Adájọ́ ṣubú, ó kú nínú ọọ́físì lásìkò tó ń múra láti gbọ́ ẹjọ́

 Justice Lokulo-Sodipe

Oríṣun àwòrán, BARRISTER NG

Adajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun kan niluu Akure, Lokulo-Sodipe, ti jade laye.

Iroyin ni inu ọọfi rẹ lo ti dede ṣubu lulẹ, to si ku lasiko to n mura lati lọ gbọ ẹjọ ninu yara ile ẹjọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, gbogbo akitiyan lati doola adajọ ọhun lo ja si pabo latari bo ṣe dake ki wọn to gbe digbadigba de ile iwosan.

Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro ana niluu Akure, Rotimi Olorunfemi, lo fidi iroyin naa mulẹ lori ikanni WhatsApp.

O ni “Ootọ ni o, o ṣubu ninu ọọfisi rẹ to wa nile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure laarọ oni, o si ti dakẹ ki wọn to gbe de ile iwosan.”

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade kan, alaga ajọ NBA ilu Akure, Banji Ayenakin sọ pe iku adajọ ọhun ba awọn lojiji.

Atẹjade naa ni “Iroyin iku adajọ Lokulo-Sodipe de bami lojiji.”

“Oluwa mi jẹ adajọ to ṣe e mu yangan, ọlọpọlọ pipe ati olorukọ rere si ni pẹlu.”

“Mo ba gbogbo mọlẹbi rẹ ati Aarẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun Naijiria kẹdun.”

“Gbogbo ọmọ ẹgbẹ agbẹjọ, NBA, Akure lo n ṣedaro rẹ ati ojuṣe rẹ ninu idagbasoke ati igbeleke idajọ ododo ni Naijiria.”

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ni adajọ naa ki ọlọjọ to de.