Àìyọjú Makinde sí ìpolongo Atiku n‘Ibadan di ìjà, Makinde sòkò ọ̀rọ̀ padà sí Wole Oyelese, Atiku

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ Ẹrọ Seyi Makinde ti salaye lẹẹkansi idi to fi n tako erongba oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar lati dije.
Makinde, lasiko to n kopa lori ifọrọwerọ kan pẹlu ileesẹ tẹlifisan Channels lọjọ Ẹti, lo sisọ loju ọrọ yii lati fesi si bawọn eeyan kan se ni ko yọju si ipolongo Atiku to waye nilu Ibadan ni ọsẹ kan sẹyin.
Saaju ni Minisita tẹlẹ fun ohun amusagbara, to tun jẹ eekan kan ninu ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo, Elder Wole Oyelese ti koro oju si gomina Seyi Makinde pe ko yọju si ipolongo ibo Atiku ni Ibadan.
Oyelese ni bi Makinde fẹ, bo kọ, o yẹ ko mọ pe oun nilo Atiku, to jẹ oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu PDP tawọn mejeeji n soju, lati bori ibo gomina nipinlẹ Oyo fun saa keji.
“ Wole Oyelese ko le ri ipo Minisita gba tori ko se daadaa nigba to wa nipo naa tẹlẹ”
Amọ Makinde ni irọ to jinna sootọ ni Oyelese sọ nitori Atiku gan lo nilo oun lati ni ibo to pọ nipinlẹ Oyo.
“Bi oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu PDP ta dijọ wa, ba maa moke ninu esi ibo aarẹ, emi gomina ni maa se ipolongo ibo fun.
Oun lo nilo lati gun opo aseyọri gbogbo ti mo ti se nipinlẹ Oyo, fi ri ọpọ ibo ko nipinlẹ mi.
Bi o tilẹ jẹ pe n ko fẹ ri wọn fin, amọ ti Oyelese ba n wa ipo Minisita lọdọ Atiku, ko le ri gba nitori nigba to wa nipo minisita tẹlẹ, ko se daadaa rara.
Koda, ni agbegbe Erunmu ti Oyelese ti wa, awọn eeyan korira rẹ, ti wọn ko si fẹ sun mọ rara.”
Makinde ni awọn oloselu to ti ‘Expire’, eyiun tọjọ ti lọ lori wọn bii Oyelese wa, o wa rọ agba oselu naa lati maa sọ bi ọrọ ba se jẹ dipo ko maa mu omulomu.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
“Irẹpọ Naijiria lawọn gomina G5 n ja fun, aarẹ ko le maa wa lati ẹya kan, ki wahala ma sẹlẹ”
Wayio, Gomina Seyi Makinde ti wa salaye idi tawọn gomina marun ninu ẹgbẹ oselu PDP se n tako erongba Atiku, tii se oludije aarẹ to n soju ẹgbẹ oselu naa lati dije fun ipo aarẹ.
Makinde ni irẹpọ Naijiria lo mumu laya awọn, lawọn fi gbe igbesẹ naa nitori bi ẹkun kan soso ba n jẹ aarẹ ni Naijiria, wahala le bẹ silẹ.
“Yatọ si ifẹ tara wọn, ifẹ ati isọkan Naijiria lawọn gomina G5 n ja fun.
Nigba ti wọn panupọ pe ka maa pin ipo aarẹ laarin ẹkun Ariwa ati Guusu,wọn n fẹ ki ẹkun kọọkan lẹnu ninu ọrọ Naijiria ni.
Ko si ni dara to ki awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP maa bọwọ fun ofin to ba wu wọn, ki wn si maa tako eyi ti ko ba ifẹ ọkan wọn mu.”
Seyi Makinde wa koro oju si bi wọn se tu igbimọ alasẹ fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ekiti ka, to si woye igbesẹ naa tako awijare ti PDP n se.
“Mo kan saara sawọn gomina APC to duro sori otitọ pe ẹkun guusu Naijiria nipo aarẹ kan”
Gomina Seyi Makinde ti wa se sadankata sawọn gomina to wa ninu ẹgbẹ oselu APC fun bi wọn se duro sori otitọ pe ẹkun guusu Naijiria lo yẹ ko fa oludije sipo aarẹ silẹ ninu ẹgbẹ wọn.
“Mo kan saara sawọn gomina APC bii Nasir El-Rufai ti Kaduna, Mohammed Abubakar ti Jigawa, Mai Bala Buni ti Yobe ati gomina Yahaya Bello tipinlẹ Kogi.
Wọn panupọ laarin ẹgbẹ oselu wọn pe fun isọkan Naijiria, ẹjẹ ka fi eronga tiwa rubọ.
Ẹ jẹ ki oludije aarẹ wa lati Naijiria ẹkun guusu Naijiria, o si yẹ ka san sara si wọn.
Amọ ki lo n sẹlẹ ninu ẹgbẹ oselu tiwa, se la n ba ara wa ja, ta si fi ọwọ rọ iwe ofin ẹgbẹ oselu wa danu, n ko ro pe eyi tọna.”
N100m nìjọba mi ń dà sí ọrọ̀ ajé Igboho lóṣù - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina Ipinlẹ Oyo, onimoẹrọ Seyi Makinde ti kede pe o le ni ọgọrun milliọnu naira ti ijọba oun dá sori ọrọ aje Igboho labẹ ijọba ibilẹ orelope, lati igba ti ijọba rẹ ti bẹrẹ.
Makinde sọ ọrọ yii nigba to n ṣe ìpolongo ibo rẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nìlu Igboho to wa ni ijọba ibilẹ Oorelope.
Gomina Oyo wa ṣe apejuwe bi o ti san owo oṣu awọn oṣiṣẹ eleyii to mu ki awọn oniṣowo, oṣiṣẹ ijọba ati awọn oniṣẹ ọwọ rí owo naa ni gbogbo igba nilu naa.
Makinde, lasiko ipolongo ibo naa, tun ba awọn ori ade ati awọn olori ẹlẹsin nijọba ibilẹ Oorelope sọrọ nipa awọn ileri to se lọdun mẹrin sẹyin, ko to de ipo gomina, amọ to ti mu sẹ.
Makinde ni ifẹ ti oun ni si ilu igboho kò dikun, bẹẹ oun ko ni fi ẹtọ ilu naa dun bi o tilẹ jẹ pe igbakeji oun tẹlẹ ti wọn yọ nipo, Rauf Olaniyan, jẹ ọmọ ilu Igboho.
Seyi Makinde, nigba to n ba awọn ọdọ ilu Igboho sọrọ, wa ṣeleri lati ṣe ijọba ti yoo fi aaye gba gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
















