Wo àwọn ìpèníjà márùn ún tí Tinubu yóò dojúkọ gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Gbogbo ipele tuntun ti eeyan ba de nile aye lo maa n mu oniruru ipenija wa.
Eyii lo difa fun Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu.
Lati igba ti ajọ eleto idibo, INEC, ti kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ to waye lopin ọsẹ to kọja lawọn araalu ti n woye iṣoro ti yoo jogun ba ninu ipo tuntun naa.
BBC ṣe akojọpọ awọn ipenija marun un ti Aarẹ tuntun naa yoo dojukọ ninu iṣejọba rẹ.
Ọwọngogo owo nairan tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN
Ipenija akọkọ ti Tinubu yoo dojukọ ni aisi owo naira tuntun nigboro.
Ọpọ araalu lo gbagbọ pe nitori eto idibo Aarẹ to kọja ni ijọba apapọ ṣe ko naira pamọ ki awọn oloṣelu ma baa fi ra ibo, amọ ni bayii ti idibo ti pari, awọn araalu ko tii ri owo naa.
Ṣaaju ni CBN ti kọkọ ko owo atijọ kuro nilẹ, to si tẹ owo tuntun, eyii ko ṣẹyin bo ṣe ni ida 80% owo naira lo wa lọwọ araalu ti ida 20% pere si wa ni banki.
O ni idi eyii loun ṣe tẹ owo tuntun ki awọn owo to wa lọwọ awọn araalu le pada si banki.
Amọ o ṣeni laanu pe lati igba ti wọn ti bẹrẹ igbe ọhun sẹ tuntun lawọn araalu ti n jiya, ti ọpọ eeyan, to fi mọ awọ arugbo fi n lo aimoye wakati ni banki lai ri owo wọn gba.
Ti ẹ ko ba gbabe, gomina ipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai, sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan pe 2.3 tiriliọnu naira ni CBN ti gba pada lọwọ araalu to si ko nnkan bii 300 biliọnu naira jade, eyii ti ko to.
Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti n woye lori ohun ti Tinubu yoo ṣe lori ọrọ owo ọhun.
Yiyọ owo iranwọ ori epo bẹtiro

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipenija nla miran ti Tinubu yoo dojukọ ni ọrọ iranwọ epo, ‘subsidy.’
Lati ti igba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti gori alefa ni ọrọ iranwọ owo epo ti n jẹyọ lori boya ki wọn fopin si iranwọ naa tabi bẹẹ kọ.
Ọpọ awọn onwoye ohun to n lọ lo gbagbọ pe anfani nla ni yoo jẹ fawọn ọmọ Naijiria ti ijọba ba fopin si owo naa, bẹẹ lawọn mii gbagbọ pe ọpalanba iya yoo jẹ awọn ọmọ Naijiria ti ijọba ba ṣe bẹẹ nitori iye owo ti wọn yoo maa ta epo yoo ti wọn ju.
Amọ ṣa, Tinubu ti sọ ṣaaju pe oun yoo yọ afikun owo ori epo naa ti oun ba de ipo Aarẹ.
Boya Tinubu yoo mu ileri rẹ ṣe tabi bẹẹ kọ, oju gbogbo ọmọ Nijiria wa lara rẹ.
Iye owo ti wọn n ta dollar ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, others
Ojojumọ ni iye owo ti awọn eeyan n ra dollar si nairia n lọ soke si ni Naijiria.
Eyii ko ṣẹyin awọn ilana kan ti CBN gbe kalẹ, bo tilẹ jẹ ọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, CBN kọ lati yi awọn alakalẹ naa pada.
Ki ijọba APC to de ori alefa, owo dollar kan ko to igba naira, amọ bayii, o ti le ni ẹẹdẹgbẹrin naira.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti iṣẹ tabi owo wọn ni ṣe pẹlu owo dollar Amẹrika yii yoo maa reti ayipada tuntun lori ọrọ owo na ninu iṣejọba Tinubu.
Iṣẹ ati oṣi to n ba ọpọ araalu finra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Atẹjade kan lati ọdọ banki abaye sọ pe nnkan bii miliọnu marundinlọgọrun eeyan ni iṣẹ n ba finra ni Naijiria.
Atẹjade yii ko jina si ootọ ni Naijiria nitori ọpọ eeyan lo ṣoro fun lati ri ounjẹ oojọ wọn jẹ.
Lootọ ni pe ajakalẹ arun Corona to kọlu gbogbo agbaye ṣakoba fun ọpọ orilẹ-ede, amọ pupọ awọn orilẹ-ede naa lo ti n gbera pada.
Ni bayii ti Tinubu yoo di Aarẹ tuntun, ọpọ araalu ni yoo maa woye bi ijọba rẹ yoo ṣe din iṣẹ ati iya ku lawujọ.
Awuyewuye lori ọrọ ẹsin

