Nkan pàtàkì mẹ́jọ tí Peter Obi sọ ní Chatham House

Oludije ẹgbẹ Labour Party sipo aarẹ Naijiria ninu idibo ọdun 2023, ti sọ pe oun yoo yanju iṣoro aabo, ina mọnamọna, gbese ti Naijiria jẹ ati awọn nkan mii to ba fi di aarẹ Naijiria.
Peter Obi sọ ọrọ naa lasiko to ṣe abẹwo si Chatham House. ni United Kingdom lọjọ Aje.
O ni lara nkan ti oun yoo ṣe ti oun ba fi di aarẹ Naijiria, ni lati fọwọsowọpọ pẹlu banki apapọ Naijiria, lati fi opin si bi iye ti wọn n ṣẹ owo Naira si ti ilẹ okeere ko ṣe dọgba ni Naijiria.
Obi sọ pe ilana iṣejọba ti Naijiria n lo lọwọlọwọ jẹ ti iwa ọdaran, eyi to ti fi orilẹ-ede naa sinu ìṣẹ́.
O ni oun yoo wó ilana naa palẹ ti oun ba fi di wọle ninu idibo aarẹ ninu idibo oṣu to n bọ.
Awọn nkan mii ti Peter Obi tun sọrọ le lori
- Lara nkan ti Obi tun mẹnuba ni eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, paapaa nipasẹ obitibiti gbese ti Naijiria jẹ, eyi to n waye nitori bi awọn kan ṣe n ji eporọbi wà.
- Ọgbẹni Obi sọ pe ayipada ti iṣejọba oun yoo mu ba ina mọnamọna, yoo nipa lara ipese ina, pinpin ati bukaata rẹ.
- Owo ti Naijiria yoo ma a ya yoo wa fun nkan to le mu èrè wa nikan
- Ayipada si eto ẹkọ giga pẹlu afojusun lati sọ wọn di ibudo fun iwadii imọ ijinlẹ, idagbasoke ati orisun imọ to le di owo fun idagbasoke Naijiria
- Ẹkọ nipa imọ ẹrọ, iṣẹ ọwọ, ere idaraya, kata-kara, ati imọ kọmputa yoo di dandan ni awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama.
- Peter Obi sọ pe oun yoo le òṣì kuro ni Ariwa Naijiria, nipa ṣiṣe amulo awọn ilẹ to wa nibẹ fun orisun ọrọ aje ju eporọbi lọ.
- Lori ọrọ ina ẹlẹtiriiki, Obi sọ pe ijọba oun ‘ogun nkan o fararọ ni oun yoo kede ni ẹka ipese ina’. “Ẹnikẹni to ba si fẹ ṣe idiwọ, yoo ba ogun lọ.”
- Bakan naa lo tun sọ pe oun yoo ṣẹda ayika to bojumu lati fa oju awọn oludokowo lati ilẹ okeere mọra, nipa gbigbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe awọn ofin to wulo.
Ki ni Chatham House gan?
Orukọ mii ti Chatham House n jẹ ni ‘Royal Institute of International Affairs.’Ilu London ni olu ọọfisi ajọ naa wa nilẹ Gẹẹsi.
Chatham House jẹ ibi ti wọn ti maa n sọrọ nipa bi ilu yoo ṣe toro ti yoo si ni itẹsiwaju.
Gbogbo ọrọ to maa n jade nibẹ lo kimi, to si maa n gba iyi kaakiri agbaye.












