Kíló ń ṣẹlẹ̀ láàrin Ọ̀gá CBN Emefiele àti DSS?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ Banki apapọ ni Naijiria ti kede pe adari banki apapọ naa, Godwin Emefiele ti pada si ẹnu iṣẹ rẹ lẹyin isinmi ni oke okun.

Eyi ko ṣẹyin iroyin ti ko fidi mulẹ pe Ajọ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria ti fi panpẹ mu Emefiele.

Amọ ninu atẹjade ti ẹka eto iroyin Ajọ CBN, Osita Nwanisobi gbe jade lo ti ni adari Banki agba naa ti ni lati bẹrẹ iṣẹ rẹ lọkunkundun.

Eyi n waye ṣaaju ipade ajọ Monetary Policy Committe ti yoo waye ni Ọjọ Kẹtalelogun si Ọjọ Kẹrinlelogun, ọdun 2023.

Bakan naa ni Ajọ DSS fi lede pe iroyin ofege ni pe awọn fi panpẹ ọba mu Emefiele, wọn ko si otitọ kankan ninu iroyin ọhun.

Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe bẹrẹ...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin to ti n ja ranyin lati Osu Kejila, odun 2022 ni pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuye ni Naijiria ti fẹ fi panpẹ mu Ọga agba ileeṣẹ Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele.

Eleyii ko ṣẹyin igbeṣẹ ileẹjọ giga ni Abuja to paṣẹ pe DSS ko ni aṣẹ lati fi panpẹ ọba mu Emefiele nitori wọn ko ni ẹsun to munadoko.

Saaju ni ajọ DSS ti fi ẹsun ṣiṣe agbatẹru fun igbesunmọmi kan Emefiele, ti wọn si gbe lọ si ileẹjọ.

Ajọ DSS ni nitori Emefiele n sagbatẹru fun awọn agbesunmọmi, iyẹn tunmọ si pe o jẹbi ọdaran nipa eto ọrọ aje.

Adajọ to gbọ ẹjọ naa ni ajọ DSS ko fidi rẹ mulẹ boya Emefiele ti wọn fẹsun kan ni ọga agba CBN.

Ati pe to ba jẹ oun ni, o yẹ ki Ajọ DSS kọkọ fi ọrọ naa to aarẹ Buhari leti ki wọn to gbe ẹjọ naa sita.

Nitori naa Adajọ John Terhemba wa da ẹjọ naa nu pẹlu aṣẹ pe ki wọn lọ wa ẹri to daju si ki o le fidi mulẹ.

Nitori naira tuntun ni wọn sẹ gbogun ti Emefiele – Ajọ Ajafẹtọ

Lati igba ti ajọ CBN ti kede owo tuntun ni Naijiria ni orisirisi nkan ti n ṣẹlẹ lori ọrọ Ọga Godwin Emefiele.

Ile Aṣofin agba ni Naijiria ni awọn ko buwọlu igbesẹ naa, amọ Minisita fun eo iṣuna, Zainab Ahmed ni ko si ohun ti Emefiele ṣe to ṣẹyin ohun.

Amọ awọn ajọ Ajafẹtọ kan to fi mọ ẹgbẹ alatako ni ko lẹtọ ki wọn ni Emefiele lara nitori igbesẹ to gbe lori eto ọrọ aje.

Ajọ coalition of national interest defenders (CNID) wa fikun un pe ajọ DSS fẹ ṣakoba fun Emefiele ni.

Bakan naa ni wọn kesi aarẹ Buhari ati Olootu eto idajọ ni Naijiria lati gbe igbeṣẹ lori ọrọ naa.

Ọrọ Emefiele niise pẹlu eto aabo ilu- DSS

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni awọn gbọdọ ṣe iwadii ofin toto lori ẹsun to gbode kan to si niise pẹlu aabo ilu.

Bakan naa ni wọn ni awọn n ṣiṣẹ fun eto aabo gbogbo ọmọ Naijiria ni nitori naa ki awọn eniyan ni igbekẹle ninu wọn.

Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ ajọ DSS, Peter Afunaya ni awọn kan n lọ iroyin ofege lati fi ba iṣẹ awọn jẹ.

Amọ o ni ajọ naa yoo tẹpa mọ iṣẹ aabo ilu lati ri pe alaafia jọba ni gbogbo ẹkun lati ilu lorilẹede Naijiria.