Oríṣun àwòrán, CAN
Eto idibo ọdun yii mu iyapa wa laarin awọn Musulumi lati iha Ariwa atawọn ọmọlẹyin Kristi ni iha Guusu.
Awuyewuye na bẹrẹ nikete ti Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC kede Kashim Shettima, ti awọn mejeji jẹ Musulumi, gẹgẹ bii igbakeji rẹ.
Ọpọ awọn eeyan, paapaa lati inu ẹgbẹ alatako lo sọ pe ‘Muslim-Muslim ticket’ naa ko tọ fun orilẹ-ede bii Naijiria.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan n sọ, ọpọ awọn to ṣatilẹyin fun Tinubu ṣe bẹẹ nitori ẹya ati ẹsin, bẹẹ naa lawọn to tẹle Peter Obi ṣe.
Ṣugbọn Tinubu funra rẹ ti sọ pe oun kii ṣe ojuṣaju nipa ti ọrọ ẹsin, eredi ree ti iyawo oun ṣe jẹ igbakeji alufaa nile ijọsin.
Wo ohun márùn ún tó le yípadà tí Tinubu bá dépò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @BATofficial
Wọn ti kede Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Naijiria.
Nibayii ti wọn si ti kede rẹ, ọpọ ayipada ni yoo de ba igbe aye rẹ ati gbogbo awọn to ba yii ka. Idi si ni yii ti a fi gbe awọn ohun marun un ti o ṣeeṣe ko yaipada nipa oun at’awọn to yii ka yẹwo .
Ipo Sẹnetọ tabi first Lady, ewo ni Oluremi Tinubu yoo di mu?
Sẹnetọ ni iyawo Asiwaju Bola Tinubu, oun lo si n ṣoju ẹkun idibo Lagos Central.
Nibayii ti ọkọ rẹ n lọ si ile agbara gẹgẹ bi aarẹ, o daju pe iyawo pẹlu yoo wa pẹlu rẹ gẹgẹ bi obinrin akọkọ iyẹn “first lady”.
Tinubu funrararẹ ti sọ eyi pe ki awọn aṣofin agba maṣe reti iyawo oun mọ laarin wọn.
Remi Tinubu ko dije fun ipo Sẹnetọ lopin ọsẹ to kọja.
Adebule Idiat (Lagos West) ati Sanni Ẹshinlokun (Lagos Central) ni yoo maa ṣoju ipinlẹ Eko ni ile aṣofin.
Eyi fihan pe Sanni Ẹshilokun ni yoo maa rọpo Rẹmi Tinubu nile asofin agba naa bayii.
Bourdillion: Ṣe yoo ṣi di ipo agbara mu?
Bi Tinubu ba de ipo aarẹ tan, iwọnba ni irin rẹ sì ile rẹ nilu Eko, ti ọpọ mọ si Bourdillion yoo jẹ.
Idi ni pe ile apata agbara Aso Rock Villa ni yoo maa gbe julọ.
Bi o tilẹ wu Tinubu lati maa wa sibẹ loorekoore, awọn ẹṣọ alaabo Secret Service ko ni fi aye rẹ silẹ fun un.
Eyi tumọ si pe eto abo rẹ gẹgẹ bi aarẹ, igba kọọkan bi asiko akanṣe ayẹyẹ, ni o le e maa wa nibẹ.

