Ẹ má fọ́jú tẹ́ńbẹ́lú wo ìgbìmọ̀ ìpolongo Tinubu mọ́ - Alawuje

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ikọwefiposilẹ ti ọkan ninu ọmọ igbimọ ẹgbẹ ipolongo ti oludije ẹgbẹ All Progressives Congress APC, Bola Ahmed Tinubu fi aiṣedede ti awọn alakoso eto ipolongo ẹgbẹ APC funra rẹ han.

 Abdulhakeem Adegoke Alawuje, oludari igbimọ awọn ọmọlẹyin Jagaban,(Diciples for Independence Campaign Council, Comrade, DICC, )lo sọ ọrọ yii nigba to n fi ẹdun ọkan rẹ han si bi alakoso igbimọ ipolongo fun oludije ẹgbẹ APC, Naja’atu Muhammad lọjọ abamẹta ṣe fi ipo rẹ silẹ.

 Muhammad, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta sọ pe awọn iṣẹlẹ lagbo oṣelu ati iṣejọba tiwantiwa ko jẹ ki o ṣeeṣe fun oun lati tẹsiwaju ninu oṣelu ẹgbẹ APC.

Sugbon ẹgbẹ oṣelu APC so wi pe Naja'atu je ọdalẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbin sinu APC, o si tenumọ pe loooto ni wọn ti yọ ọ kuro nitori aiṣedeede re ati iwa ọdalẹ rẹ.

Oludari awọn ọmọ igbimo ọmọlẹyin ipolongo fun Jagaban, Abdulhakeem Adegoke Alawuje ninu atejade kan ti o fi sita fun awọn akọroyin ti ke si igbimọ ipolongo aarẹ APC lati maṣe doju ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

 Abdullhakeem fi ẹsun kan igbimọ ìpolongo aarẹ fun Tinubu ati Shetima pe wọn ko yan awọn olododo ati awọn ọmọ ẹgbẹ to ni ifọkansin lati ri wi pe Bola Tinubu gba ipo aarẹ Muhammadu Buhari nipa bibori ninu eto idibo aarẹ ọdun yii.

 Nigba to n gbadura pe ki Ọlọrun je ki Tinubu di aarẹ, Alawuje ni ipa ti awọn alatilẹyin Tinubu ti ko ti di olokiki pọju awọn to ti lokiki lọ.

O rọ ẹgbẹ ipolongo aarẹ APC lati maṣe f'oju aito wo awọn ẹgbẹ naa.

Oorun Tinubu ti pọjù, kò dá pé lára àti ní ọpọlọ - Adarí ìpolongo Tinubu tó fipò sílẹ̀
Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Adari fun ipolongo ibo tẹlẹ fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Najatu Muhammad ni o so kogba ko ọrọ lori ilera Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko.

Ọsẹ to kọja ni Najatu Muhammad kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi adari ipolongo ibo naa.

Nigba to n sọrọ lori idi to fi ja ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije sipo aarẹ, Bola Tinubu silẹ, Najatu ni bi nkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria ti ko tẹ oun lọrun lo sokunfa idi ti oun fi kuro lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC.

Najatu ni ilera Tinubu ko da to lati di aarẹ orilẹede Naijiria, nitori ọpọ akoko ni Tinubu ma fi n sun.

“Asiwaju ti mo joko ti fun wakati meji, to si fi pupọ ninu akoko naa sun, emi ati Bisi Akanbe ni a ṣe eyi to pọju ninu sisọrọ naa.

“Pataki ibẹ nipe, ilera Tinubu ko da to, ti a fẹ gbọ otitọ ọrọ. Ko ki n ṣe pe mo korira Tinubu, mo bu ọwọ ti rẹ fun nitori o ti ran awọn eeyan lọwọ, eyi to dara gan

“Sugbọn ti a ba sọrọ oloi fun ogunlọgọ eeyan, ti a ba ni pe ki a yọ ti ẹlẹyamẹya kuro, gbogbo wa lamọpe, Tinubu to kojuosuwọn rara, to si jẹ pe awọn ti yoo ṣe olori fun wa ni awọn to wa ni ayika rẹ.

“Ti a ba wiru, Tinubu yoo ma wiru. Mo ni igbagbọ pe Tinubu ni aisan lago ara rẹ, nitori ko le da mu kọpu dani”

“Gbogbo nnkan ti Tinubu sọ lo jẹ irọ”

Najatu tẹsiwaju pe pupọ ninu awọn Tinubu lo jẹ irọ nla. O ni ẹgbẹ oṣelu APC ko le fa Tinubu kalẹ to ba jẹ pe ilẹ Hausa lo ti wa.

“Ki a yọ ti ẹgan kuro, ki a yọ ti Eko ati Ibadan kuro, to ba jẹ pe Tinubu ko ki n ṣe Yoruba ni, ko ni le kopa ninu eto idibo yi sugbọn awọn eeyan wa lẹyin rẹ nitori pe o jẹ ọmọ Yoruba.

Nigba ti polongo ibo ni Yola, ani lati bẹ pe ki wọn gbe Tinubu kuro nitori pe pupọ awọn nnkan to n sọ lo jẹ irọ nla.”

O binu nitori pe o ko ri owo ọfẹ gba lọwọ Tinubu- APC fesi fun Najatu

Ẹka ẹgbẹ oṣelu APC to n risi ipolongo ibo Aarẹ ti fesi pada fun Najatu Mahammed, olori ẹka naa tẹlẹ, ti wọn si fẹsun kan pe nitori pe ko ri owo ọfẹ gba lọwọ Tinubu lo fa to fi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Ninu atẹjade kan, Kaasim Afugbua, ọmọ ẹgbẹ APC fi lede, o ni alaga fun ileeṣẹ ọlọpaa tẹlẹ naa n reti owo ọfẹ lo sokunfa idi to ya juro ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni bi eeyan ba wa ni iye ọdun ti Najaatu wa, to si tu ṣe bi pe o fẹran owo, Tinubu ni isẹ lati ṣe to ba di aarẹ orilẹede Naijria.

“Ọsẹ to kọja, Najaatu Muhammed yọ ara rẹ kuro laarin awọn ọmọ lẹyin Tinubu, to si darapọ mọ Atiku, to si tun kede pe ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria ma dibo fun idibo nunu oṣu to n bọ.

“Nitori nnkan ti Najaatu yoo jẹ lo fa ati pe o ti wa pẹlu Atiku tipẹ tipẹ. Ariwo lasan ni obinrin naa pa sita.

“Iru awọn eeyan bi Najaatu ni wọn fẹ ki nnkan jẹ ti wọn nnkan sugbọn Asiwaju ni ọna ko si ni ibẹ rara, to si jẹ eyi lo fa to fi n ba orukọ Tinubu jẹ kiri.”