Ẹgbẹ́ Agbẹkoya wọ́ Gómìnà mẹ́wàá lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, @Others
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba Koya leadership Training Foundation ti gbẹ awọn Gomina to n daari awọn ipinlẹ ti nsọ ede Yoruba ni ẹkun Iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ.
Ajọ ẹgbẹ Yoruba koya ninu atejade kan ti wọn fi lede latowo Demola Sanyaolu ti aarẹ ẹgbẹ na Otunba Giwa Deji Osibogun fọwọsi
ni iwa aibikita awọn Gomina lati ẹkun Iwọ oorun guusu Naijiria lori eto aabo ati ẹmi awọn ọmọ Yoruba.
Ninu iwe ipejọ (IB/CS/189/22 ti o wa niwaju kootu ijọba apapọ ti ile ibadan)
ni awọn adari ẹgbẹ naa Otunba Ayodeji Osibogun, Bisi Owumi,Oloye Ronke Okusanya, SenatoOlatokunbo Ogunbanjo ati arakunrin olakunle Osuntokun fi owosi lati gbe awọn gomina ati awọn agbẹjọro agba awọn ipinle ti ọrọ kan lọ si ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, @Others
Awọn ilu ti ẹgbẹ agbekoya ohun gbé lọ sí ile ẹjọ ni ipinlẹ Edo,Ekiti,Kogi,Kwara,Lagos,Ogun,Osun,Ondo ati ipinlẹ Ọyọ.
Awọn ẹgbẹ agbekoya ni aisi alaafia ni awọn ipinlẹ ti wọn ti ń sọ ede Yoruba lofa idi ti awọn fi gbé wọn lọ si ile ẹjọ.
Wọn ni iwa ijinigbe lopopona ibadan sì Eko, ipinlẹ Edo,Kwara, Kogi Ogun,Ondo ti o waye latọwọ awọn darandaran ati awọn odaran ni awọn Gomina ko bikita ti wọn si je ki ọrọ abọ jewon logun.
Wọn ni latari iwa ijinigbe fifi ẹran jẹ ọkọ,jẹ ki adinku baa ise oko ni ilẹ Yoruba ti awọn agba lọ si le ṣe iṣe kankan mo n.
Gege bi Otunba Osibogun se so ninu iwe atẹjade naa, Osibogun ni ẹgbẹ awọn ti ko leta si gbogbo awọn Gomina ti ọrọ kan ti wọn ko si fesi,eyi lo mu ki awọn gbe wọn lọ si ile ẹjọ.
O ni igbesẹ yii o mu ki awọn Gomina wọnyi ṣe iṣe ti wọn diboyan wọn si.














