Mọ̀ síi nípa mẹ́ta nínú àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo

Seyi Makinde, Teslim Folarin ati Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Collage

Ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kọkanla oṣù Kẹta ni eto idibo sipo gomina yóò waye kaakiri awọn ipinlẹ ni orilẹ ede Naijiria.

Ni ipinlẹ Oyo oniruuru awọn oludije lo jade lati ẹgbẹ oṣelu lọkan-o-jokan lati gba ipo naa lọwọ gomina to wa nipo lọwọ, Onimọẹrọ Seyi Makinde.

Seyi Makinde naa funra rẹ n gbero lati tun pada sipo naa gẹgẹ bo ṣe jẹ oludije labẹ to kọkọ gbe wọle.

BBC News Yoruba wa ṣe agbeyẹwo awọn oludije mẹta ninu awọn to n wa ipo naa laifi ti ẹgbẹ oṣelu tabi ojuṣaaju kankan ṣe.

Onimọẹrọ Oluwaseyi Makinde

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook

A bi Makinde ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kejila ọdun 1967 sinu idile Pa Olatubosun Makinde ati Madam Abigail Makinde ti agboole Aigbofa ni Oja’ba, Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ 'Michael’s Primary School,' Yemetu nilu Ibadan ati 'Bishop Phillips Academy,' Iwo Road Ibadan.

Ṣeyi Makinde lọ ile ẹkọ giga Fasiti ipinlẹ Eko ni Akoka Yaba, nibi ti o ti kẹkọọ gboye imọ nipa ẹrọ ina mọnamọna, 'Electrical Engineering' lọdun 1990.

Bakan naa lo kẹkọọ gboye imọ nipa amojuto awọn ileeṣẹ nla, 'Industrial Control Services' ni Houston, Texas lorilẹede Amẹrika lọdun 1998, ati imọ nipa idagbasoke esi iṣiro, 'Development of Analytical Competence' ni ile ẹkọ fun idokowo n'pinlẹ Eko (ti o ti di Fasiti apapọ ilẹ Adulawọ bayii) lọdun 1999.

O kẹkọọ nipa ayẹwo epo rọbi ile ẹkọ 'Jiskoot Auto Control Training Centre', Kent lorilẹede England lọdun 2002, ati imọ nipa bi a ṣe n yanju awọn iṣoro idokowo ni ile ẹkọ giga 'Massachusetts Institute of Technology,' lorilẹede Amẹrika lọdun 2005.

Makinde ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ epo rọbi 'Shell Petroleum Development Company' fun ọdun meji lati 1990 si 1992 gẹgẹ bii Onimọẹrọ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin eyii lo ṣiṣẹ fun ileeṣẹ 'Rebold International Limited' gẹgẹ bii Onimọẹrọ ati igbakeji alamojuto laarin ọdun 1992 si 1997.

Lọdun 1997 ni Makinde bẹrẹ iṣẹ aladani tiẹ gangan ti o pe orukọ rẹ ni, 'Makon Engineering and Technical Services Limited (METS)'lẹyin ti o ti ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọkanojọkan ileeṣẹ epo rọbi fun ọdun marun un gbako.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti iṣẹ adani rẹ bẹrẹ ni Makinde darapọ mọ ọrọ oṣelu.

Oriṣiriṣi ẹgbẹ oṣelu lo darapọ mọ ki o to di pe o di ọmọ oye fun ẹgbẹ oṣelu 'People’s Democratic Party (PDP)' lọjọ kọkandinlọgbọn oṣe kẹsan an ọdun 2018, ti o si jawe olubori ninu eto idibo si ipo Gomina ti o waye lọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019, pẹlu onka ibo 515, 621.

Orukọ aya Ṣeyi Makinde ni Tamunominini Makinde. Igbeyawo si ti ṣatiwaye awọn ọmọ mẹta ọtọọtọ ti orukọ wọn n jẹ, Feyi, Tayọ ati Tobi.

Lọwọlọwọ bayii, Makinde n dije fun saa ikeji gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ, ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun yii.

Teslim Fọlarin

Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, Facebook

A bi Fọlarin ni ọjọ kini oṣu kẹẹwa ọdun 1963 ni ilu Zaria, ipinlẹ Kaduna.

Fọlarin jẹ ọmọ Alhaji ati Alhaja Hamzat Fọlarin ti wọn jade lati ile Baalẹ ni agbege Ọja Igbo to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ila Oorun-Ariwa n'ipinlẹ Ọyọ.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan nilu Eko ki o to darapọ mọ ile ẹkọ Girama 'Methodist Boys High School'.

Fọlarin kẹkọọ gboye imọ nipa eto oṣelu ni Fasiti ilẹ Ibadan ati imọ ẹkọ mii ni ile ẹkọ giga 'Harvard University’ lorilẹede Amẹrika.

O lo ọdun diẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba nilu London ki o to di pe o pada wa si Naijiria lọdun 2002.

