''Lóòtọ́ ní wọ́n jí Àlùfáà ìjọ Aguda lọ l'Ekiti, a kò tíì gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ajínigbé ''

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọ Aguda lorilẹede Naijiria ti kede pe lọọtọ ni wọn ji adari ijọ St. George Catholic Church, Omu-Ekiti Revd. Fr. Michael Olofinlade gbe lọ.
Ni opin ọṣẹ ni iroyin jade gbe awọn ajinigbe tun ti ṣọṣẹ ni opopona Itaji si Ijelu-Ekiti ni opin oṣẹ.
Ninu atẹjade ti Biṣọọbu Ijọ Aguda ti ipinlẹ Ekiti, Most Rev Felix Femi Ajakaye fi lede gba ọwọ agbẹnusọ diocese naa, Rev.Fr. Anthony Oluwole Ijasan ni wọn ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
‘Titi di asiko yii a ko tii gburo rẹ tabi ki awọn ajinigbe kan si wa’
Bisọọbu Ajakaye ni Ọjọ Satide, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kini, ọdun 2023 ni ijinigbe naa waye lasiko to n bọ wa si ile ijọsin rẹ.
‘Fr Olofinlade lọ fun iṣẹ iranṣẹ kuro ni ile ijọsin rẹ amọ wọn jigbe lasiko to n pada bọ ni nkan bi aago mẹfa irọlẹ.’
‘Ibi ti wọn ti ji ‘Father’ naa gbe wa ni aarin Itaji-Ekiti si Ijelu-Ekiti ni ijọba ibilẹ Oye, ni ipinlẹ Ekiti.’
‘O to irin kilomita mẹrin si ile ijọsin rẹ.’
‘Titi di asiko yii a ko tii gburo rẹ tabi ki awọn ajinigbe kan si wa tani diocese ijọ Aguda ni ipinlẹ Ekiti.’
‘Ẹ ba wa gbadura ki O pada si idi iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ayọ ati alaafia’
Bakan naa ni Fr Olofinlade fi lede pe ki awọn eniyan fi adura ran wọn lọwọ ni akoko yii.
‘E gbadura ki wọn fi iranṣẹ Ọlọrun naa silẹ ni kiakia lai ni ewu.’
‘Ẹ ba wa gbadura ki O pada si idi iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ayọ ati alaafia, lati le sin Olorun ati awọn eniyan ti Ọlọrun fi si ikawọ rẹ.’
‘Pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun to jẹ ireti wa ati agbara wa, gbogbo ibi to ba ran wa lọ ni a o lọ pẹlu ayọ ati alaafia pẹlu itẹlọrun.’












