Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún afurasí mẹ́rin ní Osogbo

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún afurasí mẹ́rin ní Osogbo nipinle Osun to wa ni guusu Iwo Oorun Naijiria.
Awọn ti adajọ dajọ iku fun ni Hammed Rafiu, Rasidi Waidi,Kayode Sunday, ati Owolabi Bashiru
Ninu ẹsun ti awọn mẹrẹẹrin jẹbi rẹ ni ẹsun ijinigbe eleyii ti wọn ji gbe Victor Akinbile to je ọmọ ẹgbọn igbakeji Gomina Ipinlẹ Osun tẹleri, Benedict Alabi ti wọn si dana sun un .
Bo tilẹ jẹ wi pe ọdun 2019 ni ẹjọ naa bẹrẹ ti awọn ti won fẹsun kan ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn,
Sugbọn ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn fi wọn si atimọle lati igba ti ọrọ naa ti bẹrẹ ni ọdun 2019.
Kini o ṣẹlẹ nile ẹjọ?
Lasiko igbejo , agbejoro ṣalaye fun ile ẹjọ pe Victor Akinbile ni awọn ọdaran naa pa lẹyin to rin irin ajo lo si Ikirun, Ipinlẹ Osun ni ọjọ kẹrindinlọgbon, oṣu kọkonla, ọdun 2018.
Lati lo sibi ayẹyẹ ibura igbakeji gomina tẹleri nipinle Osun, Benedict Gboyega Alabi ati Gomina tẹlẹ Adegboyega Oyetola.
Lẹyin ti wọn ti gba owo to le ni milliọnu mẹta lọwọ rẹ, awọn ọ̀daran naa tun ji Akinbile gbe, ti wọn si gbe e sinu ọkọ Toyota Camry re.
Lẹyin eyi ti won gbe e lo si Dominion Camp, to wa ni opopona Iragbiji si Ikirun/Osogbo nibi ti wọn ti fi ina si oun ati ọkọ ayọkẹlẹ Camry ti won gbe si eleyi ti o fa iku Akinbile.
Onidajọ Falola nigba ti o gboriyin fun ile iṣe ọlọpaa fun lilo imọ-ẹrọ igbalode lati se iwadii iṣẹlẹ naa ati bi wọn ti ṣawari awọn afurasi ati Banki ti wọn lo lati ṣe iṣẹ ibi.
Adajo so siwaju si wipe ki gbogbo owo ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi naa ati owo to wa ninu akoto banki wọn ni ki wọn fi le iyawo oloogbe naa lowo.












