Mọ díẹ̀ lára nǹkan tí Alága ètò ìdìbò sọ ní Chattam House

Oríṣun àwòrán, Chattam House
Bi eto ìdibo gbogbo ṣe n ṣúnmọ, alaga ajọ eleto ìdibo lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni eto ìdibo ọdun yoo lọ ni ọna to dara pupọ nitori o wa ni tosi awọn araalu.
Yakubu sọ eleyi nigba to n sọrọ ni Chattam House lorilẹede Gẹẹsi.
O salaye pe bí eeyan ba ni ẹtọ lati ìdibo sugbọn ko si ibi to tí maa dibo, awọn yoo se nnkan to yẹ.
O fikun pe ajọ naa ti bẹrẹ lati se afikun sì awọn ibi eto ìdibo eyi ti yoo wulo fun lílo awọn araalu.
Ọga agba INEC ni ki eto ìdibo to bẹrẹ, awọn ibi ìdibo kan wa ninu igbo, ile orisha, ile akọpati ati ile awọn eeyan nla.
"Nigba miiran, eyi maa fun awọn janduku lati kọlu awọn oludibo, ati ọpọ awọn ibudo eto ìdibo yii ni ko dara fun awọn abarapa eeyan."
"Inu mi dun pe awọn ibudo ìdibo ni a ti gbe kuro lọ si ibo miiran lati fun awọn oludibo ni anfani lati ni iriri to dara sọ nípa eto ìdibo 2023."
Yakubu ni nitori rẹ ni awọn sisẹ pẹlu awọn ileeṣẹ kan lati se afikun sì awọn ibudo ìdibo lọdun 2021.
"Fun igba akọkọ lati ọdun 1996, Orilẹede Naijiria ni ibudo ìdibo toto 176.846 yatọ si ti tẹlẹ 119,974.
Eto ìdibo Naijiria lo tobi ju ni ìwọ oorun iadulawọ
Mahmood ni eto ìdibo lorilẹede Naijiria ni o maa pe akiyesi awọn ajọ agbaye nitori ipo ti Orilẹede naa wa lagbaye.
"Lati se eto ìdibo lorilẹede Naijiria, kí n ṣe nkan kekere.
"Pẹlu awọn iwadii wa lati ọdọ awọn eto ìdibo and ileeṣẹ ijoba to n risi ọrọ abele in ìwọ oorun adulawọ, idà milọnu mẹrindinlogun awọn oludib lo wa lati Naijiria.
Mahmood ni eto ìdibo lorilẹede Naijiria dabi eto ìdibo ni gbogbo Orilẹede ìwọ oorun adulawọ ni.















