.

Adamu sọ pe ipele iṣẹlẹ omiyale na lo ṣẹṣẹ ko waye laarin oṣu kẹrin si oṣu kọkanla ọdun yii ti o si le ṣakoba fun awọn nnkan ọgbin, ẹran ọsin,awọn ohun amayedẹrun ati ayika. “Apakan ijọba ibilẹ 66 ni orilẹ-ede yii wa lara awọn agbegbe ti o ṣẹṣẹ ki ẹkun omi ti waye laarin oṣu kẹrin si oṣu kẹfa.

Nigba ti awọn ijọba ibilẹ 148 ninu oṣu Keje, Oṣu Kẹjọ ati Oṣu Kẹsan, na yo ni ipenija omi yale ti ijọba ibilẹ ọgọrun na o dojukọ iṣoro omiyale ni aarin oṣu Kẹwa si oṣu kọkanla ọdun 2023.

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adamu ṣalaye pe Bayelsa, Cross River, Delta, Edo, Lagos, Ogun, Rivers ati Ondo, yoo ni iriri ikun omi nitori ilosoke omi okun eyi ti yoo ni ipa lori pipa ẹja ati irinajo ori omi.

Minisita na pe gbogbo awọn ti ọrọ kan, láti tete tẹpẹlẹ mo bi wọn yo ṣe dena iṣẹlẹ omiyale lọdun yii.