Fadeyi Oloro di aláìrílégbé, bú sẹ́kún bí pásítọ̀ Tobi Adegboyega ṣe ṣèrànwọ́ ₦3m fún un

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR
Pasitọ ọmọ Naijiria to n fi ilẹ Gẹẹsi ṣebugbe, Tobi Adegboyega, ti ṣeranwọ owo miliọnu mẹta naira fun agba oṣere tiata Yoruba Yoruba, Fadeyi Oloro.
Adegboyega, to jẹ pasitọ ijọ Salvation Proclaimers Anointed Church to wa niluu London gbe igbesẹ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu Fadeyi Oloro loju opo ikansiraẹni agbohunsafẹfẹ, Daddy Freeze.
Eyii ko ṣẹyin aisan ọlọjọ pipẹ to ti n ba agba oṣere naa finran fun nnkan bii ọdun mẹta, ati bi wọn ṣe le kuro ninu ile to n gbe.
Lasiko ifọrọwerọ ọhun to waye loju opo Instagram Daddy Freeze ni Fadeyi Oloro ti rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ ki pasitọ Adegboyega to darapọ mọ wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti Adegboyega sọ, o ni o ti pẹ ti oun ti mọ Fadeyi Oloro, o si jẹ ọkan lara awọn oṣere ti oun rati daadaa lasiko ti oun n dagba.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo fi miliọnu mẹta naira ṣọwọ si agba oṣere naa.
Wayi o, Daddy Freeze ti kede pe pasitọ Adegboyega ti fi owo to ṣeleri ranṣẹ, oun si ti fi owo ọhun ṣọwọ si awọn mọlẹbi Fadeyi Oloro pẹlu owo mii ti awọn araalu kojọ.
“Lati ọdun mẹta sẹyin ni baba ti n ṣaisan”
Lasiko ifọrọwerọ naa ni ọmọbinrin Fadeyi Oloro ti ṣalaye pe lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni agba oṣere ọhun ti n ba aisan finra.
O ni “O ti le ni ọdun mẹta ti baba ti n ṣaisan, amọ pẹlu iranlọwọ Ọlọrun atawọn eeyan kan layika, a n gbe baba lọ sile iwosan.”
“A ti ta ọpọlọpọ nnkan bii ọkọ ayọkẹlẹ... bi a ṣe n sọrọ yii, baba ko nile lori, koda, ẹni to ni ile to n yagbe ti fun ni iwe pe ko kuro ninu ile naa laarin oṣu mẹfa.”
“A gbe baba lọ sile iwosan UCH to wa ni Ibadan... wọn ni aisan kidinrin atawọn aisan miran lo n ba baba finra.”
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn agbo kan ti Fadeyin Oloro ti mu sẹyin lo ṣakoba fun kidinrin rẹ.
Lẹyinorẹyin, bi ifọrọwerọ naa ṣe n lọ lọwọ ni Daddy Freeze gbe pasitọ Tobi wọle sori eto ọhun, pasitọ Tobi si ṣeleri miliọnu mẹta naira fun itọju Fadeyi Oloro, o ti si fi owo naa ranṣẹ ki a to maa ko iroyin yii jọ.












