'Kò yẹ kí Atiku àti PDP máa ṣe bí ọmọ kékeré tí wọ́n gba sùútí lọ́wọ́ rẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti bu ẹnu atẹ lu bi oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Atiku Abubakar, ṣe lewaju iwọde to waye lana ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun 2023.
Atiku ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo gbe iwọde naa kalẹ lati fi tako esi ibo to gbe aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu jade, ti ẹgbẹ oṣelu APC wọle ni ọfisi INEC niluu Abuja.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu APC fi lede, wọn gba Atiku ni amọran lati lọ wa awọn agbẹjọro to dantọ lati baa gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ ati pe eyi ṣe anfani ju ki oun ati awọn ọmọ lẹyin PDP maa jo kiri loju titi lori pe wọn ṣe iwọde.
Bayo Onanuga, agbẹnusọ fun ipolongo ibo aarẹ ni APC, ṣalaye pe ni ọsẹ to kọja nigba ti Atiku ṣe ipade pọ pẹlu awọn akọroyin, o ni oun setan lati gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ sugbọn ohun iyalẹnu lo jẹ pe o kuna lati tẹle ọrọ rẹ, to si pinnu lati se iwọde ti ko ni ẹsẹ nilẹ rara.
Atiku, bọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí àti ipò ìgbàkejì Ààrẹ tóo dì mú tẹlẹ, gba iléẹjọ́ lọ - APC
O ni ọrọ naa dabi pe Igbakeji aarẹ tẹlẹ ko ni isẹ lati lo lo fi ni akoko lati máa da ilu laamu pẹlu ariwo lori ọrọ to ni oun setan lati gbe lọ ileẹjọ.
Onanuga fikun pe pẹlu gbogbo iriri Atiku Abubakar ninu oṣelu, O ya ẹgbẹ oṣelu APC lẹnu pe o lewaju awọn ọmọ lẹyin PDP lati se iwọde, eyi to pe iwọde alawada lọ si ọfiisi INEC niluu Abuja.
O ni iwa ọde alawada ko le fun yin ni aṣẹyọri Bola Tinubu pada gẹgẹ bii aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan.
Onanuga tẹsiwaju pe yatọ si pe ẹgbẹ oṣelu PDP n fi akoko sofo, o gba wọn ni amọran lati lo akoko wọn lati fi wa agbẹjọro ati awọn ẹri ti yoo wulo fun wọn ni ileẹjọ.
"Wọn wa jo ijo Skelewu ki ri loju titi pẹlu ariwo ati iwọde ti ko ni ẹsẹ nilẹ rara.
"Bawo ni iwọde ti ko ni ero lẹyin ṣe fẹ mu wọn bori, o ya mi lẹnu.
"Ọna abayo kan soso to wa fun Atiku ni ko morile ileẹjọ, ko ṣe pe ko ma jo kiri loju titi pẹlu ọjọ ori rẹ ninu oṣelu.".















