Son of the prophet: Ọdún mẹ́fà ni mo fi kọ́ṣẹ́ láti máa hùwà / sọ̀rọ̀ bíi Oyedepo- White Olasunkanmi Barry

Àkọlé fídíò, Son of the prophet: Ọdún mẹ́fà ni mo fi kọ́ṣẹ́ láti máa hùwà / sọ̀rọ̀ bíi Oyedepo- White

Baba mi ninu Oluwa ni David Oyedepo- Son of the Prophet.

Ṣé ẹ rántí adẹ́rìnínpòṣónú tó máa ń sọ̀rọ̀ bíi David Oyedepo? BBC Yorùba ti wa Barry White ọmọ Omupo ni Kwara kàn, O ni: Ọdún mẹ́fà ni oun fi kọ lati maa huwa bii David Oyedepo.

White Olasunkanmi Barry jẹ ọmọ bibi ilu Omupo nipinle Kwara ni aarin gbungbun ariwa Naijiria.

O ṣalaye die lara ohun ti oju rẹ ri to ko to ri aanu gba

White ti ọpọ maa n pe ni Son of the Prophet mẹnuba awọn idojukọ to ti ri laye rẹ.

Ati awọn ere ati ayo tp ti tẹlẹ iṣe aderinposonu to n sin eeyan jẹ ti ohun n ṣe.

Bakan naa lo sọ ohun to ṣẹlẹ nigba to pade Pasito David Oyedepo fun igba akọkọ.