'Ẹ̀gàn mi tí d'ògo'; Wo ìdí tí Seyi Edun fi bú sẹ́kún bó ṣe rántí ẹni to fí ọ̀rọ̀ ọmọ bù u

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/i_am_shai/
Gbajugbaja osere tiata ati Iya ibeji tuntun, Seyi Edun ti ṣe iranti obinrin kan to ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii Tiwatope Abiodun fun bi oṣe fi ṣe yẹyẹ pe ko ri ọmọ bi lẹyin ọdun meje to ti wa ni ile ọkọ.
Osere naa lo ṣe ayẹyẹ ikomọ ibeji to ṣẹṣẹ bi pẹlu ọkọ rẹ Adeniyi Johnson ati awọn mọlẹbi diẹ.
Ikomọ naa ni wọn ṣe lai pe ero pupọ rara kọja awọn ojulumọ wọn.
Nigba to n ṣafihan ọrọ ti obinrin kan fi sori opo ayelujare Instagram rẹ ati ọrọ ti wọn jọ sọ ninu Oṣu kẹwaa ọdun kọja, O ni ẹgan oun ti d'ogo.
"Ọlọrun lo n se isẹ iyanu rẹ ninu aye mi.
"Baba ati Iya ibeji n ki yin pe ẹ se o ."

Oríṣun àwòrán, .Instagram.com/i_am_shai/

Oríṣun àwòrán, .Instagram.com/i_am_shai/

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/i_am_shai/
Laimọ pe Seyi Edun ti loyun lasiko naa, Arabinrin Tiwatope ni ki Seyi Edun sunkun si Ọlọrun lọrun ko fun un lọmọ nitori ọdun 2022 ti pari.
Seyi Edun ni oun ko mọ obinrin naa ri ti o si fi ohun to du oun pupọ fi bu oun lọdun to kọja.
O wa tọrọ aforiji pe Ọlọrun fori ji i fun bi o ṣe fi ọmọ bu oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Lẹ́yìn ìdádúró ọdún méje, Seyi Edun àti Adeniyi Johnson bí ìbejì

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/adeniyijohnson/
Ikini ku orire ati iro ayo lo ti bẹrẹ nile osere tiata, Adeniyi Johnson ati Iyawo re, Seyi Edun lẹyin ti ti wọn kede pe awọn bi ibeji.
Pẹlu idunu ati ayo ni Baba ọmọ fifi ọrọ sori ayelujara, to si ni oun ati iyawo oun duro fun odidi ọdun meje, ki Ọlọrun to gba adura wọn, fi ibeji ta wọn lọrẹ.
Adeniyi ni oun ko ni anfani lati ṣe ọjọbi rẹ nitori bi ayọ rẹ sẹkun ati pe oun awọn ọmọ ni ẹbun to dara ju fun ọjọbi rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
“Halleluyah, Baba ibeji tuntun.
“Wmi ati iyawo mi duro fun ọdun meje, Ọlọrun ni Ọlọrun yoo majé. O seto ẹbun ọjọbi fun mi.
“Ọrẹ, mọlẹbi ati awọn ololufẹ mi, inu mi dun lati sọ fun yin pe mo ti di baba ibeji, iya ati awọn ọmọ wa ni alaafia. Mo dipẹ.”
Ọpọlọpọ awọn oṣere tiata lo ti ransẹ ikini ku orire si Adeniyi Johnson lori ayelujara .















