Tí mo bá wọlé aàrẹ, Àtúntò ìṣèjọba ni màá kọ́kọ́ yanjú- Atiku Abubakar

Igbakeji Aare nigbakan ri, Alhaji Abubakar Atiku to jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) ti ṣeleri lati se atunto orilẹede Naijiria ti o ba wọle gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun yii.
Atiku, sọ eyi ni Ojobo lakoko ti o n ba awọn lẹgbẹ lẹgbẹ olugbe ipinlẹ Ọyọ sọrọ ni gbagede Jogor ni Ibadan.
Nibẹ ni ipade apero fun awọn oludije sipo aarẹ eyiti ẹgbẹ idagbasoke iwọ oorun orilẹ-ede Naijiria gbe kalẹ (SWDSF)ni ilu Ibadan.
Igbakeji aarẹ tẹlẹri. nigba to n ba awọn eeyan sọrọ lasiko ijiroro naa ni awọn eniyan iwọ oorun orilẹ-ede yii ti beere fun atunto ijọba fun ọpọlọpọ odun.
Atiku ṣeleri pe atunto orilẹ-ede ti awọn eniyan ti n pariwo fun yoo wa si imuse nigbati oun ba de ijọba ni oṣu karun un ọdun yii.
Atiku nigba to n sọrọ siwaju sọ wi pe ijọba ẹgbẹ oṣelu APC ti kuna lati tun orilẹede ṣe, bo tilẹ je wi pe ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti n pariwo fun un lati ọpọlọpọ odun seyin.
Lẹyin naa lo sọ fun awọn to wa nibi apero naa pe iṣakoso oun yoo ṣe ohun ti ijọba Muhammadu Buhari kuna lati ṣe.
Atiku ni atunto naa yoo fun ijọba ipinlẹ ati awọn ijọba ibilẹ ni agbara lati le ṣe ijọba laisi idiwọ ijọba apapọ.
O ni atunto orilẹ-ede Naijiria yoo jẹ ọkan ninu awọn oun ti ijọba rẹ yoo kọkọ ṣe laarin ọdun akọkọ ijọba oun.
Ọgbọ̀n mílíọ̀nù ọ̀dọ́ ni yóò ríṣẹ́ tí mo bá di Ààrẹ – Adewole SDP

Oríṣun àwòrán, Adewole Adebayo ESQ
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ SDP Adewole Adebayo ni ti oun ba di aarẹ orilẹ-ede yii aṣẹ ijọba yoo wa lati ni ọlọpa Ipinlẹ.
Adewole sọ ọrọ yii nibi apeero ti ẹgbẹ idagbasoke iwọ oorun orilẹ-ede Naijiria gbe kalẹ (SWDSF) fun awọn oludije sipo aarẹ orilẹ-ede yii.
Ninu ẹtọ apeero naa to waye ni Ibadan olu ilu Ipinlẹ Oyo,Adewole nii bí eto aabo orilẹ-ede yii se mẹhẹ ọna abayọ kan ṣoṣo ni lati ri wi pe ẹkun kọkan ni awọn ikọ ọlọpa rẹ.
O ni bi ko ti sii eto aabo to peye lorilẹede yii ko sẹyin bi awọn ọna to wọ orilẹ-ede yii se pọ laisi aabo to daju.
O seleri lati lo imọ ẹrọ igbalode lati ri wi pe iwọle ati ijade orilẹ-ede ninu orilẹ-ede yii ni oju ijọba apapọ yoo to.
Nigba ti o bu ẹnu atẹ lu eto isuna Naijiria Adewole ni laarin ọdun kan ti oun ba je aarẹ millionu ọgbọn ọmọ orilẹede yii ni oun yoo pese iṣẹ fun.
O ni ọpọlọpọ owo ti ijọba apapọ ya soto fun idagbasoke orilẹede yii ni o bo si ọwọ die ninu awọn oloro ti o jẹ ọrẹ fun ijọba apapọ.
Ninu ọrọ rẹ Adewole ṣalaye pe ipese ọna ti o dara,idagbasoke iṣẹ ọgbin ni oun yoo mu ni okunkudun lati ri wi pe ounjẹ po fun olukuluku eyi ti yoo mu ki opolo ọdọ ni iṣẹ lapa.












