“Ó ṣe pàtàkì láti ṣàfihàn ìbálòpọ̀ nínú fíìmù àgbéléwò nítorí...”

Oríṣun àwòrán, @ bolajiogunmola
Oṣere tiata, Bolaji Ogunmola ti sọ pe o bojumu ki wọn ṣafihan ibalopọ ninu sinima nigba mii lati le sọ itan naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Ogunmola lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch.
O ni “Mo gbagbọ pe ṣiṣafihan ibalopọ ṣe pataki nigba miran lati le ṣalaye ipa ti oṣere n ko ninu fiimu.”
“Ko ṣeeṣe ki eeyan maa sọ itan nipa awọn to n ṣiṣẹ nọbi tabi awọn to maa n ṣi ara wọn silẹ ki awọn oṣere bẹẹ si wọ aṣọ to bo ara wọn.”
“Ti itan irufẹ ere bẹẹ ba nilo ibalopọ, mo gbagbọ pe o yẹ ki wọn ṣafihan rẹ.”
Oṣere naa tẹsiwaju pe “Ti tiata naa ba jẹ eyii ti itan rẹ munadoko, awọn eeyan ko ni ranti nipa ibalopọ to wa ninu rẹ, bi ko ṣe ọgbọn to kọ wọn.”
Ogunmola, to jẹ ọkan lara awọn to kopa ninu ere “Before Valentine” sọ pe inu oun dun bi awọn araalu ṣe tẹwọgba ere ọhun.
O ni “Ohun iwuru ni ti awọn araalu ba tẹwọgba ohun ti eeyan n ṣe.”
“Iriri nla lo jẹ fun mi lati kopa ‘Chika’ ninu ere naa.”
Ta ni Bolaji Ogunmola?
Bolaji ogunmola jẹ ọkan lara awọn oṣere tiata ti irawọ wọn ṣẹṣẹ n milẹ titi lagbo oṣere ni Naijiria.
O kẹkọọ jade ni fasiti Ilorin, Unilorin ati fasiti ijọba apapọ, National Open University Of Nigeria.
Lara awọn ere ti Ogunmola ti kopa ni Tough Love, Sobi's Mystic, All Shades of Wrong, Okon Goes to School, Tempted, Outcast, Out of Luck, On Bended Knees ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lọdun 2020, wọn fa orukọ rẹ kalẹ fun ami ẹyẹ oṣere ti irawọ rẹ n milẹ titi, iyẹn nibi ami ẹyẹ ‘Best of Nollywood Awards.’












