Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀ fáwọn ènìyàn Osun láti sagbéjẹ́ mọ́wọ́ bí Tribunal yóò ṣe gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́la

Gboyega Oyetola ati Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ wí pé kí wọ́n so agbéjẹ́ mọ́wọ́ bí ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò yóò ṣe gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní ọ̀la, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2023.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun ní gbogbo nǹkan tó yẹ láti ri dájú pé ààbò wà fún àwọn aráàlú ni àwọn ti ṣe lábẹ́ òfin tí àwọn kò sì ní fàyè gba kí ẹnikẹ́ni da omi àláfíà ìpínlẹ̀ náà rú rárá.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola fi síta lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ènìy[pan kò tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Opalola ní àwọn máa ri dájú pé ààbò tó péye wà ní ìpínlẹ̀ náà ṣáájú, lásìkò àti lẹ́yìn ìdájọ́ náà bá wáyé.

Ó fi kun pé àwọn wà ní sẹpẹ́ láti fi ìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tó bá gbèrò láti ṣe ohunkóhun tó lòdì sí ohun tí òfin là kalẹ̀ nítorí kí gbogbo àwọn ènìyàn so agbéjẹ́ mọ́wọ́.

Bákan náà ló pàrọwà sáwọn òbí àti alágbàtọ́ láti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọn láti máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lò wọ́n fún ìwà tí kò bá tọ́ tàbí ìwà ọ̀daràn.

Ọ̀la ni Oyetola àti Adeleke yóò mọ ibi tí orí ń bẹ́sẹ̀ rè ní Tribunal

Gboyega Oyetola ati Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

Ilé ẹjọ́ to n gbọ ẹhonu ìbò nípínlẹ̀ Osun ti yan ọjọ́ Jimọ́, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kinni láti ṣe ìdájọ́ awuyewuye ti o waye nínú ètò idibo gomina to waye ni ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu APC lo pe ijawe olubori Gómìnà Ademọla Adeleke níbi eto ìdìbò gómìnà ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje, ọdún 2022 lẹjọ.

Gomina ana, Alhaji Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lo gbé Sen. Ademola Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) lọ sí ile-ejo lati tako èsì idibo to wáyé ni ipinle Osun.

Àtẹ̀jáde tí ilé ẹjọ́ fi léde

Oríṣun àwòrán, OSUN TRIBUNAL

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Èyí jẹyọ ninu atejade kan ti ijokoo igbẹ́jọ́ naa to wáyé lọjọ kerinlelogun Oṣu Kiini, eyi ti AkọweIle-ẹjọ ọhun, Ọgbẹni David Mike fọwọ si, ti won sì gbé síta fun awọn akọroyin ni ìlú Osogbo.

Atejade naa fi ìdí rè múlẹ pe idajọ naa yoo waye ni aago mẹsan-an owurọ ni ọjọ Jimọ ni ilu Osogbo, ipinle Ọsun.

Alaga igbimọ ẹlẹni mẹta to n gbọ igbẹjọ naa, Adajọ Tertsea Kume, ti sọ ṣáájú ni ọjọ Kẹrinla Oṣu Kiini pe wọn o fi tó gbogbo awọn ti ọrọ kan ati ẹgbẹ oṣelu létí ọjọ ti ìdájọ yoo wáyé.

Eyi jẹyọ lẹyin ti Olupẹjọ ati awọn ti wọn pé lẹjọ ti wa farahan láti sọ tẹnu wọn ni ile-ẹjọ naa.

Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni ọjọ karun-un oṣu kẹjọ gbé ẹjọ lọ siwaju ile-ẹjọ to wa ni ilu Osogbo lati tako esi idibo lati awọn ẹka ibo 749 kaakiri ijọba ibilẹ mẹwaa 10, ti wọn n sọ pe awọn aṣiṣe ninu idibo ṣẹlẹ, ati didi ibo pupọ ju ohun tó wà nínú akọọlẹ.

Ajo eleto idibo (INEC) kede Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina pẹlu ibo 403, 271 ti ibo Gboyega si jẹ 375, 027.