Bolanle Raheem àti ọkọ rẹ̀ kò bá wa jiyàn, mo kan ṣàdédé gbọ́ ariwo ìbọn - Ọlọ́pàá Ẹlẹ́rìí

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Igbẹjọ lori iku obinrin agbẹjọro to padanu ẹmi rẹ lọjọ keresimesi ọdun to kọja, Bolanle Raheem tẹsiwaju ni ileẹjọ lọjọru, ọjọ kẹdogun, oṣu kinni ọdun 2023.

Ẹlẹri keji to jẹ akẹgbẹ afurasi olujẹjọ nidi isẹ ọlọpaa, Fiyegha Ebimine, farahan ni ileẹjọ lati salaye oun to mọ nipa isẹlẹ naa.

Ebimine jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa mẹta to wa loju opopona lasiko ti isẹlẹ naa waye.

Ninu alaye rẹ ni ileẹjọ giga nipinlẹ Eko, o ni lati ẹka ileeṣẹ Ajiwe ni oun.

O ni Drambi Vandi ati ọlọpaa miiran ti gbera lati bọ si opopona abẹ afara Ajah lati ṣe isẹ, eyi to jẹ mọ dida awọn ọkọ duro, ki wọn si yẹ wọn wo.

"Emi ati ekeji mi da ọkọ Bolanle Raheem duro amọ wọn ko duro"

Ẹlẹri keji naa salaye pe “Nigba ti mo ri ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Venza, mo da duro sugbọn wọn ko duro rara, o ya mi lẹnu nitori pe wọn ko sa ere asapadude rara.

“Wọn fa gilaasi ọkọ naa sile, mo ai gbọ ariwo ni kete ti wọn gba ẹgbẹ mi kọja.

“Obinrin kan joko si ẹgbẹ awakọ ni iwaju ọkọ naa, ti ọkunrin kan si n wa ọkọ naa.

Lẹyin ti emi da wọn duro, ti wọn ko da mi lohun, ẹni keji mi, Mattew Ameh naa da ọkọ naa duro, ti wọn ko si da lohun."

Ebimine ni kete ti wọn gba ẹgbẹ awọn kọja ni oun gbọ ariwo ibọn.

“Mo beere lọwọ ikeji mi, Ameh pe ki lo sẹlẹ? "

"A ri Vandi to sa pamọ sinu ọkọ Korope l.ẹyin ti ọta ibọn ba Bolanle Raheem"

Ẹlẹri keji naa sọ siwaju pe "Obinrin kan lati ninu ọkọ Toyota Venza ni mo ri to sare si ASP, to si pariwo pe o ti pa ẹgbọn rẹ.”

Ẹlẹri naa sọ fun ileẹjọ pe lẹyin ti awọn pejọ sibi isẹlẹ naa ni wọn sawari Vandi ninu ọkọ Korope to sapamọ si, ti wọn si gbe sinu ọkọ Toyota Venza

“Mo gbinyanju lati mọ ohun to sẹlẹ. Mo pe Vandi lori ẹrọ ibanisọrọ. Mo ni Ọga, ki lo sẹlẹ? O ni ki n fara balẹ.”

O tẹ siwaju pe oun pe Vandi ni igba keji sugbọn idahun kan naa lo sọ fun oun.

Àkọlé fídíò, Kehinde Sogunle: Èmi ni alága ìgbìmọ̀ tó ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà ìdàgbàsókè ọlọ́dún 25 fún Ogun

N ko ri ohun ibẹru kankan ninu ọkọ mọlẹbi naa

Ebimine, nigba to dahun ibeere agbẹjọro Onigbajo, o ni ọkọ Toyota Venza mọlẹbi naa ko dẹru ba oun tabi awọn eeyan ayika nitori pe wọn lọ ni ilọ alafia ni.

“Rara o, ọkọ ayọkẹlẹ Venza ko dẹru ba mi rara nigba to kọja ni ẹgbẹ mi. Wọn n lọ ni alaafia ni”

Agbẹjọro fun olujẹjọ, Adetokunbo Oduntola sọ fun ileẹjọ lati fun oun ni anfani lati lọ si ibi ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ.

O ni eyi yoo fun oun anfani lati ni oye si nipa isẹlẹ naa

O fikun pe awọn ko ti ri esi ayẹwo ibọn ati ọta ibọn ti wọn fi ẹsun rẹ kan onibara rẹ.

Adajọ Ibironke Harrison ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun 2023 lati gbọ ọrọ lẹun awọn Ẹlẹri yooku.