Fọlarin ṣe agunbanirọ n'ipinlẹ Kaduna ki o to di pe o darapọ mọ oṣelu.

Lẹni ọdun mọkandinlogoji, Fọlarin dije o si wọle ninu ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii Sẹnetọ to ṣoju aringbungbun Ọyọ lọdun 2003.

Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, Facebook

O wọle pada fun saa ikeji gẹgẹ bii Sẹnetọ lọdun 2007.

Lọdun 2014, Fọlarin jawe olubori gẹgẹ bii ọmọ oye ti yoo du ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn Abiọla Ajimọbi to n ṣe Gomina lọwọ nigba naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lo fi ẹyin rẹ janlẹ lati wọle fun saa ikeji.

Ninu ọṣu kejila ọdun 2017, Fọlarin darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu 'All Progressive Congress, APC’.

Ninu oṣu kẹsan an ọdun 2018, Fọlarin di ọmọ oye ti yoo dije fun ipo Sẹnetọ ti yoo ṣoju APC ni Aringbungbun Ọyọ.

Fọlarin lo jawe olubori lẹyin ibo gẹgẹ bi o ṣe fi ẹyin Sẹnetọ ti o wa ni ipo naa tẹlẹri, Arabinrin Monsurat Sunmonu janlẹ.

Fọlarin ati aya rẹ, Amofin Angela Folarin bi ọmọ meji, ki o to di pe aya rẹ di oloogbe ninu oṣu kini ọdun 2022.

Lọwọlọwọ bayi, oun lo n dije fun ipo Gomina Ọyọ labẹ asia APC ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun yii.

Adebayo Adelabu "Pẹnkẹlẹmẹsi"

Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Facebook

A bi Adelabu lọjọ kejidinọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 1970 sinu idile Aderibigbe Adelabu lati agboole Oke-Oluokun ni agbegbe Kudeti ilu Ibadan. Baba Baba rẹ ni Adegoke Adelabu ti ọpọ eeyan mọ si "Pẹnkẹlẹmẹsi".

Adebayọ lo si ile ẹkọ alakọbẹrẹ 'Ibadan Municipal Government Primary School' laarin ọdun 1976 si 1982, ati ile ẹkọ Girama 'Lagelu Grammar School' Ibadan, laari ọdun 1982 si 1987.

Lẹyin ti o pari ile ẹkọ Girama, Adelabu kẹkọọ gba oye ẹni ti o tayọ julọ ninu imọ ẹkọ iṣiro karakata ni fasiti Obafemi Awolowo Ile-Ifẹ.

Adelabu kekọọ gba iwe ẹri akọṣẹmọṣẹ lati ọdọ ajọ to n ṣe akoso awọn onimọ iṣiro idokowo, 'Institute of Chartered Accountants of Nigeria (ICAN)' ki o to rin irinajo lọ gba awọn ọkanojọkan iwe ẹri imọ ẹkọ ni awọn ile ẹkọ bii, Harvard, Stanford, Wharton, Columbia, Kelloggs, Euromoney, ati 'University of London'.

Adelabu ṣe iṣẹ gẹgẹ bii onimọ iṣiro karakata pẹlu ileeṣẹ 'PriceWaterhouse (ti o ti di PricewaterhouseCoopers nisin). Laarin ọdun meje ti o lo nibẹ, o le iwaju, o si ṣe akoso ayẹwo eto ẹnawo fun awọn ile ifowopamọ nla nla ati awọn ileeṣẹ mii lorilẹede Naijiria ati ni oke okun.

Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Facebook

O kuro ni ileeṣẹ naa lọdun 2000 lati darapọ mọ ile ifowopamọ First Bank gẹgẹ bii alakoso ayẹwo eto ẹnawo ati olutọna agba ki o to di pe o ni igbega lẹnu iṣẹ naa laarin ọdun 2002 si 2003.

Lẹyin ti Adelabu kuro ni First Bank lo daapọ mọ 'Standard Chartered Bank' ti wọn ni ẹka ni orilẹede Ghana ati Naijiria.

O ṣiṣẹ pẹlu wọn titi di ọdun 2009 ki o to pada lọ jẹ ọkan lara awọn ọga agba ile ifowopamọ First Bank lẹni ọdun mọkandinlogoji.

Adebayọ Adelabu gba iwe iyansipo lati ọwọ aarẹ orilẹede yii tẹlẹri, Goodluck Ebele Jonathan ninu ọṣu keji ọdun 2014, gẹgẹ bii igbakeji Gomina Banki apapọ orilẹede Naijiria.

Lẹyin ọdun diẹ ti o ṣiṣẹ nile ifowopamọ apapọ orilẹede Naijiria ni o kọwe fi ipo silẹ lati dije du ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, lọdun 2019, ṣugbọn Ṣeyi Makinde to n bẹ lori aleefa lọwọ bayii lo jawe olubori ti Adelabu si ṣe ipo keji.

Lọwọlọwọ bayii, Adebayo Adelabu ni oludije fun ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun yii.