Aarẹ ọmọ Yoruba akọkọ ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ Ogun
Lati igba ti orilẹede Naijiria ti n ni olori gbogbo, awọn adari rẹ to wa lati ilẹ Yoruba ni wọn n jẹ ọmọ ipinlẹ Ogun.
Awolọwọ jẹ minisita feto isuna ati igbakeji ijọba ologun labẹ Yakubu Gowon Ikenne nipinlẹ Ogun.
Olusẹgun Obasanjọ lati ilu Owu ni Abeokuta naa jẹ olori ijọba ologun ati aarẹ fun ọdun mẹjọ laarin ọdun 1977 si 1979, ati ọdun 1999 si 2007.

Oríṣun àwòrán, Obafemi Awolowo

Oríṣun àwòrán, @BATofficial
Oloogbe MKO Abiola ni ko ba tun tẹle ki ijoba ologun to gba ibo rẹ danu.
Aarẹ buhari ti buwọlu orukọ rere gẹgẹ bi ara awọn adari orilẹede Naijiria, ọmọ ẹgba, iyẹn Abẹokuta loun naa

Oríṣun àwòrán, Yemi osinbajo/twitter
Oloye Earnest Shonekan jẹ olori ijọba fidihẹ lọdun 1993, ọmọ ipinlẹ Ogun ni oun naa.
Bakan naa igbakeji aarẹ to wa nipo bayii, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo naa pẹlu, ọmọ ilu Ikẹnẹ ni nipinlẹ Ogun.
Tinubu yoo yi itan yii pada gẹgẹ bí ọmọ Eko.
Ṣe iyalọja Eko ni tabi ọmọbinrin akọkọ ni Sade Tinubu Ojo yoo di mu?
Fọlashade Tinubu-Ojo, ọmọ aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Naijiria, Bọla Tinubu ni iyalọja Eko.
Oun lo jẹ oye yii lẹyin ti iya gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa pa ipo da.
Nisinyi ti baba rẹ ti n gbaradi lati gun aga aarẹ ni Naijiria, oun ni yoo di apele orukọ ‘first daughter’ mu bayii gẹgẹ bi ọmọbinrin akọkọ.
Ibeere ti ọpọ wa n beere bayii ni pe se oun naa yoo ṣidi lọ si ilu Abuja, ti yoo si lọ di iyalọja ni Wuse tabi ọja Eko ni iya yoo lẹdi mọ.
Ọrọ Emefiele ati ayipada owo naira
Lara awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ to mu ilu kangogo ṣaaju idibo ni ọrọ ayipada owo ti gomina banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele gbe sori.
Ọpọ eeyan lo tako ilana naa, paapaa julọ awọn eekan oloṣelu lẹgbẹ oṣelu APC.
Ọpọ awọn gomina naa lo fẹsun kan Emefiele pe o mọọmọ mu ayipada ba Naira ni, ki araalu ba lee korira ẹgbẹ oṣelu APC nitoripe ipo oludije aarẹ ẹgbẹ naa ko bọ síi lọwọ.

Oríṣun àwòrán, CBN
Nisisiyi ti Tinubu wọle sipo aarẹ, ṣe yoo fi aye gba Emefiele ko pari saa rẹ ni tabi yoo gbọn ọn yọ bo ba wolẹ?
Ẹwẹ, ọpọ awọn gomina wọnyi lo ti fi ọkan awọn eeyan wọn balẹ pe ki wọn maa na owo atijọ wọn lọ.
Wọn ni Tinubu yoo yi ofin naa pada, ni kete to ba bọ si ori oye.
Igba ati akoko ni yoo le e sọ boya eyi yoo wa si imusẹ ti Tinuba ba gori aleefa.
Ṣe Tinubu yoo yọ Subsidy, owo iranwọ lori eroja epo rọbi?
Owo iranwọ ti ijọba fi n di alaafo iye ti araalu n ra epo ati iye to yẹ ki wọn maa raa ni wọn n pe ni susbsidy.
Amoṣa, awọn iwadi ati iroyin to n jade bayii n sọ pe n ṣe lawọn kan n fi eto naa ṣe jẹunjẹun ati pe ẹgbẹlẹgbẹ owo to yẹ fun idagbasoke orileede Naijiria lo ti ba ipese owo iranwọ yii lọ.
Amọ Tinubu ti sọ yanya lasiko ipolongo ibo rẹ pe lilọ nii kẹyin bọi, loun yoo fi subsidy ṣe.

