Greece Train Collision: Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá nínú rélùwéè méjì tó forí ṣọra wọn sọ ohun tí ojú wn rí

Rélùwéè méjì forí sọra, èèyàn 32 kú, ọ̀pọ̀ fara pa

Reluwee meji fori sọra

Eeyan mejilelọgbọn ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọlọpọ mii si farapa ninu ijamba ọkọ oju irin to waye ni orilẹ-ede Greece.

Ijamba naa lo waye nigba ti ọkọ ojurin meji kọlu ara wọn ní ẹba ilu Larissa lasalẹ ọjọ Isẹguin.

Awọn oṣiṣẹ adola ẹmi si ti ń ṣiṣẹ takuntakun lati doola ẹmi awọn to farapa ati awọn to seese ki wọn ha sinu ọkọ ojurin naa.

Ọkan lara awọn to wa ninu ọkọ reluwe naa nígbà tí iṣẹlẹ ọhun waye, Stergios Minenis ni oun fo jade ninu ọkọ ojurin ti oun wa ni, nigba ti oun gbọ ariwo nla.

Stergios ni ọkọ ojurin ti oun wa takiti, ti o si dawo si apakan, lẹyin eyi ni ariwo nla sọ, ti awọn okun ina ọkọ naa si gbana lẹsẹkẹsẹ.

O ni bi ọkọ naa ti ń takiti ni ina n jo ni gbogbo ayika inu ọkọ reluwe naa.

Reluwe gbina

Oríṣun àwòrán, Reuters

"Gbogbo ibujoko ninu reluwe lo gbina, ẹjẹ kun ara ọpọ eeyan, a fẹ fo jade lati oju ferese"

Ọkan lara awọn arinrin-ajo to wa ninu ọkọ naa ni, bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni gbogbo gilaasi ọkọ ojurin naa fọ, eyi si lo mu ki ẹru bawọn eeyan, ti ọpọlọpọ si figbe ta.

Minenis ni awọn lakaka lati gba oju ferese jade, ti awọn ko si ni anfani yíi nitori gbogbo ibi ijoko si wọn lo gbana lẹsẹkẹsẹ.

Angelos Tsiamouras ni iṣẹlẹ na dabi iṣẹlẹ ilẹ riri, Lazos ni oun ko farapa ṣugbọn awọn to wa layika oun farapa, ti ẹjẹ wọn si yi oun lara

Ọkọ ojurin naa lo jẹ ọkọ ero to gbera ni Athens lo si Thessaloniki nígbà tí iṣẹlẹ naa waye.

Iṣẹlẹ yii lo jẹ eyi ti o buru julọ ni Greece gẹgẹ bi akọsilẹ, bẹẹ si ni ohun to fa iṣẹlẹ naa ko ti ye awọn alaṣẹ .

Ọkọ̀ ojú omi dànù lórí òkun, èèyàn 100 kú
Aworan

O to ọgọrun un eeyan pẹlu awọn ọmọde to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ oju omi doju bolẹ ni agbegbe guusu orilẹede Italy.

Lọwọlọwọ bayii, o to ọmọ ajeji mẹtalelọgọta ti wọn di rẹ mulẹ pe wọn ti ku pẹlu awọn ọmọde mejila to ni ikoko ninu.

Ọkọ oju omi naa lo ko ero toto igba, to si danu ni agbegbe Crotone lọjọ Aiku.

Olootu ijọba ilẹ Italy, Giorgia Meloni, ti rọ ajọ agbaye lati gbe igbesẹ ti yoo fi opin si irinajo awọn arinrinjo si orilẹede naa lati ori okun.

Awọn musulumi n gbadura ni iboji oku awọn to ku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn asọbode ni eeyan ọgọrin ni awọn sawari laaye

Ọkọ oju omi naa lo gbera lati orilẹede Turkey pẹlu awọn eeyan lati orilẹede Afghanistan, Pakistan, Somalia, Syria, Iraq ati Iran.

Gẹgẹ bi Minisita fun ọrọ okeere fun Pakistani ṣe sọ, eeyan mẹrindinlogun lati orilẹede naa ni ori ko yọ, ti eeyan mẹrin si sọnu.

Awọn asọbode ni eeyan ọgọrin ni awọn sawari laaye.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ofin gbe ọkan lara awọn eeyan to ye isẹlẹ naa lori ẹsun fifi ọna ẹburu wọ orilẹede naa, ti wọn si bẹrẹ si ni sawari awọn oku ninu okun naa.

Ọmọdekunrin kan, ẹni ọdun mẹrindinlogun padanu ẹgbọn rẹ obinrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn lasiko ikọlu naa.