N kò mọ bí òkò ṣe bá mí lójú lọ́jọ́ ìgbeyàwó mi, ilé ìwòsàn ni mo ti yajú – Ìyàwó ọ̀sìngín ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Daily Trust
Lẹyin ọsẹ kan gbako ti isẹlẹ kan to da ayẹyẹ igbeyawo ru waye nilu Kano, iyawo ọsingin to ko ijamba lasiko isẹlẹ naa, ti bawọn akọroyin sọrọ.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju lori bi wahala se bẹ silẹ lasiko ayẹyẹ igbeyawo kan nilu Kano lasiko tawọn ẹsọ fijilante ya wọ ibẹ.
Gẹgẹ bi awọn eeyan to wa nibi ayẹyẹ naa ti salaye, awọn mọlẹbi iyawo lo ransẹ pe awọn fijilante naa pe ki wọn wa dawọ ayẹyẹ naa duro, nibi ti wọn ti lo gbogbo elere lati wa kọrin nibẹ.
Alaye awọn mọlẹbi naa ni pe awọn agba awujọ lagbegbe naa ti kede saaju pe ko gbọdọ si irufẹ ipejọpọ bayii ni agbegbe naa lasiko yii.
Rogbodiyan bẹ silẹ nigba tawọn fijilante naa de, ti awọn kan si n lẹ oko, ti oko kan si lọ ba oju iyawo tuntun.
“Ko ye mi bi oko se ba mi loju, ile iwosan ni mo ti yaju”
Ninu alaye rẹ, iyawo tuntun naa ni oun oun ko tilẹ le sọ bi oko se ba oju oun nitori ojiji lo waye, ti oun si daku nibẹ.
“Mo kan le ranti igba tawọn fijilante naa de sibi ayẹyẹ igbeyawo mi, ti wọn si to eeyan mẹwa niye.
Se ni wọn n na awọn eeyan, ti wọn si n leri leka pe ayẹyẹ igbeyawo naa ko ni waye rara.
Lati akoko naa, n ko mọ ohun to sẹlẹ mọ am mo sa ba ara mi nile iwosan lasiko ti mo yaju.
Koda, wọn ti fi bandeji bo oju mi kan to kun fun ọgbẹ, bi isẹlẹ naa se waye, ko tiẹ ye mi.”
Wọn mọọmọ sọ ọjọ ayọ wa di ibanujẹ ni, o yẹ kawọn alasẹ da si isẹlẹ yii - Ọkọ iyawo tuntun
Nigba ti oun naa n salaye bi isẹlẹ yii se waye, ọkọ iyawo tuntun, Hamisu Bala ni awọn eeyan kan lo mọọmọ pinnu lati sọ ọjọ ayọ awọn di ọjọ ibanujẹ.
O wa n rawọ ẹbẹ sawọn alasẹ lati dide ja fun ẹtọ iyawo oun.
“A ko le fori jin awn eeyan to ba ọjọ ayọ wa jẹ, a si fẹ ki ijọba dide si ọrọ naa nitori pe wọn mọ pe ibi igbeyawo ni.”
A ko fi ọwọ kan ẹnikẹni nibi igbeyawo naa, awọn araalu atawọn adari abule naa lo n bara wọn ja – Olori Fijilante
Wayi o, Naziru Abubakar Adamu tii se adari ikọ fijilante nijọba ibilẹ ti isẹlẹ naa ti waye, ti salaye pe kii se ọwọ awọn fijilante ni igbeyawo naa ti daru.
O ni awọn osisẹ oun ko fi ọwọ kan ẹnikẹni nibudo ti igbeyawo naa ti n waye.
Amọ Adamu ni awọn eeyan nibi ayẹyẹ naa atawọn adari abule to se ofin pe ipejọpọ ko gbọdọ waye, ni wọn kọju ija si ara wọn nibẹ.
“A ko se ohunkohun nibi ayẹyẹ igbeyawo naa, igbimọ kan tawọn asaaju abule naa gbe kalẹ, o fofin de lilo gbogbo elere lasiko ayẹyẹ lagbegbe wọn.
Ba si se n sọrọ yii, olu ileesẹ ọlọpaa ni Kano la wa, lati wa yanu isẹlẹ naa.”
Lọwọlọwọ bayii, ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti mu eeyan meji si atimọle lori isẹlẹ naa, ti wọn yoo si foju wn bale ẹjọ laipẹ.
Àwọn ọkùnrin tó ń bá ‘DJ’ jà nítorí orin lọ́jọ́ ìgbéyàwó fi òkúta fọ́ ìyàwó lójú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti gbe ọkunrin meji lọ sile ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn fọ oju obinrin kan lọjọ igbeyawo rẹ.
Opin ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn afurasi naa gbiyanju lati pa orin ti DJ fi n da awọn eeyan laraya, lẹyin ti wọn ni orin naa ko ṣe itẹwọgba.
Asiko ti wọn n ba DJ naa fa wahala ni wọn sọ okuta si oju omidan to n ṣe igbeyawo, eyii to ko ma riran mọ.
Iroyin ni ṣe lawọn eeyan naa n sọ okuta si ara wọn nigba ti ija bẹ silẹ ti ọkan lara awọn okuta naa si ba iyawo loju.
Ọlọpaa ni awọn afurasi mejeji ti wa ni akata awọn bayii.
Inu ọkọ iyawo bajẹ
Ọkọ obinrin ọhun, Mustapha Bala ti sọ pe inu oun ko dun si ohun ti wọn ṣe si iyawo oun, awọn afurasi naa si gbọdọ jiya to tọ labẹ ofin.
O ni “Inu mi ko dun rara nitori ṣe ni iyawo mi n wa ẹkun mu.”
“Mi o le sun, mi o le wo lẹyin iṣẹlẹ naa, wọn gbọdọ jiya to tọ labẹ ofin.”
Mutapha sọ pe iṣẹlọ ọhun ṣe akoba fun eto igbeyawo naa, amọ lọwọ yii, bi wọn yoo ṣe tọju obinrin naa lo jẹ oun logun.
O ni bo tilẹ jẹ pe iyawo oun ti padanu oju rẹ kan, oun ṣi nifẹ rẹ, oun ko si ni fi silẹ nitori ipenija oju ọhun.















