Nítorí pé ọkọ̀ àwọn Bolanle kò ní Nọ́mbà ni a ṣe dá a dúró ṣùgbọ́n....- ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹni ti wọn kọkọ pe nibi ipẹjọ naa ni akẹgbẹ Vandi ti wọn jọ wa lẹnu iṣẹ lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.

Inspector Mattew Ahmen sọ fun ileẹjọ pe awọn n da ọkọ duro lati ṣayẹwo rẹ ni ọjọ naa

O ni adari wọn ni Vandi to si wa ni ẹyin nigba ti awọn wa ni iwaju, ti akẹgbẹ wọn miran si wa ni aarin.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye…

Ọlọpaa ti wọn fi ẹsun kan pe o pa arabinrin Bolanle Raheem ti ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ọlọpaa Drambi Vandi lo sọ bẹẹ niwaju adajọ Ibironke Harisson ni ileẹjọ giga ni ilu Eko.

Ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an pe o yin ibọn lu arabinrin Raheem to jẹ agbẹjọro obinrin ni ilu Eko

Ọjọ ọdun Keresimesi ni iṣẹlẹ naa waye ti wọn ni Vandi yinbọn lu arakunrin naa bi oun ati awọn mọlẹẹbi rẹ ṣe n bọ lati ile ijọsin.

Lẹyin naa ni wọn gbe lọ si ileẹjọ ni Ọgbọnjọ, Oṣu Kejila to si ti wa ni ahamọ lati igba naa.

Nibayii, Ajọ to n risi ọrọ awọn ọlọpaa ni Naijiria, PSC ti ni ko lọ rọkun nile fun igba diẹ naa.

Ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó pa Bolanle Raheem ní òun kò jẹ̀bí ẹ̀sùn náà

Inspekitọ Mathew sọ pe: wọn da ọkọ Bolanle duro, ko si duro, lẹyin naa ni wọn gbọ iro ibọn.

‘’Lẹyin naa ni gilaasi ọkọ fọ, ti obinrin kan si fo jade ninu ọkọ pe ọga o ti pa ẹgbọn mi.’’

O ni arabinrin naa di aṣọ Vandi mu, wọn ti Vandi sinu ọkọ, wọn si gbe e lọ.

Agbẹjọrọ ti ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo lo ṣaaju igbejọ naa, ti Adetokunbọ Odutola si jẹ agbẹjọro fun ẹni ti wọn fi ẹsun kan.

Adajọ ti sun igbẹjọ da Ọjọ Karundinlogbọn si Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu Kini, ọdun 2023.

Tani Bolanle Raheem ti wọn yinbọn pa?

Agbẹjọro ni Bolanle Raheem to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ Croston Homes Consulting ni ilu Eko.

O jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ awọn agbẹjoro ni Naijiria, ti o si jẹ ogunna kan ṣoṣo lọwọ iya rẹ.

Ileẹkọ Olabisi Onabanjo University ni Ago Iwoye, ni ipinlẹ Ogun.

Arabinrin naa jẹ onimọ nipa eto ile gbigbe to si ti lamilaaka, ti awọn eniyan si ma lọ gba imọran lọwọ rẹ.