Oríṣun àwòrán, @BATofficial
Ṣe yoo le ṣe eyi ni ibeere opo nitori ọpọlọpọ awọn oloṣelu ni wọn ni o n jẹun labẹ eyi.
Awọn ọmọ Naijiria yoo maa reti ipa rere ti aarẹ kẹrindinlogun lorilẹede Naijiria yoo ni ninu igbesi aye wọn ati idagbasoke orileede yii nigba ti wọn ba seto ibura fun Bola Tinubu lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un.
Obidients àti àwọn yòókù, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín – Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram
Aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Ahmed Tinubu ni oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu kọọkan ati awọn ọludije fun ipa ti wọn ko ninu eto idibo to waye lọjọ Satide.
Tinubu sọ eleyi nigba to n tẹwọ gba esi idibo ti ajọ INEC kede lowurọ Ọjọru.
Tinubu, ẹni to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lo jawe olubori ninu eto idibo aarẹ lẹyin to fidi oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ati oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar janlẹ.
“Boya o jẹ Batified, Atikulated, Obidients tabi Kwankwasiyya, gbogbo yin ni mo ki pe ẹ dibo fun ilọsiwaju ati igbaye gbadun orilẹede Naijiria
“Mo ki yin pe ẹ ni igbagbọ ninu ijọba awarawa ati ọjọla rere fun orilẹede wa.
Èmi ló kàn lóòtọ́ọ́, mo gbà èsì ìbò ààrẹ - Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram
Aarẹ tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn dibo yan gẹgẹ bi aarẹ tuntun, to si fi wọn lọkan balẹ pe ijọba rẹ yoo mu ayipada ọtun de ba ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
Tinubu ni lootitọ ‘Oun lo kan’ lati di aarẹ orilẹede Naijria ti wọn ko si ja gbogbo ọmọ Naijiria kulẹ, ti oun yoo si ripe oun sisẹ pọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria lati gbe Naijiria lọ si ilẹ ileri.
Nigba ti o dupẹ lọwọ awọn eeyan niluu Abuja, Tinubu ni idinu ijọba awarawa ni aṣeyọri oun, to si rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu yooku lati gba ruku ti gẹgẹ bii aarẹ nitori ohun kana ni wọn ja fun.
“Eyi akẹgbẹ mi ti a jọ dupo papọ, mo bẹ yin, mo rọ yin, ẹ ja jọ sisẹ pọ lati ṣe ara lọkan lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, others
“Ilu ti yan mi lati lewaju orilẹede yii, ẹ ja ka fọwọsowọpọ lati mu ohun tu de ba orilẹede Naijiria.
“Mo ṣe ileri lati sisẹ pọ pẹlu yin lati mu ki awọn eeyan wa loke okun wa ile lati wa mu ilọsiwaju orilẹede Naijiria.”
“Mo mọ ibi ti bata ti n dun yin, maa si pese ọna abayọ fun yin”
Bakan na ni Tinubu ni gbogbo ohun awọn ọdọ ni oun gbọdọ, ti oun si ṣe ileri pe gbogbo ibi bata ti n dun wọn lẹsẹ ni yoo pese ọna abayọ fun.
O ṣe ileri lati sisẹ pọ pẹlu awọn ọdọ lati mu ayipada ba orilẹede Niajiria
“Eyi ọdọ, a jọ ma ri rinajo yii papọ ni, a jọ sisẹ papọ ni, mo tẹti si ọrọ ẹkọ yii, mo pese owo iranwọ fun awọn akẹkọ, ko ni si iyansẹlodi mọ lorilẹede Niajiria mọ.
“Mo mọ ibi ti bata ti n dun yin ma si pese ọna abayọ fun yin.
”Bo ya o jẹ BATified, ATIKUlated, OBIdient ati awọn miiran, mo dupẹ lọwọ yin pupọ pe ẹ ni igbagbọ ninu ijọba awarawa orilẹede Naijiria.”
Bakan naa ni kan sara si Aarẹ Muhammadu Buhari, Iyawo aarẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fun atilẹyin wọn fun aṣeyọri rẹ gẹgẹ bi aarẹ tuntun fun orilẹede Naijiria.















