PDP fòfin dé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ kan l‘Ekiti, Wike ní ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers ti bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fi ofin de awọn ọmọ ẹgbẹ kan, to si ni ki wọn lọ rọkun nile fun igba diẹ naa.

Gomina Wike koro oju si isẹlẹ naa lọjọ Satide nigba to n kopa ninu iponlogo ibo ni ijọba ibilẹ Khana nipinlẹ Rivers.

Wike sọ oko ọrọ si iṣejọba alaga ẹgbẹ oṣelu naa eyiun, Iyorchia Ayu ati awọn ẹmẹwa rẹ.

O ni bi Ayu ṣe le awọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti, ni ko ni ṣe e ni anfani kankan rara.

Ọmọ to ba ni iya oun ko ni sun, oun gan ko ni sun, awa duro de yin - Wike

“Lile awọn eeyan ko ni anfani kankan ti yoo ṣe fun Iyorchia Ayu rara, a si ti wa wọ iya ija bayii.

“Gbogbo ọna labẹ ofin ni a ma lo lati tako ipinnu ti a ba ri pe ko ba ofin mu.

“N jẹ ẹ ro pe ẹ le ma dunkoko mọ awọn eeyan pe ẹ le wọn kuro ninu ẹgbẹ, radarada.

“A wa ti kọja gbogbo ipele yẹn. A ni igbagbọ ninu ẹgbẹ oṣelu to ba bọwọ fun eto ofin rẹ nikan.

“Ọmọ to ba ni iya oun ko ni sun, oun gan ko ni sun. Awa duro de yin.”

Ki lo fa a ti PDP fi ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ kan lọ rọkun nile fun igba diẹ l‘Ekiti?

Ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe awọn ti ofin de Sẹnẹtọ Chimaroke Nnamani lati ipinlẹ Enugu ati Oloye Chris Ogbu lati ipinlẹ Imo lẹsẹkẹsẹ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ, Debo Ologungba fi lede , o ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn ṣe iwadi pe awọn ẹgbẹ na ko tẹle ofin ti ọdun 2017.

Bakan na lo ni ẹgbẹ naa ti buwọlu pe ki awọn ẹgbẹ kan nipinlẹ Ekiti lọ rọkun nile fun igba diẹ nitori pe wọn ṣe ojumeji fun ẹgbẹ oṣelu naa.

O darukọ awọn ọmọ naa: Ayeni Funso lati ariwa ipinlẹ Ekiti, Ajijola Lateef Oladimeji lati arin gbogbo Ekiti, Emiola Adenike Jennifer lati guusu Ekiti keji, ati Ajayi Babatunde Samuel lati ariwa keji ipinlẹ.

Awọn yooku ni Olayinka James Olalere, Akerele Oluyinka, ati Fayose Oluwajomiloju John.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, “Ẹgbẹ oṣelu PDP rọ awọn olori ati awọn ọmọ lati ṣe arawọn lọkan ninu igbinyanju lati da gbogbo ikolọ ẹgbẹ naa pada, ki wọn si tun pada si ipo aarẹ ninu oṣu to n bọ.”