''Mò ń ta ilé ọmọ mi, mo tún ń fi ẹyin ilé ọmọ hááyà, eͅ wá rà á láti bímọ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni iroyin yii nitori ohun ti ko fi bẹẹ wọpọ ni isẹlẹ to n waye yii.
Isẹlẹ ara ọtọ yii lo n fidi rẹ mulẹ pe awoͅn eniyan ti n ra ile oͅͅmoͅ bi eͅni ti n ra oͅkoͅ ayoͅkeͅleͅ ni orileͅede Columbia.
Iwadii BBC fihan pe awoͅn oͅdoͅbinrin to n ta ile oͅmoͅ woͅn naa, n ta lati ri aje jeͅun ni.
Obinrin to soͅ iriri reͅ fun akroyin BBC ni oun ma n ya awoͅn eniyan ni ile oͅmoͅ oun, eleyii ti woͅn n pe ni ‘surrogacy.’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ori ayelujara ni awoͅn obinrin ti n ta ile oͅmoͅ woͅn…
Ninu atẹjade kan to fi si oju opo Facebook reͅ, ni obinrin naa ti ni ‘’ Bogota ni mo ti wa, mo si n ta ile oͅmoͅ mi’’
Iroyin fi lede pe arabinrin yii ki n sͅe eͅni akoͅkoͅ ti yoo sͅe iru nkan bawoͅnyii, to fi moͅ awoͅn ara ileͅ Venezuela.
Lara woͅn tileͅ ti ni onibara ni agbegbe South America ni oͅpoͅloͅpoͅ osͅu seͅyin.
Arabinrin Mery lati orileͅede Venezuela ni nitori owo ni oun sͅe gbe igbeseͅ beͅeͅ lati igba ti oun ati oͅkoͅ afeͅsoͅna oun ti pinya.
Awọn obinrin to n ta ile ọmọ maa n gba owo bii $4,000 si $12,000’
‘Oͅdun marun un ni emi ati afeͅsoͅna mi fi wa papoͅ, ti a si bimoͅ meji.
Amoͅ mo n ta ile oͅmoͅ mi bayii lati fi ran awoͅn toͅkoͅ-taya to ni isͅoro ati bimoͅ loͅwoͅ, ti emi naa yoo si maa ri owo jeͅun.’
‘O kere tan awoͅn obinrin miran ma n gba owo ileͅ okeere to to eͅgbeͅrun doͅla mejila $12,000, amoͅ awoͅn miran ma n gba $4,000.’
‘Owo yii yoo ranmiloͅwoͅ lati gbe igbe aye iroͅrun peͅlu awoͅn oͅmoͅ mi.’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Awoͅn eniyan n sͅe ipolowo ile ọmọ tita lori ayelujara ati afihan aworan rẹ lori titi, ti woͅn a si fi noͅmba woͅn sibeͅ"
Akoͅroyin BBC, Lucia Franco to n sͅewadii isͅeͅleͅ yii ni Columbia ni iyaleͅnu lo jeͅ fun oun lati ri awoͅn eniyan ti woͅn n ta ile oͅmoͅ woͅn warawara.
‘’Mi o tilẹ mọ pe ko ni nira rara lati ri eͅni ti yoo ta ile oͅmoͅ reͅ fun awoͅn ti woͅn ba feͅ ya a lo lati bimoͅ’’
‘’Awoͅn eniyan n sͅe ipolowo reͅ lori ayelujara ati aworan lori titi, ti woͅn a si fi noͅmba woͅn sibeͅ.’’
‘’Ohun ti wọn ma n sͅe ni lati ta eͅyin to n di oͅmoͅ tabi ko gbe oyun eͅlomiran ti dokita yoo fi si inu reͅ.’’
Awoͅn miran tileͅ ma n fun awoͅn dokita ni riba ki woͅn ba fi orukoͅ baba ati iya to ra ile oͅmoͅ naa si geͅgeͅ bi obi oͅmoͅ jojolo naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi woͅn sͅe ma n sͅe ipolowo ile oͅmoͅ woͅn ree…
Lara awoͅn ohun ti woͅn ma n koͅ si ori eͅroͅ ayelujara ni; ‘mo n fi ile oͅmoͅ mi sͅowo fun eͅni to ba feͅ ra.’
‘Oͅmoͅ oͅdun mejilelogun ni mi, mi o tii bimoͅ ri.’’
‘’Mo feͅ ran eͅnikeͅni to ba n wa oͅmoͅ loͅwoͅ lati ri pe woͅn di oͅloͅmoͅ ni aye. Ara mi ji pepe, mi o si ni aleebu.’’
‘’Awoͅn eͅni to ba wa ya ile oͅmoͅ mi gboͅdoͅ wa lati Ecuador, ki woͅn si le rinrinajo loͅ si orileͅede Amerika.
Amoͅ awoͅn miran tileͅ ma n fi aworan oͅmoͅ sita, ki woͅn ba le moͅ iru eͅya ati isͅeͅda ti oͅmoͅ ti woͅn ba ba woͅn gbe si inu yoo sͅe ri.
Eͅlomiran tileͅ ni nitori oun feͅ ki awoͅn obi miran yoͅ ayoͅ oͅmoͅ ni oun sͅe gbe igbeseͅ lati ya woͅn ni ile oͅmoͅ oun.
Amoͅ awoͅn eniyan bii Mery ni nitori owo ni awoͅn sͅe n ta ile oͅmoͅ woͅn fun eͅnikeni to ba fe bi oͅmoͅ
Titi di asiko yii, gbogbo igbiyanju lati jeͅ ki ijoͅba ileͅ Columbia fesi si isͅeͅleͅ naa lo jasi pabo.












