Òkò ba òǹlàjà lórí lásìkò tò ń la ìja, ikú dé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ilé ẹjọ́ májísíréètì kan ní ìlú Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo ti sọ arákùnrin kan, Funmilayo Asojo sẹ́wọ̀n fẹ́sùn wí pé ó pa ẹnìkan tó ń la òun àti ẹni tó ń bájà.

Asojo ń kojú ìgbẹ́jọ́ fẹ́sùn pé ó sọ̀kò pa Bamiduro Adewole nígbà tí Adewole ń làjà láàárín Asojo àti ọkùnrin kan tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin náírà.

Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún tó kọjá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ìlú Ute ní ìjọba ìbílẹ̀ Ose, ìpínlẹ̀ Ondo.

Olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni òǹlàjà to ku, wn fẹsun ipaniyan kan ẹni to sọko

Olóògbé Adewole tó ń ṣiṣẹ́ ọdẹ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan tó jẹ́ ti ìjọba ni Asojo ju òkò náà bà á ní orí, tó sì gba ibẹ̀ dé ilé ìwòsàn.

Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí Adewole wà ní ilé ìwòsàn ni ẹ̀mí bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Ẹ̀sùn ìpànìyàn ni Asojo ń kojú nílé ẹjọ́ báyìí.

Olùpẹjọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Augustine Omhenemhen sọ fún ilé ẹjọ́ pé ẹ̀sùn tí Asojo kojú lòdì sí ẹ̀ka 319 ÀTI 355 òfin ìwà ọ̀daràn ìpínlẹ̀ náà tọdún 2006.

Omhenemhen rọ ilé ẹjọ́ láti sọ Asojo sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n Olokuta títí àwọn yóò fi tẹ̀sìwájú nínú ìgbẹ́jọ́ náà.

Nígbà tó ń gbe ìdájọ́ kalẹ̀, Adájọ́ R. O. Yakubu ni kí wọ́n sọ Asojo sẹ́wọ̀n Olokuta fún ìgbà kan ná, tó sì sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹta ọdún 2023.

Àkọlé fídíò, Tititlayo Atiku: Ọkọ́ mi fẹ́ sẹ̀san rere fún Nàíjíríà, ló ṣe ń dìje ipò ààrẹ fún ìgbà kẹta