Ìyá ẹni ọdún 97 tó lọ́wọ́ nínú ikú 10,505 èèyàn rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì he ní Germany

Imrgard Furchner

Oríṣun àwòrán, AFP

Obinrin kan to ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọwe fun ọkan lara adari ọmọ ogun Nazi ti ri ẹwọn he lẹyin to jẹbi ẹsun pe o lọwọ ninu iku 10,505 eeyan.

Irmgard Furchner, to jẹ ẹni ẹni ọdun mẹtadinlọgọrun ṣiṣẹ akọwe ni ibudo Stutthof lasiko ti ko tii to ọmọ ọdun mejidinlogun laarin ọdun 1943 si ọdun 1945.

Furchner wa lara awọn obinrin to jẹjọ fun iwa ọdaran to waye lọdun naa lọhun, ki wọn to dajọ ẹwọn ọdun meji naa fun.

Bo tilẹ jẹ pe obinrin ọhun kii ṣe ara awọn ọmọ ogun, adajọ sọ pe o mọ nipa ọpọ nnkan to n ṣẹlẹ ninu ibudo naa.

Igbagbọ wa pe ko din ni ẹgbẹrun marundinlọgọrin eeyan to jade laye ni Stutthof naa ti wọn ko awọn eeyan si, lara awọn ti awọn ẹya Jew atawọn ọmọ ogun Soviet ti ọwọ tẹ si wa.

Iroyin ni onururu ọna ni wọn fi n pa awọn eeyan ni Stuttof naa lai bikita, nigba ti wọn fi afẹfẹ gaasi ‘gas chamber’pa ọpọ awọn mii.

Ile ẹjọ ọhun, to wa lagbegbe Itzenhoe, ni Germany gba ọrọ latẹnu awọn eeyan to wa ninu ibodu iku naa ko to ṣedajọ rẹ.

Nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ lọdun 2021, Furchner kọkọ fẹsẹ fẹ kuro nile awọn arugbo to n gbe ki ọwọ awọn agbofinro to tẹ.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fi adari ibudo naa, Paul-Werner Hoppe si ẹwọn lọdun 1995 fun pe o lọwọ ninu ipaniyan amọ o gba ominira lẹyij ọdun meji.

Wayi o, obinrin ọhun ti wa tọrọ aforiji fun ipa to ko ninu iku awọn to jade laye ni ibudo ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe ẹwọn ọdun meji ni wọn da fun, obinrin naa ko ni foju ba ọgba ẹwọn.