Nínú àwọn dókítà 280 tí a ní, ayédèrú ni 199 nínú wọn – Ìjọba Zamfara

Doctor

Oríṣun àwòrán, Pexels:Tima Miroshnichenko

Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle ti sọ pe ko din ni ayederu dokita mọ́kàndínnígba (199) to n gba owo ijọba lai ṣiṣẹ.

Matawalle lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Maradun.

Gẹgẹ bii ohun ti gomina ọhun sọ, oṣoṣu ni ijọba n san owo fun ọ̀rìnlénígba (280) dokita ki aṣiri to tu pe dokita mọ́kànlélọ́gọ́rin (81) pere lo jẹ ojulowo ninu wọn.

Governor Bello Matawalle

Oríṣun àwòrán, Governor Bello Matawalle

O sọ siwaju si pe oun ti ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC ipinlẹ naa lati ṣawari awọn mọ́kàndínnígba ayederu dokita ọhun lọna ati dẹkun irufẹ iwa bẹẹ lọjọ iwaju.

Matawalle ni aṣiri awọn ayederu oṣiṣẹ naa tu lẹyin ti awọn bẹrẹ iforukọsilẹ gbogbo oṣiṣẹ ipinlẹ ọhun nibi ti wọn ti n gba oju ati ika wọn silẹ.

Gomina naa sọ pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin afojusun ijọba lati bẹrẹ eto lati maa san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, eyii to jẹ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

O ni “Ni kete ti a sọ pe a fẹ bẹrẹ si n san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, a o kan le maa san owo naa bẹyẹn, oni awọn igbesẹ ti a gbọdọ tẹle.”

“Nigba ti a bẹrẹ iforukọsilẹ, a ṣakiyesi pe dokita 280 lo n gbowo oṣu lọwọ ijọba amọ dokita 81 pere ni a ni nipinlẹ Zamrafa.”

Ko si ojulowo oṣiṣẹ ti yoo padanu iṣẹ rẹ

Matawalle fi kun pe ko si ojulowo oṣiṣẹ kankan ti yoo padanu iṣẹ rẹ lẹyin eto iforukọsilẹ naa ti wọn gunle.

O ni “Mi o ni da ẹnikẹni duro lẹnu iṣẹ, koda, ṣe ni mo maa fun awọn oṣiṣẹ naa nile ti wọn yo maa gbe.”

“Mo ti kọ ile 450 fun wọn ti ẹnikẹni ko si tii mọ nipa rẹ, amọ lọjọ Aiku ni mo maa fun wọn ni kọkọrọ ile naa.”