Ìfẹ́ aráàlu kọ́ ní ìdájọ́ Tribunal Osun, gbogbo ìlú ló dìbò fún Adeleke – PDP

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede pe awọn ko faramọ idajọ ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun magomago lasiko idibo, tribunal gbe kalẹ ni ipinlẹ Osun.

Ileẹjọ Tribunal lo kede pe Ademola Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP ko lo pegede ni idibo sipo gomina ni ipinlẹ Osun.

Tribunal ni oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Gboyega Oyetọla lo lọwọ ninu idibo sipo gomina ọhun.

Ẹgbẹ osẹlu PDP lasiko ti wọn n fesi si aṣẹ ileẹjọ naa ni kii ṣe ifẹ awọn araalu ni nkan ti Tribunal ṣe.

PDP ni niṣe ni awọn eniyan tu yaya jade lasiko idibo naa lati fi oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Ademola Adeleke si ipo.

‘’Igbagbọ wa nipe ileẹjọ kotẹmilọrun yoo ṣe idajọ ododo nipa esi idibo naa.’’ - PDP

‘’Ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kẹje, ọdun 2022 ni awọn eniyan jade lati yan gomina tuntun ni ipinlẹ Osun.’’

‘’Awọn to jẹ oluworan nipa eto idibo ni ibo naa lọ ni irọwọrọṣẹ lai si magomago.’’

‘’Bakan naa ni awọn eniyan tuyaya jade lati wa dibo fun oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Ademola Adeleke.’’

‘’Ifẹ awọn araalu ni Ademola Adeleke ti wọn yan si ipo, ti o si yẹ ki ijọba bọwọ fun gidigidi.’’

‘’Lẹyin aṣe tribunal yii, a o lo gbogbo agbara ti a ni labẹ ofin lati ri pe otitọ jọba ninu eto idibo sipo gomina naa.’’

‘’A wa kesi awọn araalu lati fi ọkan balẹ ki wọn si tẹti leko lati maa ṣatilẹyin fun gomina Ademola Adeleke.’’

‘’Igbagbọ wa nipe ileẹjọ kotẹmilọrun yoo ṣe idajọ ododo nipa esi idibo naa.’’