Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ́míí Kamal Aboki tó jẹ́ gbajugbajà adẹ́rìnpòṣónú Tiktok ní Kano

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Others

Ọpọ eeyan lo n ṣe idaro ọdọkunrin adẹrinpoṣonu to gabjumọ lori ayelujara Tiktok ni ipinle Kano bayii.

Kamal Aboki lo maa n pa awọn eeyan lẹrin ni ariwa Naijiria.

O dalaisi nibi ijamba ọkọ to waye ni Kano leyin to de lati ipinle Borno.

Tishama Cemetery ni ile ikẹyin ti wọn sin Kamal Aboki si nilan esin Islam eyi

ti o wa ni ilu Kano

Aworan

Oríṣun àwòrán, Usman Illiyasu

Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe ṣẹlẹ?

Usman Iliyasu ẹgbọn ologbe nigba ti o ba akọroyin ile iṣẹ BBC sọrọ ni aburo oun ririn ajo lọ si ilu Maiduguri.

O ni oun pe Kamal ni bii aago marun uirọlẹ ti o si ṣalaye pe oun wa ninu moto ti o un gbee bọ pada si Kano.

Usman ni ẹnikan lọ tufo iku aburo oun fún idile won lati igba naa ni iya awọn ti wa ninu ibanuje okan.