''Èsì ìdíbò kíkà ọdún 2023 yóò tẹ̀síwájú, kìí ṣe tí 1999 tí ẹ dàrú '' - APC

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu APC ti kesi awọn araalu pe mimi kan ko lee mi esi idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ati Labour party ṣe kesi ajọ INEC lati dawọ kika esi idibo duro, ki alaga ajọ INEC naa si fi ipo rẹ silẹ.

Bakan naa ni wọn pe fun idibo miran ti yoo muna doko kaakiri orilẹede Naijiria.

Amọ, ẹgbẹ oṣelu APC ninu esi wọn ni ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour Party n gbiyanju lati doju idibo tiwantiwa bolẹ lorilẹede Naijiria, ni wọn si sọ pe ko ṣeeṣe.

Olubadamọran pataki lori eto iroyin, Dele Aleke lo kesi awọn araalu lati maṣe kọbi ara si ẹgbẹ oṣelu alatako naa.

Aleke ni awọn ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour Party fi kan INEC ko muna doko, ti ko si lẹṣẹ nlẹ.

''Idibo ọdun 2023 kii ṣe ti ọdun 1999 ti ẹ daru, eleyii ko ni sẹeṣe, a gbọdọ pari ohun ti a bẹrẹ.''

''Eto idibo tiwantiwa ni eto, o ni iberẹ , o si ni opin. ko si ẹnikẹni to gbọdọ daaru.''

''Ko tọ si Obasanjo lati da esi idibo duro''

Ninu ọrọ rẹ, aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC naa ni aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣegun Obasanjo ko ni aṣẹ lati kesi INEC pe ki wọn da esi idibo kika duro.

Wọn ni ko ni aṣẹ naa nitori pe o fi si apa kan.

''Ọṣu Kini, ọdun yii ni Obasanjọ kede pe ki awọn eniyan dibo fun oludije lẹgbẹ oṣelu Labour party, Peter Obi.''

''Eyi fihan inu rẹ ko dun si esi idibo to n jade nitori naa lo sẹ pe fun ki wọn da esi idibo naa duro.''

Láì fi ẹ̀rọ̀ BVAS kéde èsì ìbò ààrẹ, èsì ìbò kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà - PDP, LP

Obi ati Atiku

Awọn ọmọ ẹgbẹ alatako kan ti binu jade kuro ninu gbọngan ti ajọ eleto idibo, INEC, ti n kede esi ibo Aarẹ Naijiria lọjọ Aje.

Ẹgbẹ alatako meji pataki ni Naijiria, PDP ati Labour Party, LP sọ pe inu awọn ko dun si esi ibo ti INEC n gbe jade lati ori ẹrọ ayarabiaṣa BVAS.

Igba akọkọ ree ti INEC yoo lo ẹrọ ọhun fun eto idibo gbogbo-gbo lorilẹede Naijiria.

Amọ INEC ti sọ pe ofuutu-fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kanu lasan ni ẹsun ti awọn ẹgbẹ oṣelu naa fi kan oun.

Lẹyin naa ni alaga ajọ ọhun, Mahmood Yakubu, sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa kede esi ibo awọn ipinlẹ to ku.

A fẹ ki INEC kede pe ibo aarẹ pe ko pari, ko si kede ọjọ ti ibo tuntun yoo waye - PDP

Atẹjade kan ti ẹgbẹ oselu PDP fi sita ti wa koro oju si ikede esi ibo aarẹ to n lọ lọwọ naa, ti wọn si ni awọn n fẹ ki wọn kede ibo aarẹ naa bii eyi ti ko pari.

Atẹjade naa ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Ọmọwe Daniel Bwala fọwọsi ni o pọn dandan ki INEC dawọ ikede esi ibo naa duro.

O ni eyi ni yoo fun INEC lanfaani lati lee bori ariwisi tawọn ẹgbẹ oselu n se nipa asilo ẹrọ BVAS ati bo se kuna lati fi esi ibo aarẹ soju opo ayelujara rẹ.

PDP ni ohun to yẹ ki INEC se ni pe ko kede ọjọ ti eto idibo mii yoo waye, ko si ri daju pe oun fi awọn esi ibo naa sori ayelujara.

Ẹ dawọ ikede esi ibo aaẹ duro, kẹsi wọgile ibo aarẹ ta di kọja - Labour Party

Aṣoju ẹgbẹ PDP nibi ti wọn ti n kede esi ibo naa, tun fẹsun kan INEC pe o n lẹdi apo pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC.

Nigba ti aṣoju Labour ni ki wọn dawọ ikede naa duro, ki wọn si wọgi le idibo ọhun lati tun di.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu APC, ti oludije rẹ, Bola Tinubu ṣi n lewaju bayii ti sọ pe ẹni ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun, le gba ile ẹjọ lọ.

Lati igba ti awọn Ologun ti gbe ijọba kalẹ lọdun 1999, ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo n leke tente eto oṣelu Naijiria.

