Iyabọ Yerima, ọmọ Adisa Akinloye di adelé adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, others
L'ọjọ Aje ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde burawọle fun adajọ Iyabọ Ṣubulade Yerima gẹgẹ bii adele adajọ agba ipinlẹ Ọyọ.
Iburawọle fun adele adajọ agba tuntun naa lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti adajọ tẹlẹri, Muntar Abimbola ṣiṣẹ fẹyinti.
Nibi ipejọpọ ranpẹ naa to waye ni ọọfisi Gomina nilu Ibadan, Makinde ṣalaye pe ijọba oun yoo fun adele adajọ agba tuntun ni gbogbo atilẹyin to nilo lati ṣe ojuṣe rẹ bo ti tọ.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹka ijọba to ku lati rii daju pe eto idajo di gbigbe kalẹ ni ilana igbalode.
Wo awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa adele adajọ agba tuntun n'ipinlẹ Ọyọ
A bi Iyabọ Ṣubulade Yerima sinu idile gbajugbaja Amofin, Oloṣelu ati agba Oye nilẹ Ibadan, Adisa Meredith Akinloye ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹsan an ọdun 1958 ni agboole Akinloye of Oje-Itutaba ilu Ibadan, ni ijọba ibilẹ Ila Oorun Ariwa Ibadan.
O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Omolewa Nursery and Primary School, Oritamefa, Ibadan laarin ọdun 1962 si 1969.
Bakan naa ni o lọ si ile ẹkọ Girama St Margret Girl’s Secondary School, Ilesa, lati oṣu kini ọdun 1970 si oṣu keje ọdun 1974.
O tẹsiwaju lọ si ile ẹkọ Girama Ibadan Grammar School, Ibadan, laarin ọdun 1974 si 1975.
Ipele ikeji eto ẹkọ ti o ka, iyẹn 'A-level' nile ẹkọ gbogboniṣe Ibadan waye laarin ọdun 1975 si 1977.
Laarin ọdun 1978 si 1981 ni o kẹkọọ gboye akọkọ ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile-Ifẹ, ki o to rin irinajo lọ si oke okun nibi ti o ti kẹkọọ nipa imọ ofin ni 'University of Buckingham, United Kingdom' laarin oṣu kẹsan an ọdun 1981 si oṣu kejila ọdun 1983.
O tẹsiwaju lọ ile ẹkọ giga imo ofin orilẹede Naijiria n'pinlẹ Eko lati kẹkọọ gboye imọ nipa ofin, gẹgẹ bi o ṣe di Amofin lọdun 1985.
Yerima ṣe agunbanirọ ni ẹka eto ẹkọ ti a ti n kọ nipa ofin ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile-Ifẹ laarin ọdun 1985 si 1986.
Lẹyin eyii ni o bẹrẹ iṣẹ Amofin ni ipinlẹ Kaduna bẹrẹ lati ileeṣẹ Amofin Baba Amartey & Co., ki o to da ileeṣẹ Amofin tiẹ, eleyii ti o pe ni 'Yerima & Co.' silẹ nilu Zaria, ipinlẹ Kaduna laarin oṣu karun un ọdun 1986 si oṣu kẹrin ọdun 2001.
A yan an gẹgẹ bii Adajọ agba ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ninu oṣu kẹfa ọdun 2001.
Iyabo Ṣubulade wa nile ọkọ, osi ti ni awọn ọmọ ati ọmọ ọmọ.