Amọ lakoko yii, Peter Obi, lati inu ẹgbẹ oṣelu Labour ti ko fi bẹẹ gbajumọ tẹlẹ ri ti n gbena woju ẹkun APC ati PDP.

Eyii ko ṣẹyin bi ọpọ awọn ọdọ, ti wọn jẹ ida meji ninu mẹta awọn to forukọ silẹ lati dibo, ṣe wa lẹyin rẹ digbi.

Yatọ si awọn mẹta yii, ẹgbẹ oṣelu marundinlogun mii lo n dije du ipo Aarẹ Naijiria.

Ki ni amuyẹ lati jawe olubori ibo Aarẹ?

Ki ẹgbẹ oṣelu kankan to le jawe olubori ninu ibo Aarẹ ni Naijiria, oludije rẹ gbọdọ ni iye ibo to pọju ati ida 25% ibo ti wọn ba di ipinlẹ marundinlọgbọn ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja.

Bi bẹẹ kọ, atundi ibo yoo waye laarin ọjọ mọkanlelogun, amọ ko ṣẹlẹ ri ni Naijiria.

Obi gbo ewuro soju Tinubu nipinle Eko

Wayi o, Obi ti ti da rugudu silẹ laarin agbo APC lẹyin to jawe olubori ninu ibo Aarẹ naa nipinlẹ Eko, eyii ti ọpọ gbagbọ pe o jẹ ti Tinubu.

Tinubu, to ti fi akoko igba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko ri, ni igbagbọ wa pe yoo jawe olubori ni ipinlẹ naa latari awọn ohun to ti gbeṣe nibẹ, atawọn eeyan to ti ara rẹ dide.

Wayi o, ẹgbẹ oṣelu APC ti gba ijakulẹ nipinlẹ Eko bayii, ti Tinubu funra rẹ si sọ pe oun yoo gba abajade esi idibo gbogbog naa wọle gẹgẹ bii ọmọluabi.

Yatọ si ipinlẹ Eko, Obi tun fidi Tinubu janlẹ ni ipinlẹ rẹ, Enugu, atawọn ipinlẹ mii.

Ki lo ti Ṣẹlẹ sẹyin?

Ó yẹ kí agbófinró gbé Melaye, Momodu àti Enenche lóri ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n ń sọ – Ikọ ipolongo Tinubu

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Collage

Ikọ ipolongo Bola Tinubu ati Kashim Shettima, PCC, ti ke si awọn agbofinro lati fi ṣikun ofin mu agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Dele Momodu ati Dino Melaye.

Ikọ ipolongo naa tun ni ki wọn fi panpẹ ofin mu pasitọ ijọ Dunamis, Paul Enenche, lori eṣun pe o sọrọ to le da rogbodiyan silẹ laarin ilu.

Wọn ni o tun yẹ ki awọn agbofinro maa fi imu finlẹ lọna ati le da sẹria fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ to ba n gbimọ pọ lati da wahala silẹ lẹyin idibo Aarẹ.

Olubadamọran fun ikọ ipolongo Tinubu ati Shettima, Dele Alake sọ pe eto idibo naa lọ bo ṣe yẹ lai si magomago kankan gẹgẹ bii ohun ti awọn to bojuto idibo naa lati ilẹ okere sọ.

Agbẹnusọ ọhun sọ pe awọn esi ibo to n jade tako awọn iroyin ẹlẹjẹ ti ẹgbẹ alatako n gbe kiri nitori awọn esi naa ko lọ bi wọ n ṣe lero.

Alake ni “Ọrọ naa ti da omi tutu si wọn lọkan to bẹẹ ti awọn adari wọn n sọrọ kobakungbe.”

“A mọ̀ nipa awọn agbenusọ awọn ẹgbẹ kan to n kọrin ogun nitori wọn mọ pe wọn maa lulẹ, paapaa ẹgbẹ oṣelu PDP.”

"Ọrọ Dino, Momodu ati Enenche lodi si ofin"

Atẹjade naa tẹsiwaju pe “Idi ree ti a fi n ke si ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko tete pa awọn eeyan bii Dino Melaye, Dele Momodu ati pasitọ Paul Enenche ti ijọ Dunamis Church lẹnu mọ.”

“Ọrọ jagidijagan ti Dino Melaye sọ lori Twitter, Momodu to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan nipa ẹni ti yoo jawe olubori ati ọrọ odi Paul Enenche lori pẹpẹ iwaasu jẹ eyii to lodi si ofin.”

“Ko si yẹ ki eyikeyi ninu gbogbo wọn lọ lai foju wina ofin.”

“Wọn ti mọ pe wọn maa lule, kaka ki wọn gba kamu gẹgẹ bii ọmọluabi wọn n wa ọna eburu.”

Alake pari ọrọ rẹ pe pupọ ninu esi ibo to n jade lati akata ẹgbẹ oṣelu Labour lo jẹ eyii ti kii ṣe ojulowo.

Lẹyin naa lo ni ki awọn agbofinro maṣe kawọgbera lori ọrọ naa.